Mohbad@29: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn ikú òjijì akọrin yìí

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lonii yii, ojọ Kẹta, oṣu Kiini, ọdun 2025 ni gbajugbaja akọrin takasufee, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, tọpọ eeyan mọ si Mohbad ko ba pe ọdun ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to ba jẹ pe o ṣi wa laye.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Mohbad nigba to ku lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023.

Iku rẹ mu awuyewuye dani lori ayelujara, ti ọpọ si n tọka si ẹni to ni ileeṣẹ orin to n gbe e sita tẹlẹ, Naira Marley, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa tabi ile-ẹjọ ko tii fidi eyi mulẹ pe lootọ ni.

Oṣu Keji, ọdun 2022, ni Mohbad kuro nileeṣẹ to n gbe orin sita, Marlian Music to jẹ ti Naira Marley.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 gbe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹtala dide lati ṣe iwadii iku onkọrin ọhun.

Iku rẹ lo tun fa bi awọn ọlọpaa ṣe fi kele ofin gbe Naira Marley ati gbajumọ kan nipinlẹ Eko, Balogun Eletu, ti wọn tun n pe ni Sam Larry, ati awọn miran.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 ni wọn lọ wu oku Mohbad fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa a.

Èsí àyẹ̀wò òkú Mohbad kò tẹ́ mí lọ́rùn, mo fẹ́ tún àyẹ̀wò òkú ọmọ mi ṣe - Bàba Mohbad

Aworan Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mogbad/Instagram

Latigba ti esi ayẹwo lati mọ iru iku to pa gbajugbaja olorin takasufee nni to ku lasiko ti ogo rẹ n buyọ, Ilerioluwa Alọba ti jade ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi awọn kan ṣe n sẹ sọ ejo lọwọ ninu, bẹẹ lawọn miran n sọ pe boya nitori ti wọn ti tete sin oku naa ni esi ayẹwo ko ṣe iru iku to pa Ilerioluwa ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad.

Oriṣiriṣi awuyewuye to n lọ nigboro yii lo mu ki BBC YORUBA kan si baba oloogbe naa, Ọgbẹni Joseph Alọba lati mọ boya esi ayẹwo ọhun tẹẹ lọrun tabi ko tẹẹ lọrun.

Ṣugbọn nigba to n ṣalaye, Ọgbẹni Joseph Alọba jẹ ko di mimọ pe oun ko nigbagbọ kankan ninu esi ayẹwo naa ti wọn gbe jade.

O ni ko ṣee ṣe ki esi ma jade lori ayẹwo, lai nii ṣe bo tilẹ pẹ to, ṣugbọn to sọ pe oun ṣetan lati na owo lori ayẹwo miran.

Bakan naa ni Ọgbẹni Alọba sọ pe irọ to jinna si otitọ ni iyawo ọmọ oun tẹlẹ naa, Wunmi n pa mọ oun kaakiri wi pe oun mọ nipa bi wọn ṣe tete sinku Mohbad, ọmọ oun.

Bi esi ayẹwo ọhun ko ṣe tẹ mi lọrun naa ni ko tẹ gbogbo aye lọrun

Baba Mohbad tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe “Bi esi ayẹwo yẹn ko ṣe tẹ mi lọrun naa ni ko tẹ gbogbo aye lọrun. Ṣugbọn a ni lati gba aṣẹ lati ile-ẹjọ pe ohun ti a fẹẹ ṣe ree, ti a ba si ti gba aṣẹ, iṣẹ ti bẹrẹ naa niyẹn.

Ilé ẹjọ́ fún Naira Marley àti Sam Larry ní béèlì lórí ìgbẹ́jọ́ Mohbad

Aworan Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Instagram

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan tó wà ní Yaba, ìpínlẹ̀ Eko ti fún gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Naira Marley àti Sam Larry ní béèlì ogún mílíọ̀nù náírà.

Naira Marley, Sam Larry àtàwọn méjì mìíràn ni wọ́n wọ́ lọ sílé ẹjọ́ ní ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 tí ilé ẹjọ́ sì jù wọ́n sí àhámọ́.

