Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Eko àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì

eto idibo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Eto ijọba ibilẹ ti bẹrẹ bayii nipinlẹ Eko, ti awọn eeyan diẹ si ti tu sita lati to fun eto idibo naa.

O le ni milọnu meje oludibo to forukọsilẹ kaakiri ipinlẹ Eko lat le ni anfani lati yan awọn alaga ijọba ibilẹ ogun ati ijọba ibilẹ LCDA mẹtadinlogoji, to fi mọ awọn kanṣelọ.

Eto idibo naa ni igbagbọ wa pe yoo waye ni ẹku idibo 13,325 kaakiri ipinlẹ Eko.

Ajọ eleto idibo nipinlẹ Eko ti fi ọkan awọn araalu balẹ pe ko ni si kudiẹkudiẹ lasiko eto idibo, ti gbogbo rẹ yoo si lọ pẹlu irọnu.

Gẹgẹ bii o ṣẹ waye lasiko eto idibo gbogbo, lilo ẹrọ BVAS , ẹrọ ti o n fontẹ lu ojulowo oludibo lasiko eto idibo.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede ofin konilegbe ile kaakiri ipinlẹ Eko, bẹrẹ lati ago mẹta owurọ si ago mẹta ọsan lọjọ Ṣatide.

Ṣugbọn ki lo jẹ ki eto idibo jẹ pataki ati nnkan to yẹ ko mọ nipa rẹ?

Ta lo ṣeeṣe ko bori?

Ẹgbẹ oṣelu mọkanla lo wa loju opo iwe idibo, ti awọn oludibo si le lo PVC wọn lati tẹka si.

Eto idibo ijọba ibilẹ lati ọdun 2014 fihan pe ẹgbẹ oṣelu to wa ni ipo lo ma n bori eto idibo ijọba ibilẹ, gẹgẹ bii ẹgbẹ Shine your Eye, ẹgbẹ gan to n pe fun otogẹ lorilẹede Naijiria (EiE Nigeria).

Lati ọdun 1999, ẹgbẹ kan lo n dari ipinlẹ Eko, to si jẹ pe gbogbo ipo nipinlẹ Eko pata ni ẹgbẹ oṣelu kan n dari.

Ẹgbẹ oṣleu The All Progressives Congress (APC), tabi aṣopọ ẹgbẹ awọn ẹgbẹ oṣelu (AD, AC, ACN ṣaaju APC), lo ti n dari ijọba ṣaaju ipadabọ ijọba awarawa, to si jẹ pe ẹgbẹ yii lo ti n dari ijọba, to si le awọn yooku kuro fun ọpọ ọdun.

N jẹ awọn eeyan ma n jade dibo?

Ji jade eeyan jade dibo lorilẹede Naijiria lo ma n kekere. Ọpọ eto idibo ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria lo ma n kekere.

Eto idibo to waye ni ọdun 2021 nipinlẹ Eko lo jẹ pe ida mọkanla eeyan lo jade dupo laarin eeyan milọnu mẹfa to forukọsilẹ fun ibo, gẹgẹ bii awọn ijọba ipinlẹ ṣe ṣalaye.

Ki lo jẹ ki eto idibo ijọba ṣe pataki?

Gẹgẹ bii igun kẹta fun ijọba, ẹnikẹni to ba bori ni iṣẹ rẹ jẹ pe gbigbe ijọba wa sunmọ awọn araalu.

Iṣẹ wọn ni lati ṣe itọju araalu ni ẹsẹkuku ni abala ẹtọ ẹkọ, eto ilera, ipese ọja, ọna to wọ agboole ati bẹẹ lọ ni ilu.

Ṣugbọn, fun ọpọ ọdun, ijọba ipinlẹ ko ri awọn anfani yii pese fun araalu.

Irufẹ agbara wo ni ijọba ilẹ ni?

Lọdun to kọja, ile ẹjọ to giga ju lorilẹede Naijiria gbe idajọ nla to pe fun ominira ijọba ibilẹ.

Idajọ yii fopin si bi awọn ijọba ipinlẹ se n gba owo ijọba ibilẹ mọ owo wọn lati ọdọ ijọba apapọ, ti ile ẹjọ si tun palaṣẹ pe ki wọn ma san owo naa taara si apo ijọba ibilẹ..

