Àwọn nnkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Awujale ilẹ̀ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, tó wàjà

Awujale Sikiru Kayode Adetona

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ti waja lẹnu ọdun mọkanlelaadọrun.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu Keje, ọdun 2025.

Agbẹnusọ fun aafin Awujale, Oloye Fassy Yusuf fidi iroyin naa mulẹ fun BBC News Yoruba.

Ọdun 1960 ni Ọba Adetona jẹ Awujalẹ gbogbo ilẹ Ijẹbu.

Lati asiko diẹ lo ti dabi i pe ara Kabiyesi ko ya, paapaa bi ko ṣe kopa nibi ọdun Ojude Ọba to kọja.

Ninu gbogbo pọpọṣinṣin to waye lasiko ọdun naa, ohun kan ti awọn eeyan ko ṣai kiyesi ni aisi Kabiyesi ilu Ijẹbu Ode, Ọba Sikiru Adetọna to jẹ Awujalẹ ti Ijẹbu lori ijoko lasiko ajọdun naa.

Kabiyesi Awujalẹ kii pa ọdun yii jẹ bi o ti wulẹ o mọ, eleyi lo si n mu ki ọpọ maa beere pe ki lo ṣe Kabiyesi Awujalẹ Sikiru Adetọna to fi pa ti ọdun yii jẹ.

Iyawo rẹ, Olori Kẹmi Adetọna lo ṣoju rẹ nibi ayẹyẹ ọdun naa.

Ko si atẹjade kankan lati aafin Awujalẹ lori idi ti Kabiyesi Adetọna ko fi bawọn peju sibi ajọdun Ojude Ọba ọdun yii, amọṣa ohun ti ọpọ n di mu ni pe, Kabiyesi Awujalẹ kii ṣe ọmọde mọ lẹni ọdun mọkanlelaadọrun nitori naa o ṣeeṣe ko jẹ wi pe ipa ọjọ ogbo ti n han lara Ọbalaye naa ni.

Ninu ọrọ ti awọn agbaagba meji kan ti wọn sun mọ Ọbalaye naa ati Aafin Awujalẹ fi to BBC Yoruba leti, ọjọ ogbo ati awọn ipenija ilera to rọ mọ ọjọ ogbo kun ara awọn ohun ti ko jẹ ki Kabiyesi naa le darapọ mọ ajọdun naa.

Taa ni Ọba Sikiru Olukayode Adetona?

Awujale ilẹ Ijebu

Oríṣun àwòrán, Others

Ọjọ kẹwaa oṣu Karun un, ọdun 1934 ni wọn bi Ọba Sikiru Olukayode Adetona, gẹgẹ bi Arẹmọ ni agboole ọba Ogbaagba.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Baptist School, Ereko, Ijebu Ode, Ogbere United Primary School, Oke Agbo, Ijebu Igbo, ati Ansar-Ud-Deen School, Ijebu Ode laarin ọdun1943 si1950.

Ile ẹkọ Olu-Iwa (to ti di Adeola Odutola) College, Ijebu Ode lo ti ka ẹkọ girama laarin ọdun 1951 si 1956. Lọdun 1957 si 1958, Arẹmọ Adetona ṣiṣẹ ni ẹka oluwadii owo nileeṣẹ ijọba Western Region, niluu Ibadan, ko to o di pe o kọwe fi iṣẹ silẹ lati lọ kẹkọọ nipa iṣiro owo ni orilẹede United Kigdom.

Ọjọ kẹrin oṣu Kini, ọdun 1960 ni ijọba Western Region kede iyansipo rẹ gẹgẹ bi Awujale tuntun, to si gba ọpa aṣẹ lọjọ kejidinlogun oṣu Kini ọdun naa. Amọ o, ọjọ keji oṣu Kẹrin lo to o gba ade ti wọn si ṣe iwuye lẹyin to ti ṣe awọn etutu oye tan.

Ọba Adetona ni ọba ilẹ Yoruba to ti i pẹ julọ lori itẹ lati bi ọpọ ọdun sẹyin.

Ṣaaju ko to jọba, awọn marun un mii ni wọn jọ dije dupo gẹgẹ bi ọmọ oye, amọ oun ni awọn afọbajẹ dibo fun ni ibamu pẹlu abala ofin kọkanla to wa fun ọrọ oye jijẹ ni Western Region lọdun 1957.

Gomina igba naa fọwọ si nnkan ti awọn afọbajẹ fẹ, eyi to sọ ọ di ọba titi di akoko iku rẹ.