Ikú gbajúmọ̀ olórin Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ni wọ́n ń jẹ́jọ́ lé lórí.

Adájọ́ Adeola Olatunbosun sọ fún àwọn olùjẹ́jọ́ náà láti fi ìwé ìrìnnà wọn kalẹ̀ fún ilé ẹjọ́ kí wọ́n sì máa yọjú sí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn ní àgọ́ ọlọ́pàá Panti.

Ó ní Naira Marly àti Sam Larry pèsè onídùró mẹ́ta tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì gbọdọ̀ ní ogún mílíọ̀nù náírà nínú akoto owó wọn.

Olatunbosun tún ṣèkìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ kàn sí òun lórí ìgbẹ́jọ́ náà.

Ó ní òun máa gba ohùn ẹnikẹ́ni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ tí òun sì ma wá gbé sí etí ìgbọ́ gbogbo ènìyàn.

Lórí ikú Mohbad, ẹgbẹ́ nọ́ọ̀sì Eko sọ̀rọ̀ lórí afurasí ''Auxillary Nurse'' tó wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Kii ṣe ara wa rara ati rara.

Gbolohun yii ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nọọsi ẹka ti ipinlẹ Eko fi sita lori afurasi nọọsi ti awọn ọlọpaa mu lori iku gbajugbaja akọrin Mohbad.

Nọọsi auxillary yii gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ti ṣe sọ ko le jẹ ara awọn nitori ijọba ko faramọ apejuwe auxillaruy nọọsi ninu awọn to n ṣe iṣẹ itọju alaisan lorileede Naijiria.

Akọwe ẹgbẹ naa arakunrin Toba Odumosu lo ṣalaye ọrọ yi ninu ifọrọwerọ to ni pẹlu akọroyin BBC Yoruba.

Arakunrin Toba sọ pe awọn kan si ileeṣẹ ọlọpaa lati le mọ iru ẹni ti awọn agbofinro sọ pe o wa ni akasọ awọn.

O ni nigba tawọn debẹ tawọn si fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo,gbangba lo han pe kii ṣe ẹni to kawe gboye nilana ẹgbẹ awọn tori naa kii ṣe ojulowo nọọsi.

Mohbad: Ìdí tí a ṣe fi gáàsì tajútajú tú àwọn tó ń ṣe ètò ìdágbáre ‘candlelight’ ká rèé – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko

Mohbad

Oríṣun àwòrán, iammohbad/instagram

leeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣalaye eredi to ṣe fi gaasi tajutaju le awọn to n ṣe iwọde idagbere ‘candlelight’ fun olorin takasufe to dagbare faye, Mohbad, ni iloro lekki Toll Gate.

Alukoro ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin ṣalaye ninu atẹjade kan loju opo X rẹ pe awọn eeyan naa kọja aye wọn lo jẹ ki awọn fi gaasi tajutaju le wọn.

Gẹgẹ bii laaye rẹ, aago mẹjọ alẹ ni eto naa yoo dopin lagbegbe Muri Okunola, gẹgẹ bii adehun ti awọn to ṣagbatẹru eto naa ni pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa.

Amọ pupọ ninu awọn to kopa ninu eto naa kọ lati pada sile wọn lẹyin aago mẹjọ ti wọn fẹnuko si.

Kaka ki wọn pada sile wọn, ṣe wọn n korajọ lagbegbe Lekii Toll Gate naa, eyii to n fa sunkẹrẹfakẹrẹ ọkọ, ti wọn si fẹ sọ eto ọhun di iwọde ni iloro naa lodi si adehun to wa nilẹ ṣaaju.

Hundey ni awọn eeyan ọhun kọja agbegbe ti wọn sọ pe awọn yoo ti ṣe eto idagbere, wọn si di irinkerindo ọkọ lọwọ ni iloro ọhun.

