Èèyàn márùn-ún tó bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé l’Ondo gba ìtúsílẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti kede pe awọn ti doola awọn eeyan marun un kan ti ko sọwọ awọn ajinigbe lopopona Ifon si Owo nipinlẹ Ondo.
Orukọ awọn marun-un naa ni Adewole Paul, Oluwadara Feranmi, Andrew Patience, Oribamise Taiwo, ati Ajayi Leka.
Bẹẹ ba gbagbe, awọn ajinigbe yii lọsẹ to kọja, ti wọn si gbẹmi eeyan kan ati awakọ ọkọ ero lasiko ti wọn kọlu ọkọ ero ni opopona marose Ifon si Ilu Owo nipinlẹ Ondo.
Agbegbe yi jẹ ọkan lara ibi ti awọn ajinigbe ti maa n sọsẹ ju nipinlẹ Ondo.
Agbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami nigba to n ba BBC News Yoruba ṣalaye pe awọn eeyan marun un ni wọn ti wa ni ile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju ko di pe awọn pada si ọdọ mọlẹbi wọn.
“Adupẹ lọwọ Ọlọrun pe gbogbo awọn eeyan yii ni ati ri, ti wọn si ti wa ni ile iwosan bayii nibi ti wọn ti gba itọju.
”Ni aipẹ, wọn yoo darapọ mọ awọn mọlẹbi wọn."
Se loootọ ni pe awọn mọlẹbi san owo itusilẹ?
Saaju ni iroyin kan tẹ wa lọwọ pe awọn ajinigbe naa pe awọn mọlẹbi eeyan marun-un to wa lakata wọn, ti wọn si n bere fun milionu marun-un naira gẹgẹ bi owo itusilẹ.
Ọkan lara mọlebi awọn ti wọn jigbe naa to ba BBC Yoruba sọrọ, Lawal Happiness, fidi iroyin naa mulẹ.
O ni awọn ajinigbe naa ti kọkọ beere fun ọgbọn millionu, ki wọn to ja walẹ si million mẹta fun ẹni kọọkan wọn, ki wọn to wa fẹnuko si million marun un Naira.
O ni eyi waye lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lati ọdọ awọn ẹbi awọn ọmọ to fara kaasa iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Fumilayo Odunlami ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko gbọ nipa boya awọn mọlẹbi san owo itusilẹ.
“Lati ijọ ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ni Ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe Owo ati awọn ẹsọ wa ti wọ inu igbo lọ lati ṣawari awọn ajinigbe naa.
“Nigba ti wahala yii pọ, ti awọn ajinigbe ri pe wọn ti n wa wọn, ni wọn fi ẹsẹ fẹ, ti wọn si fi awọn eeyan naa silẹ.”
Sugbọn nigba ti Ileeṣẹ BBC News Yoruba kan si Lawal Happiness pada, o jẹ ko di mimọ pe awọn mọlẹbi san owo itusilẹ, ko di pe wọn tu awọn eeyan marun naa silẹ.















