Kamala Harris rí àtìlẹyìn tó yẹ láti borí ìbò àbẹ́nú, di olùdíje ààrẹ fẹ́gbẹ́ òṣèlú Democratic

Kamala Harris
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbakeji aarẹ fun ilẹ Amẹrika, Kamala Harris, ti n ri atilẹyin ọpọ awọn asoju ọmọ ẹgbẹ Democratic gba lati di oludije sipo aarẹ ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa.

Eto agbeyẹwo oludije ti ileesẹ iroyin Associated Press se lọjọ Aje fihan pe Harris ti ri atilẹyin awọn asoju to ku diẹ ko to ẹgbẹrun meji (1976) gba, eyi to nilo lati bori isoro akọkọ eto idibo naa.

Eyi tumọ si pe Harris ti wa loju opo lati de ade oludije aarẹ fẹgbẹ oselu Democratic, ko si koju oludjije aarẹ fẹgbẹ oselu Republican ninu eto idibo aarẹ ti yoo waye losu kọkanla ọdun yii.

Kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Kamala Harris

Idije Harris yoo wa di ohun nigba tawọn asoju ẹgbẹ oselu ba pe orukọ saaju eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu Democratic ti yoo waye nipinlẹ Chicago.

Awọn asoju yii si ni awọn ọm ẹgbẹ oselu maa n yan lati lọ soju wọn nibi idibo abẹnu ẹgbẹ oselu ikọkan wọn lati dibo yan oludije fun ipo kọọkan.

Ko tii si ẹnikẹni to tii kede faraye pe oun fẹ tako Kamala Harris ninu eto idibo abẹnu naa lati yan oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu Democratic lati ọjọ Aiku ti Joe Biden ti kede pe oun ko kopa ninu idije sipo aarẹ mọ.

Nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu Democratic, ti yoo waye laarin ọjọ kinni si ikeje osu kẹjọ ọdun 2024, nibi tawọn asoju ẹgbẹ oselu naa yoo ti dibo, ni Harris yoo ti lanfaani lati di oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu naa.

Ta ni Kamala Harris tí Joe Biden ṣàtìlẹ́yìn fún láti du ipò Ààrẹ Amẹrika?

Ni bayii to ku nnkan bii oṣu mẹrin ki eto idibo Aarẹ Amẹrika waye, Aarẹ Joe Biden ti sọ pe oun ko ni dije du ipo fun saa keji mọ.

Lẹyin ikede naa ni Biden sọ pe Kamala Harris loun ṣatilẹyin fun lati dije bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan mii naa nifẹ ati dije.

Ṣaaju lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat atawọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan ti kọkọ sọ pe Biden yoo lulẹ lasiko idibo latari bo ṣe n lulẹ ninu awọn itakurọsọ to n waye ṣaaju eto idibo naa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan ko ṣatilẹyin fun Kamala lasiko ibo ọdun 2020, ọpọ eeyan lo n tii lẹyin bayii lẹyin saa rẹ gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ.

Lara eredi ti wọn fi n ṣatilẹyi fun ni bo ṣe n ja fẹtọ awọn obinrin lati le ṣẹ oyun, ẹyọnu ti awọn alawọ dudu ni si nilẹ naa ati boṣe jẹ amofin ni ibẹrẹ aye rẹ.

Awọn kan ni ọwọ rẹ yoo yege ninu eto idibo naa gẹgẹ bii amofin tẹlẹ to n gbena woju Donald Trump to jẹ arufin.

Bi Kamala ṣe di igbakeji Aarẹ

Alameda County ni Kamala ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii amofin lọpọ ọdun sẹyin ko to di agba ọjẹ nidi iṣẹ naa, titi to fi di aṣaaju amofin ni San Fransacisco lọdun 2003.

Lẹyin naa ni wọn fi ibo gbe wọle gẹgẹ bii amofin agba ipinlẹ California to jẹ obinrin akọkọ nipo naa ti kii ṣe alawọ funfun.

O lo anfani irawọ rẹ to n tan lọdun naa lati du ipo sẹnetọ ni California lọdun 2017.

O gbiyanju lati du ipo Aarẹ lọdun 2020 ṣugbọn o lulẹ.

Laarin ọdun kan to han gbangba pe ko ni le di Aarẹ ni Biden kede rẹ gẹgẹ bii igbakeji.

Gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ, ara aṣeyọri Kamala ni bo ṣe ja fun ẹtọ awọn obinrin lati ṣẹ oyun.

Bo tilẹ jẹ pe o ṣe awọn aṣeyọri kan, awọn ọmọ Amẹrika kan tun gbagbọ pe o kuna lati ṣe awọn nnkan ti wọn n fẹ ko ṣe lori oye.

Ibẹrẹ pẹpẹ Kamala Harris

Ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 1964 ni wọn bi Kamala Harris niluu Oakland, nipinlẹ California, ti awọn obi rẹ si jẹ ọmọ ilẹ okeere.

Ọmọ orilẹede India ni iya rẹ, Shyamala Gopalan Harris, nigba ti baba rẹ jẹ ọmọ ilẹ Jamaica.

Ko sọ ile nu nitori ọpọ igba lo maa n ṣabẹwo si India lati kekere.

O kawe lọpọ ile ẹkọ, lara awọn ile ẹkọ naa ni Howard University ati University of California College of the Law, San Francisco.