Kí ló ń fa awuyewuye oyè jíjẹ́ láàrín àwọn ọmọ ọba Àwùjalẹ̀ lórí ẹni t'ọ́ba tọ́ sí?
Atẹjade kan ti arakunrin kan fi si ori ayelujara nipa awọn to le jẹ ọba Awujalẹ ti ilẹ Ijẹbu ti n da họwuhọwu silẹ bayii .
Bawo lọrọ naa se jẹ ni ibeere yin abi? N o laa han yin.
Laipẹ yii ni ọgbẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ Ladipo Adeokun fi akọsilẹ kan si ori ayelujara, nipa ilana jijẹ ọba Awujalẹ ti ilu Ìjẹ̀bú. Ohun ti oun n sọ ni pe awọn mẹrin ti oun darukọ ni wọn lẹtọ si apere naa
Awọn orukọ to da ko mu orukọ idile Adeyemi kun un lo mu ki awon idile Adeyemi ti wọn ni Baba awọn ni akọbi Anikilaya lori oye o sọrọ sita pe ko paada, odi ada ni.

Ẹbi Adeyemi, to jẹ okan lara idile to wa labẹ Anikilaya gbe ohun soke pe awọn ni akọbi , eese ri arakunrin naa fi fo orukọ awọn ri lọ n da orukọ awọn ti wọn ni wọn ko si lara idile mẹta ro lẹrọ sinapere Awujalẹ labẹ ẹbi Anikilaya.
Amosa, ninu ọrọ tirẹ, Ọgbẹni Adeokun ṣalaye pe, iwe itan akọsilẹ kan ti wọn pin nibi eto iwuye ọkan lara awọn ọmọ idile Adeyemi kan naa loun ri ri oun fi kọ ohun ti oun kọ si oju opo ayelujara.

Awọn ẹbi Adeyemi ti ni ọrọ ko ei bẹẹ o, ki wọn ma ṣe da ori itan kodo nitori ọjọ iwaju.
Alagba Adeyemi- Anikilaya to sọrọ lorukọ ẹbi Adeyemi sọ fun BBC News Yoruba pe ọmọ mẹta ni Anikilaya ni lẹyin to gun ori apere Awujalẹ, awọn mẹta yii ni wọn si le fi ọwọ sọya pe awọn lẹtọ si didu Oba jijẹ:
- Adeyemi
- Ọgbagba
- Ademolu
o salaye siwanu sii pe lootọ ọmọ pọ to Qnikilaya bi ko to jọba, ṣugbọn gẹgẹbi aṣa oba jijẹ ni ilẹ Ijẹbu, ,"ijẹbu ko le jẹ ki wọn jọba nitori pe ko si agbara yẹn ninu ẹjẹ wọn".