Màá ṣe àyẹ̀wò DNA fọ́mọ Mohbad, kí wọn tó sin-ín, ẹ má gba òkú ọmọ mi lẹ́yìn mi - Bàbá Mohbad

Joseph Aloba, tíí ṣe bàbá gbajúmọ̀ akọrin tàkasúfèé nnì, Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad, ti ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti sin òkú ọmọ òun lẹ́yìn òun.

Nínú fídíò kan tó fi sórí ayélujára Facebook, ni bàbá Mohbad ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan ṣe ń pè fún pé kí wọ́n gbé òkú ọmọ náà kalẹ̀ fún àwọn, kí àwọn lọ sin òkú ọmọ náà.

Bàbá ọmọ náà ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ gba òkú ọmọ òun láì gba àṣẹ lọ́wọ́ òun.

Ṣáájú ni àwọn kan ti ń ní kí àwọn ọlọ́pàá gbé òkú ọmọ náà sílẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè sin ọmọ náà bó ṣe tọ́.

Baba Mohbad ṣe àyẹ̀wò tuntun fún òkú ọmọ rẹ̀ láti mọ irú ikú tó pa á

Awọn mọlẹbi gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti ṣe ayẹwo tuntun fun oku rẹ lọna ati mọ iku to pa a.

Ṣaaju ni baba Mohbad, Jospeh Aloba ti kọkọ sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan pe esi ayẹwo ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe lori oku ọmọ oun ko tẹ awọn mọlẹbi lọrun , awọn yoo si ṣe tiwọn.

Kí ló dé tí ẹbí Mohbad tún n wá àwọn ẹlẹ́rìí síi lórí ikú rẹ̀?

Igbimọ agbẹjọro mọlẹbi gbajugbaja akọrin takasufee to ti doloogbe, Ilerioluwa Oladimeji Aloba, tọpọ eeyan mọ si Mohbad ti sọ pe awọn yoo nilo awọn ẹlẹrii sii lati wa ṣalaye awọn ohun ti oju wọn to nipa iku rẹ.

Wọn ni ọrọ iku Mohbad gbẹgẹ pupọ leyi tawọn fi gbọdọ mọ ohun ti wọn yoo sọ sita fun araalu.

Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe, ọkan lara awọn olori igbimọ ọhun, Taiwo Odumosu sọ ninu atẹjade to fi sita, pe awọn ẹri ti wọn ba gba, ọlọpaa lo yẹ ki wọn ko o fun, kaka ki wọn fi sita fawọn eeyan.

Bakan naa lo tun rọ awọn eeyan lati jade wa sọ ohun ti wọn mọ nipa iku Mohbad, lati le ran iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ

“Bi a ba wo bi awọn ohun to rọ mọ iku Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad), ati awọn ohun ti wọn ti gbe sita fawọn eeyan, leyi to jẹ pe ọwọ ọlọpaa nikan lo wa, awa igbimọ agbẹjọro mọlẹbi Aloba yoo fẹ lati rọ ẹnikẹni to ba ni awọn ẹri to jọju, to si ṣe pataki lọwọ, lati le jẹ ki iṣẹ iwadii yọri si rere nipa iku ọmọ wa, ki wọn wa ba igbimọ agbẹjọro lati fi to wa leti.

“Ẹ tun le kan si awọn ọlọpaa naa lati fi to wọn leti pẹlu fun aabo ẹlẹri ati afurasi,” atẹjade ọhun ṣalaye.

Odumosu sọ pe oniṣẹ iwadii coroner ti pe fun ẹlẹrii, to si ni awọn mọlẹbi n wa iranlọwọ lati ko ẹri jọ lati le mọ ohun to ṣeku fa iku aitọjọ Mohbad.

“Ẹ dakun, ẹ jẹ ko di mimọ pe Joseph Aloba ko wa ibaṣepọ to dan mọnran kankan lasiko yii. Gbogbo ohun to n fẹ ni lati ri idi okodoro ohun ṣeku pa ọmọ rẹ

Ile-ẹjọ iwadii coroner nikan lo lẹtọọ lati sọrọ lori iwadii ti yoo mu wa yọri ninu ẹjọ to n lọ nile-ẹjọ,” o fi kun atẹjade naa.