Ṣugbọn lẹyin ọdun kan ti idajọ naa waye, ijọba ipinlẹ kuna lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ.

Bí ìbò ìjọba ìbílẹ̀ ṣe ń wáyé lọ́la l‘Eko, ibi tí ìgbaradì dé dúró rèé, tí lílọ-bíbọ̀ ọkọ̀ àti bàálù ṣì ń dáwọ́ dúró láti aago mẹ́ta àárọ̀ sí mẹ́ta ọ̀sán

Àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdìbò

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Eko, Lagos State Independent Electoral Commission (LASIEC) ti sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ètò ti láti ṣètò ìdìbò sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí yóò wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje, ọdún 2025.

Níbi àpérò kan tí alága àjọ LASIEC, Onídàájọ́ Bola Okikiolu-Ighile ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Keje ti ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ akin tí wọ́n ti gbé ní ìgbáradì fún ètò ìdìbò náà.

Okikiolu-Igbhile sọ àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Eko láti ri dájú pé wọ́n kópa nínú ètò ìdìbò náà, tó sì sọ àrídájú rẹ̀ pé ètò ààbò ti wà ní sẹpẹ́.

"Ọjọ́ ètò ìdìbò náà ti dé báwa báyìí, mo lè sọ àrídájú rẹ̀ pé LASIEC ti gbáradì"

Ó ṣàlàyé pé ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Ogun (20) àtàwọn LCDA métàdínlógójì (37) tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko ní ètò ìdìbò náà ti máa wáyé.

"Èèyàn 6,214,970 ló gba káàdì ìdìbò l‘Eko, àgọ́ ìdìbò 13,250 ni ìbò ti máa wáyé, alága àti igbákejì alága 57 àti káńsílọ̀ 376 ni wọ́n máa dìbò yan"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbogbo ipò alága àti igbákejì alága mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57) tó fi mọ́ àwọn ipò káhúnsílọ̀ 376 ni wọ́n máa dìbò yan aṣojú sí.

Nígbà tó ń ṣàlàyé nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti là kalẹ̀ lórí ètò ìdìbò náà, ó ní àwọn ibùdó ìdìbò 13,250 ni ètò ìdìbò náà ti ma wáyé.

Ó sọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́ẹ̀dógún nínú ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kàndínlógún tó fi orúkọ sílẹ̀ ló máa kópa níbi ètò ìdìbò ọ̀hún.

Ó fi kun pé àwọn èèyàn 7,060,195 ló forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò àmọ́ tó jẹ́ èèyàn 6,214,970 ló ti gba káàdì ìdìbò wọn.

Okikiolu-Igbhile ṣàlàyé pé àjọ náà ti ṣiṣẹ́ takuntakun láti jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò, àwọn ọlọ́jà, àwọn ọ̀dọ́, àwọn ilé ìjọsìn, tó fi mọ́ àwọn àkàndá ẹ̀dá ṣáájú ètò ìdìbò.

Ó sọ pé àwọn òijíròrò náà bẹ̀rẹ̀ ní kété tí òun ti gba àkóso ọjọ́ náà nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2025 lójúnà àti ri pé gbogbo èèyàn ló kópa nínú ètò ìdìbò náà.

"Gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó de iṣẹ́ wa àti láti rip é ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀."

Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo òfin tó de ètò ìdìbò ni àwọn ti fi ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń kópa níbi ètò ìdìbò náà.

"Gbogbo ibi tí wọ́n bá ti jí àpótí ìbò gbé ni àtúndi ìò ti máa wáyé"

Ọ̀gá àgbà LASIEC tún là á mọ́lẹ̀ pé tí ìṣẹ̀lẹ̀ jíjá àpótí ìdìbò gbé bá wáyé ni ibùdó ìdìbò kankan, níṣe ni àtúndì ìbò máa ní ibùdó ìdìbò bẹ́ẹ̀.

Ó ní àwọn máa ṣe àrídájú pé rẹ̀ pé ètò ìdìbò náà lọ ní ìrọwọ́ rọsẹ̀.

