Baba Mohbad ṣe àyẹ̀wò tuntun fún òkú ọmọ rẹ̀ láti mọ irú ikú tó pa á

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn mọlẹbi gbajugbaja olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti ṣe ayẹwo tuntun fun oku rẹ lọna ati mọ iku to pa a.

Ṣaaju ni baba Mohbad, Jospeh Aloba ti kọkọ sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan pe esi ayẹwo ti ijọba ipinlẹ Eko ṣe lori oku ọmọ oun ko tẹ awọn mọlẹbi lọrun , awọn yoo si ṣe tiwọn.

"Wọn ti ṣe ayẹwo tuntun naa lọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ, oṣu Keje, ọdun 2024 yii"

Wayi o, ile ẹjọ majistreeti kan to wa niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, ti fun baba Mohbad laṣẹ lati lọ ṣe ayẹwo tuntun fun oku ọmọ rẹ.

Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe ile ẹjọ naa tun paṣẹ pe ọgbẹni Aloba funra rẹ ni ko san gbogbo owo ti yoo na lati ṣe ayẹwo oku naa.

Ọkan lara awọn agbẹjọro fun idile Mohbad, Monisola Odumosu, sọ ninu atẹjade kan pe wọn ti ṣe ayẹwo tuntun naa lọjọ kọkandinlogun ati ogunjọ, oṣu Keje, ọdun 2024 yii.

O ni awọn yoo tẹsiwaju lati ṣe ayẹwo ‘toxicology ati histology’ lati ara awọn nnkan ti wọn ti mu kuro lara oku Mohbad.

O ni “ti a ko ba mọ ohun to ṣokunfa iku rẹ ninu ayẹwo akọkọ, ayẹwo keji, lara eyii ti ‘toxicology ati histology’ wa yoo ṣafihan rẹ.”

Agbẹjọro mọlẹbi oloogbe naa fi kun pe baba rẹ wa ni ikalẹ lasiko ti ayẹwo naa n lọ lọwọ, to fi mọ awọn onimọ mii atawọn eeyan ti baba rẹ n fẹ ko wa nibẹ.

Irinajo iku Mohbad...

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Mohbad wa to fi jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ti ohun to ṣokunfa iku rẹ si fa họwuhọwu lori ayelujara.

Ọkan lara awọn ọmọ ileeṣẹ orin Naira Maley ni tẹlẹ amọ aarin oun ati Naira daru.

Lẹyin iku rẹ ọhun ni ọlọpaa gbe iwadii dide, ti wọ si fi ṣikun ofin mu ọpọ awọn ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu rẹ atawọn ti iroyin ni wọn dunkoo mọ ọ lasiko to wa laye.

Amọ lẹyin ayẹwo oku ti ijọba ṣe lẹyin ti wọn wu oku naa tan, ikọ oluwadii ni ayẹwo naa ko ṣafihan ohun to ṣekupa oloogbe ọhun latari pe oku naa ti jẹra.