'Ọmọ mi ní kí n bá òun ṣe mílíìkì sóyà kalẹ̀, mi ò mọ̀ pé ìgbà tí mà á ri kẹ́yìn nìyẹn'

Emmanuela Orakwelu tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìkọlù náà

Oríṣun àwòrán, ORAKWELU FAMILY

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọ̀kan lára àwọn òbí tó pàdánù ọmọ rẹ̀ sínú ìjàmbá ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Plateau ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe mú ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ lọ, tí ọmọ rẹ̀ míì sì tún farapa.

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje, ọdún 2024 ni ilé ẹ̀kọ́ Saints Academy tó wà ní ìlú Jos, olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau ṣàdédé dàwó tí akẹ́kọ̀ọ́ tó tó ogún sì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá náà.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tún farapa.

Ìyá kan, Ujunwa Orakwelu láti ìjọba ìbílẹ̀ Aniocha ní ìpínlẹ̀ Anambra sọ fún BBC Igbo pé ará ilé òun lọ sáré wá sọ fún òun pé ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ òun ń lọ ti dàwó.

“Nígbà tí alábàágbélé mi bèèrè lọ́wọ́ mi pé ṣé àwọn ọmọ lọ sílé ẹ̀kọ́, ẹ̀rù bàmí nítorí mo kọ́kọ́ rò pé ìjà ìgboro ti bẹ̀rẹ̀ ní Jos ni láì mọ̀ pé ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ mi ló ti dàwó.”

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí wọ́n sọ fún òun pé ilé ẹ̀kọ́ náà ti dàwó ni òun sáré pe ọkọ òun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tí àwọn sì jọ sáré lọ sílé ẹ̀kọ́ náà.

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ̀ ajé ló gbé ẹbí Orakwelu dé ìlú Jos láti ìpínlẹ̀ Anambra.

Ó sọ pé bí àwọn ṣe ń súnmọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ni àwọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ kankan le jáde nínú ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún láàyè nítorí bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe dàwó tó.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“A bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tó rì sábẹ́ ilé náà.”

Ó ní èèyàn kan sọ fún òun pé wọ́n ti rí ọmọ kan yọ nínú àwọn ọmọ òun àti pé ó ti wà nílé ìwòsàn fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú tó péye.

“Nígbà tí a gbọ́ ìyẹn, èmi àti ọkọ mi tún tẹ̀síwájú láti máa wá ọmọ mi kejì ṣùgbọ́n a ò tètè ri.”

Nígbà tó yá Ujaunwa àti ọkọ rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn láti lọ wo ọmọ tó farapa, tí àwọn dókítà sì sọ fun pé apá rẹ̀ ló kán àti pé àwọn ti ń tọ́jú rẹ̀.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lópọ̀ ilé ìwòsàn ni àwọn lọ láti ṣàwárí ọmọ òun kejì ṣùgbọ́n pàbó ni ìgbìyànjú àwọn ń jásí.

“Ní nǹkan bíi aago méje ìrọ̀lẹ́ ni èèyàn kan pe ọkọ mi láti yàrá ìgbóòkúpamọ́sí ti ilé ìwòsàn OLA tí wọ́n fi òkú àwọn ọmọ tó wà níbẹ̀ hàn-án. Emmanuela Ujunwa Orakwelu, ẹni ọdún mẹ́tàlá wà lára àwọn ọmọ náà.”

Ujunwa ní kí ọmọ òun tó lọ sílé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ náà ló sọ fún òun láti bá òun ṣe mílíìkì sóyà kí òun tó dé láti ilé ẹ̀kọ́ àṣé ìgbà ìkẹyìn tí òun máa ri mọ nìyẹn.

Gómìnà Plateau kéde títi ilé ẹ̀kọ́ náà pa

Gómìnà Mutfwang àti ibi ilé tó dàwó

Oríṣun àwòrán, CALEB MUTFWANG/NEMA/X

Lẹ́yìn ìjàmbá yìí ni gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau, Caleb Mutfwang kède ìbánikẹ́dùn ọlọ́jọ́ mẹ́ta láti ṣe ìdárò àwọn ọmọ náà.

Bákan náà ló pàṣẹ pé kí wọ́n ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa pé wọn kò gbọdọ̀ ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ mọ́ nílé ẹ̀kọ́ náà.

Nígbà tí gómìnà Mutfwang ṣàbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ló pàṣẹ náà tò sí tún ní kí wọ́n nawọ́ gán àwọn awakùsà tó ń ba ilé àwọn èèyàn lọ́nà àìtọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn olùgbé agbègbè náà ní àwọn awakùsà ló máa ń ṣiṣẹ́ níbi ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà sí tẹ́lẹ̀.

Wọ́n ní àwọn gbàgba pé ilẹ̀ gbígbẹ́ tó ti wáyé níbi ilẹ̀ náà lọ ṣàkóbá fún ilé ẹ̀kọ́ náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Jos ní akẹ́kọ̀ọ́ 154 ló wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi wáyé, wan ní 132 ni wọ́n dóòlà ẹ̀mí wọn tí wọ́n gbé lọ sílé ìwòsàn.

Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Plateau, Musa Ashoms ló kéde iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó farapa náà.

Ní Busa-Buji, ìjọba ìbílẹ̀ àríwà Jos ni ilé ẹ̀kọ́ Saints Academy wà.

Ojú mi báyìí ni ilé ẹ̀kọ́ náà ti dàwó

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó ṣojú mi kòró tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lójú rẹ̀ ní ilé ìtajà tó wà níwájú ilé ẹ̀kọ́ náà ni òunb wà lásìkò tí ìjàmbá náà wáyé.

Ó ní àwọn gbìyànjú láti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì tó yọjú síbẹ̀ àma àwọn kò ní irinṣẹ́ tó lè ṣe iṣẹ́ náà.

Ó sọ pé lásìkò táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́ ni àwọn ṣàdédé gbọ̀ gbì tí ilé ẹ̀kọ́ náà dàwọ lulẹ̀.

Ilé ẹ̀kọ́ tó dàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images