"A máa ṣe àtúndì ìdìbò níbi tí wọ́n bá ti já àpótí ìdìbò gbé.

"A ò gbàdúrà pé kí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé ṣùgbọ́n tó bá rí bẹ́ẹ̀, a máa nílò láti tún ìbò dì níbẹ̀.

Ẹ̀ṣọ́ ààbò tó wà ní ìdí àpótí ìbò

"Gbogbo ètò ààbò ti wà ní sẹpẹ́ "

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ètò ààbò, Okikiolu-Igbhile ṣàlàyé pé àwọn kò ní fi ọwọ́ kékeré mú ètò ààbò lásìkò ètò ìdìbò náà bí àwọn ṣe ti ṣèpàdé pẹ̀lú ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó sì ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè ààbò tó péye fún àwọn.

"Àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò mẹ́rin, ó kéré tán, ló máa wà ní ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan tó fi mọ́ ọlọ́pàá, NSCDC, ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àtàwọn ológun tí yóò máa lọ máa bọ̀.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣàlàyé, láàárín aago mẹ́rin òwúrọ̀ sí aago mẹ́ta ọ̀sán ni ètò ìdìbò náà fi máa wáyé tó sì rọ àwọn èèyàn láti rip é wọ́n jáde dìbò yan ẹni tó wù wọ́n.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tún pàrọwà sáwọn èèyàn láti lọ ṣàyẹ̀wò ibùdó ìdìbò wọn ṣáájú kí ètò ìdìbò tó bẹ̀rẹ̀ nítorí àlékún ti bá ibùdó ìdìbò láti 8,000 di 13,325 láàárín ọdún 2019 sí àsìkò yìí.

Gbogbo ibùdó ìdìbò ni ọlọ́pàá máa wà, táwọn aráàlú náà bá dẹ̀ rí nǹkan tí kò bójúmu, kí wọ́n tètè fi tó wa létí - Ọlọ́pàá Eko

Nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin ṣàlàyé gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ àwọn NSCDC, Iléeṣẹ́ ológun, Navy àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn ti ṣe ìpàdé láti ṣe àrídájú pé ààbò fún gbogbo èèyàn lásìkò ìbò náà.

Hundeyin ní àwọn ti jíròrò lórí ọ́nà táwọn máa gbà ri pé ààbò wà fún gbogbo èèyàn, pé kí àwọn èèyàn má bẹ̀rù láti lọ ṣe ojúṣe wọn.

"Gbogbo ibùdó ìdìbò ni ọlọ́pàá máa wà, táwọn aráàlú náà bá dẹ̀ rí nǹkan tí kò bójúmu kí wọ́n tètè fi tó wa létí."

Ó fi kun pé kò ní sí lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ tàbí èrò láti aago mẹ́fà òwúrọ̀ títí di ààgo mẹ́ta ọ̀sán tí ètò ìdìbò náà máa fi wáyé.

Ó sọ pé ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó tàpá sófin ètò ìdìbò tàbí tí wọ́n bá mú fún lílọ bíbọ̀ ló máa fojú ba ilé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀.

Hundeyin fi kun pé àwọn tó á ń ṣiṣẹ́ tó ṣe kókó sí ètò ìdìò náà nìkan ni àǹfàní wà fún láti rìn láàárín wákàtí náà.

Àwọn òṣíṣẹ́ LASIEC

Iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà òfurufú dá iṣẹ́ dúró

Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà òfurufú, Air Peace ti kéde pé àwọn ti gbégi dínà ètò ìrìnnà ní ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́ta òru ọjọ́ Àbámẹ́ta nítorí ètò ìdìbò náà.

Àtẹ̀jáde kan tí Air Peace fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́bọ̀ sọ pé ọkọ̀ òfurufú àwọn kò ní jáde tàí wọnú Eko láti aago mẹ́ta òru títí di aago mẹ́ta ọ̀sán.

Wọ́n ní aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni iṣẹ́ máa bẹ̀rẹ̀ padà ní ìámu pẹ̀lú ìkéde tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi síta.

Air Peace tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn oníbàárà wọn tí ètò náà ṣe ìdíwọ́ fún.