Kí ló fa gbas-gbos láàárin Peter Obi àti Iléeṣẹ́ Ààrẹ?

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ Aarẹ orilẹede Naijiria ati oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni wọn ti bẹrẹ si ni ma sọko ọrọ si ara wọn lori ayelujara lori ifẹhonuhan ‘Ẹ fopin si ijọba buburu’ to fẹ waye.
Ifẹhonuhan yii ni awọn eeyan kan ti a ko le fidi wọn mulẹ gbero lati se fi tako bi nnkan se nira lọwọ yii lorilẹede Naijiria, ti ọpọ awọn araalu lori ayelujara si ti fi ifẹ han si ero naa.
Oṣu kẹjọ ni wọn gbero pe ki ifẹhonuhan naa waye ni gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria ati olu ilu Abuja.
Ko jẹ tuntun pe ọwọngogo ounjẹ n se ọpọ akoba nla fun araalu.
Ijọba apapọ, ileeṣẹ ọlọpaa ati ile igbimọ aṣofin kekere ti ṣekilọ lati tako ifẹhonuhan naa.
Bawo ni ọrọ yii se kan Peter Obi?
Agbẹnusọ fun Aarẹ Bola Tinubu, Bayo Onanuga lọjọ Satide fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Peter Obi pe awọn ni igi lẹyin ọgba ero ifẹhonuhan naa
Onanuga ninu ọrọ to gbe sori ayelujara ni ki awọn agbofinro na wọ mu Peter Obi ti ifẹhonuhan naa ba pada di wahala.
O rọ awọn araalu lati ma se tẹle ẹtan ẹgbẹ oṣelu Labour ati Peter Obi.
“Ẹ ma jẹ ki wọn tan yin jẹ: awọn kọlọrọsi ẹda to n gbero lati se se ifẹhonuhan ni wọn jẹ alatilẹyin Peter Obi, oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party to lulẹ.
Onanuga tun ṣekilọ pe ifẹhonuhan ni o ṣeeṣe ko da bi iwọde EndSars to waye lọdun 2020.
“Ko si orilẹede kankan lagbaye ti ko iṣoro eto ọrọ aje to mẹhẹ, ti ọwọngogo nnkan si bawọn finra.”

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bayo Onanuga
A wa ko mọ ohunkohun nipa ọrọ ti Onanuga sọ- Ẹgbẹ oṣelu Labour
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu Labour, Obiora Ifoh fi lede fun awọn akọroyin lati fi tako ọrọ Onanuga. Ifoh ṣalaye pe irọ to jina si otitọ ni ọrọ to n jade lẹnu agbẹnusọ Aarẹ.
“Alaafia ni wọn mọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Labour, ti a si ma n sọ fun awọn alatilẹyin pe ki wọn jẹ ki alaafia jọba ni gbogbo igba.
“A ki n se ẹgbẹ ti ko ni ibẹru fun ofin orilẹede Naijiria.
“A n fi asiko yii sọ pe ohun iyalẹnu lo jẹ pe ki eeyan kan ma sọ pe awọn eeyan lo n gbero lati se ifẹhonuhan.
“Peter Obi ati awọn ololufẹ ko lọwọ ninu ifẹhonuhan kankan.
“O di pe ijọba n wa eeyan kan lati da lẹbi lori ijọba buburu ti a n koju lorilẹede Naijria lonii.
“Naijiria si le gbe ilana to dara kalẹ. A wa tun n gba awọn oludamọran ijọba ni imọran pe ki wọn sọ ohun ti wọn ma sọ sita nitori o le da wahala si lẹ lori pe a n se oṣelu,”















