Mo ṣetán láti gbọ́ àwíjàre àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan tó ń ṣèwọ́dé lórí ayípadà orúkọ ilé ẹ̀kọ́ náà - Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe oun ti ti ṣetan lati gbọ awijare awọn akẹkọọ Poly Ibadan ti wọn n ṣe iwọde lori ayipada orukọ ile ẹkọ giga ti Makinde kede.
Makinde sọrọ yii lẹyin tawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga naa atawọn akẹgbẹ wọn ti wọn ti kẹkọọ jade nile ẹkọ naa ti ṣe ifẹhonuhan tako bi gomina ipinlẹ Oyo ṣe yi orukọ ile ẹkọ si Omololu Olunloyo Polytechnic.
Lasiko ti o n ṣe ifilọlẹ igbimọ alaṣẹ awọn ile ẹkọ giga marun un ipinlẹ Oyi ni ọọfiisi rẹ, Makinde sọ pe oun mọ pe ọpọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ ni wọn ko fẹ ki ijọba yi orukọ ti ile ẹkọ naa ti n jẹ tipẹ pada.
Ṣugbọn gomina ni iru igbesẹ bayii ko nii ṣe pẹlu nnkan tawọn eeyan ko fẹ ko yi pada..
Loṣu Kẹfa to kọja ni Makinde fi orukọ gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Ọmọwe Omololu Olunloyo sọ orukọ ile ẹko naa eyi ti ọgọọrọ awọn akẹkọọ ti n ṣe iwọde tako.
Ninu ọrọ rẹ, Makinde ni ''n ko ni ṣalai sọ ohun kan tabi omiran lori awuyewuye to n lọ lori ayipada orukọ Poly Ibadan si Omololu Olunloyo Polytechnic.
Akọsilẹ fi han pe baba Olunloyo ni ọga agba akọkọ Poly Ibadan.
Eyi tumọ si wi pe baba mọ nkan to pọ nipa idasilẹ ile ẹkọ giga yii, ati pe baba ko ipa tiẹ ninu idasilẹ ati idagbasoke ile ẹkọ naa.
O ṣee ṣe kawọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ijọba ranti pe asiko kan wa ti a n ṣe agbeyẹwo bo ya lati ṣe ayipada oruko ile ẹkọ LAUTECH.
Mo fẹ ṣe ayipada orukọ ile ẹkó naa si Ladoke Akintola University, ṣugbọn ẹgbẹ awọn to ti kẹkọọ jade nile ẹkọ naa ran awọn aṣoju si mi.
Ẹgbẹ awọn to ti kẹkọọ jade yii ni wọn ṣalaye fun mi nipa awọn fasiti ti wọn n ṣe nnkan mii yatọ si ẹkọ nipa imọ ẹrọ nikan ti wọn ko s iyi orukọ wọn pada.
Bayii ni mo gba si wọn lẹnu lẹyin ti mo ri i wi pe ọrọ ti wọn sọ mọgbọn dani.''
Gomina ipinlẹ Oyo ni oun ṣetan lati gbọ nnkan tawọn akẹkọọ Poly Ibadan fẹẹ sọ gan an lori ayipada orukọ ile ẹkọ naa.
Makinde ni nnkan toun fẹ kawọn akẹkọọ to n ṣe iwọde mọ pe, wọn n ṣe idiwọ fun ọpọ araalu lẹnu iṣẹ wọn nigba ti wọn ba n ṣe iwọde.
Ki lo ṣẹlẹ saaju asiko yii?

Loṣu Kẹfa to kọja ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde wi pe ayipada yoo ba orukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan, lati bu ọla fun Oloogbe Victor Ọmọlolu Olunlọyọ to Gomina tẹlẹri ni'ipinlẹ Ọyọ.
Yatọ si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ti Oloogbe naa ti wa tẹlẹ ri, Olunloyo ni Giwa agba akọkọ to ṣe akoso ile ẹkọ giga naa l'ọdun 1970 ki o to tẹwọgba iṣakoso ipinlẹ Ọyọ fun oṣu meloo kan laarin ọjọ kinni oṣu kẹwaa si ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 1983.
Lati ọjọ ti Gomina Makinde ti ṣe ikede naa ni ọkanojọkan awuyewuye ati ifẹhonuhan ti n lọ lori itakun ayelujara nitori ikede naa.
Apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ tẹlẹri ati awọn to n kẹkọọ lọwọ lo si ti kọ iwe ranṣe si Gomina Makinde wi pe ko yi ero rẹ pada lori ayipada orukọ ile ẹkọ giga naa.
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 1970 ni wọn ṣe idasilẹ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan, idasilẹ yii waye gẹgẹ bii agbega fun ile ẹkọ ti a ti n kọ nipa iṣẹ ọwọ, 'Technical College, Ibadan.'
Ọpọlọpọ atunṣẹ lo si ti waye si iwe apilẹkọ ti a fi ṣe agbekalẹ ile ẹkọ giga naa ki o le wa ni ibamu pẹlu awọn nnkan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ lero pe yoo ṣe anfani fun ipinlẹ naa ati orilẹede agbaye l'apapọ.















