Ilé ẹjọ́ ní nọ́ọ̀sì tó fún Mohbad lábẹ́rẹ́ gbọdọ̀ jẹ́jọ́, bu ẹnu àtẹ́ lu Wumi àti bàbá olóògbé

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ ẹsun iku to pa gbajumọ olorin takasufee, Ilerioluwa 'Mohbad' Aloba, ti sọ pe ko si ọwọ ẹnikẹni ninu iku olorin ọhun.

Amọ ṣa, adajọ ile ẹjọ naa to n joko niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, Adedayo Shotobi tọka si nọọsi to ṣetọju oloogbe naa ṣaaju iku rẹ.

Shotobi sọ pe itọju ti nọọsi naa ṣe ko ba ofin mu, bẹẹ ni ko ṣe itọju oloogbe naa ni ilana awọn oniṣegun tootọ.

Àkọlé fídíò, Ó ní ìdí tí mo fi ní kí wọ́n sin òkú ọmọ mi Mohbad ní kíákíá, Bàbá Mohbad ṣàlàyé

Adajọ ọhun ti sọ pe ki wọn ṣe ẹjọ nọọsi naa, Feyisayo Ogedengbe lori ẹsun pe o ṣe iṣẹ ti ko ni imọ to tọ nipa rẹ ati bo ṣe fun Mohbad labẹrẹ lai kọkọ gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ lọwọ dọkita.

Adajọ Shotobi ni "gẹgẹ bi abala kọkandinlogun ofin to rọ mọ iwadii iku ojiji nipinlẹ Eko, ile ẹjọ yii da laba pe ki ọọfisi eto idajọ ipinlẹ Eko ṣe ẹjọ nọọsi Felicia Ogedengbe lori ẹsun pe o n ṣiṣẹ iṣẹgun lai gba aṣẹ ati laibikita."

Ile ẹjọ naa tun sọ pe o yẹ ki ọlọpaa ṣewadii kikun lori iwe ẹsun ti oloogbe naa kọ mọ Sam Larry ati Naira Marley ṣaaju iku rẹ latari awọn ọrọ kan to jẹyọ lasiko igbẹjọ ọhun.

Lẹyin naa ni adajọ Shotobi tun da Joseph Aloba, to jẹ baba Mohbad lẹbi pe o tete sare sin oku ọmọ rẹ lai kọkọ ṣe iwadii ohun to pa a.

Ni ti Wumi Aloba, to jẹ iyawo oloogbe, ile ẹjọ bu ẹnu atẹ lu u pe o ṣetọju ọkọ rẹ ninu ile lasiko to yẹ ko gbe lọ sile iwosan nibi ti awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun yoo ti tọju rẹ.

Ile ẹjọ ọhun tun bu ẹnu atẹ lu bi ọrọ iku oloogbe naa ṣe di tọrọfọnkalẹ lori ayelujara ti oniruru eeyan si n ṣe idajọ funra wọn.

Àkọlé fídíò, Tó bá jẹ́ pé òkú ma ń wo ẹ̀yìn, ọkọ mi yòó ti sun ẹ̀kún gálọ̀ọ́nù kan

Lẹyin naa lo rọ ijọba ko maa pese eto aabo to peye faraaalu ni gbogbo igba.

O tun rọ awọn agbofinro ki wọn dẹkun ati maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu eto abo araalu.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni Mohba jade layẹ lẹyin to gba itọju ninu ile latari bo ṣe ṣeṣe nibi ode kan.

Lara awọn ti araalu kọkọ di ẹbi iku rẹ ru ni Naira Marley ati Sam Larry latatri bi wọn ṣe kọkọ n dunkoko mọ ṣaaju iṣẹlẹ iku rẹ.

Amọ ile ẹjọ ti sọ pe Naira Marley ati Sam Larry ko lọwọ ninu iku rẹ bo tilẹ jẹ pe o ṣeeṣe ki wọn dunkoko mọ saaju ko to jade laye.