"Ìdí rèé tí a kò ṣe fẹ́ káwọn akọ̀ròyìn gbé àjọ̀dún ọdún Osun Osogbo 2024 síta"

Aworan ojubọ Osun

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin kan jade lopin ọsẹ to kọja wi pe awọn alakoso ayẹyẹ Osun Osogbo ti fofin de àwọn ileeṣẹ iroyin wi pe wọn o gbọdọ gbe nkankan sita lati ibi ayẹyẹ naa ti tọdun 2024 yii.

Atẹjade yii ti adari eto iroyin Osun Osogbo 2024 , Oyindamola Olukanni fi sita sọ pe ileeṣẹ iroyin kankan, tabi awọn gbajumo ori itakun ayelujara to fi mọ awọn apanilẹrin-in ti wọn maa n ṣe "skit" ko gbọdọ gbe ohun kohun jade lati ibi ayẹyẹ Osun Osogbo t'ọdún yii lai gbaṣẹ lọwọ awọn alakoso eto naa.

Oyindamola tun sọ ninu atẹjade ọhun pe ẹnikẹni to ba kọ lati tẹle ilana yii yoo foju wina ofin.

"Idi ti a ṣe fofin de awọn ileeṣẹ iroyin lori Osun Osogbo ree"

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ lori foonu, Ọgbẹni Oyindamola to jẹ adari eto iroyin fun ayẹyẹ Osun Osogbo ṣalaye pe, ọpọ awọn akoroyin lo n fi Osun Osogbo pa owo sapo ara wọn eyi ti ko si de apo ijọba ipinlẹ Osun.

Oyindamola fikun ọrọ rẹ pe awọn t'awọn jẹ onimọ nipa ipolowo tawọn n ba ijọba ṣiṣẹ gan an maa n fowo ra ohun tawọn n gbe jade lori Osun Osogbo ni.

"Kii ṣe wi pe a ni k'awọn eeyan sanwo ki wọn to le gbe ohun kohun sita lori Osun Osogbo.

Ohun ti a n fẹ ni ki gbogbo akọroyin to ba fẹ wa si ibi ayẹyẹ naa forukọ silẹ pẹlu wa.

Ọpọ ileeṣẹ iroyin ni wọn ti síi f'orukọ silẹ pẹlu wa bayii," Oyindamola ṣalaye.

Adari eto iroyin fun ayẹyẹ Osun Osogbo ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe "awọn eeyan yoo si maa lanfaani lati fi foonu wọn ya fidio nibi ayẹyẹ Osun Osogbo ti wọn si le gbe soju opo ori itakun ayelujara wọn.

A o ni sọ pe ki wọn ma ṣe bẹẹ niwọn igba ti ko ba ti jẹ pe wọn fẹ fi pa owo sapo ara wọn ni."

"Ijọba ipinlẹ Osun fẹ ki Osun Osogbo maa mowo wọle"

Adari eto iroyin fun Osun Osogbo t'ọdún 2024 tun fidi rẹ múlẹ pe ijọba ipinlẹ Osun ti n ṣe akitiyan lati maa pawo wọle nípasẹ irin-ajo afẹ eyi ti Osun Osogbo wa labẹ rẹ.

"Ohun ti a n sọ ni pe ki awọn to n fi Osun Osogbo pa owo sọ fun wa nigba ti wọn ba n forukọ silẹ.

Eyi yoo le jẹ ki a sọ asọyepọ lori iye ti wọn yoo san fun ijọba ipinlẹ Osun ninu owo ti wọn ba lori fidio tabi ohun ti wọn ba gbe jade lori Osun Osogbo.

Ohun ti a ko fẹ ni pe ki wọn maa fi ayẹyẹ Osun Osogbo pa owo sapo, lai fun ijọba to ṣagbekalẹ eto ni nnkan kan níbẹ.

Ni ede kukuru, awọn ileeṣẹ iroyin lo fẹẹ jẹ wi pe ilana ti a gbe jade yii wa fun julọ."

Oyindamola ṣalaye siwaju si pe gbogbo awọn akoroyin to ba ti forukọ silẹ ni wọn yoo gba taagi fun idanimọ lasiko ti eto naa ba gberasọ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Keje yii Osun Osogbo ti ọdun yii yoo bẹrẹ.