Ẹ fura ó! Àìsàn ibà tí kò gbóògùn ti wọ ilẹ̀ Africa

Ẹ̀fọn tó ń fa ibà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣe ìkìlọ̀ pé ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àwọn ènìyàn nílẹ̀ Africa wà nínú ewu nítorí pé àìsàn ibà tí kìí gbọ́ oògùn ti ń wọ ilẹ̀ Africa.

Wọ́n ní kòkòrò tó máa ń fa ibà tí oògùn “artemisin” kì í ṣiṣẹ́ fún ti wà ní ẹkùn ìlà oòrùn Africa.

Wọ́n ní ibà yìí ti lékún sí ìdá ogún láti ìdá kan ṣoṣo láàárín ọdún mẹ́ta.

Lásìkò tí oògùn kò ṣiṣẹ́ fún àìsàn ibà báyìí kẹ́yìn, iye àwọn ọmọdé tó pàdánù ẹ̀mí wọn ló lékún ní ìdá mẹ́ta.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa àìsàn ibà méjìdínlọ́gbọ̀n ló ń ṣe ìkìlọ̀ yìí nínú ìwé àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n ṣe.

Artemisin ló máa ń pa ẹ̀fọn tó máa ń fa ibà, òhun sì ni wọ́n máa ń fi ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

Nílẹ̀ Áfíríkà, orílẹ̀ èdè Rwanda ni ibà tí oògùn kò lè kojú rẹ̀ ti kọ́kọ́ ṣẹ́yọ kó tó di pé ó fojú hàn ní Uganda àti Eritrea.

Ibà náà ti tàn káàkiri àwọn orílẹ̀ èdè náà báyìí tó sì ti ń tàn wọ àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.

Ní báyìí, ohun tó lé ní ìdá mẹ́wàá àìsàn ibà ní orílẹ̀ èdè Ethiopia, Eritrea, Rwanda, Uganda àti Tanzania ló jẹ́ pé kòkòrò tí kìí gbọ́ oògùn ló fà á.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olugbenga Mokuolu ní ẹ̀ka ètò ìlera àwọn ọmọdé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ilorin ní àsìkò ti tó láti dìde sí ìṣòro yìí kó tó di pé ó máa gba ẹ̀mí àwọn èèyàn tán.

Ní ọdún 2016, irúfẹ́ àìsàn ibà yìí kò wọ́pọ̀ ní ẹkùn àríwá Uganda àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 2019 kòkòrò yìí ti lé ní ìdá ogún ní ẹkùn náà.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà sọ pé bí kòkòrò ibà náà ṣe ń tàn ni ó ṣeéṣe kí agbára má kà á láti da dúró.

Dókítà Mehul Dhorda tó wà láti ẹ̀ka ìwádìí ní Mahidol Oxford Tropical Medicine ní Thailand ní kò ì tíì yé bí yóò ṣe jẹ́.

Àmọ́ irú nǹkan báyìí náà ti wáyé ní ẹkùn gúúsù ìlà oòrùn Asia tí oògùn artemisin kò rán ìtọ́jú ibà.

Ọmọdé tó gbé àkọ́lé dání

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹ̀kọ́ látara nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn

Irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ rí nígbà tí oògùn chloroquine kò ṣiṣẹ́ fún àìsàn ibà mọ́ ní ìlà oòrùn Áfíríkà ní nǹkan bíi ọdún 1970 tó sì tàn dé ìwọ̀ oòrùn lọ́dún 1980.

Àwọn èèyàn tó ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ ibà lékún láti 493,000 lọ́dún 1980 di 1.6m lọ́dún 2004.

Dokita Dhorda ní òun rò pé irú nǹkan báyìí kò tún ní wáyé ní Áfíríkà nítorí tí artemisin kò bá ṣiṣẹ́ mọ́, ó túmọ̀ sí pé ikú yóò pọ̀ si.

Lára àwọn nǹkan tí àwọn onímọ̀ náà ń sọ láti fi kojú ìṣòro náà ni pé kí wọ́n fi oògùn mìíràn kún artemisin kí ẹ̀fọn tó ń fa ibà kò ní lè kojú.

Dókítà Dhorda ní ìnáwó rẹ̀ yóò lékún àmọ́ ó dára láti ná owó náà báyìí ju kí ẹ̀fọn náà tàn kalẹ̀ púpọ̀ lọ.

Àwọn nǹkan míì tí wọ́n tún ń bèèrè ni:

  • Pípèsè àwọ̀n apẹ̀fọn tí àwọn èèyàn lè fi máa sùn láti dènà ẹ̀fọn.
  • Láti pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára tó ń dènà ibà fún gbogbo ènìyàn dípò àwọn ọmọdé nìkan ni àwọn orílẹ̀ èdè tí kòkòrò náà ti wà.
  • Ṣe àtìlẹyìn fún àwọn elétò ìlera láti máa ṣiṣẹ́ wọn, kí gbogbo àwọn ènìyàn sì lè ní àǹfàní láti rí ìtọ́jú.