Ǹjẹ́ o mọ̀ nípa ìwòsàn tí wọ́n ń fi ìgbẹ́ ènìyàn ṣe àti àìsàn tó le mú ọ nílò rẹ̀?

Àwòrán àwọn ìgbẹ́ nínú ike

Oríṣun àwòrán, MTC/University of Birmingham

    • Author, Suneth Perera
    • Role, BBC World Service

Ètò fífa ìgbẹ́ láti ara ẹnìkan sí ẹlòmíràn lára jẹ́ ìmọ̀ tuntun lágboolé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

Rick Dallaway ló sọ èyí bó ṣe ń ṣèrántí ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ pè é láti wá darapọ̀ mọ́ ìwádìí tó níṣe pẹ̀lú fífi ìgbẹ́ sílẹ̀.

Rick, ẹni àádọ́ta ọdún náà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò olóṣù méjì nípa iṣẹ́ abẹ tó ní ṣe pẹ̀lú fífa ìgbẹ́ sára rẹ̀ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ìrètí láti fi ṣètọ́jú àìsàn ẹ̀dọ̀ kan tí orúkọ ń jẹ́ Primary Sclerosing Cholangitis tó ń ba fínra (PSC) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Birmingham tó wà ní England.

"Kìí ṣe ìgbẹ́ wóró kan ó," ó rẹ́rìn-ín bí ó ṣe ń ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ́ láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà.

Lọ́wọ́ yìí, àìsàn tó ń ṣe Rick jẹ́ èyí tí kò ní ìtọ́jú àyàfi tó bá ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi pàrọ̀ ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

Èèyàn mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn ni àìsàn náà máa ń mú ní orílẹ̀ èdè UK, tó sì máa ń mú ẹ̀mí kúrú si fún ọdún mẹ́tàdínlógún sí ogún.

Nígbà tí Rick wà ní ẹni ọdún méjìlélógójì ní ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn ni wọ́n ṣàwárí àìsàn náà lára rẹ̀.

"Àyà pá mi nígbà náà, ẹ̀rù bà mí nítorí mi ò mọ nǹkan tó wà níwájú mi."

Ọkùnrin tó ń wo ẹ̀rọ ayàwòrán

Oríṣun àwòrán, Rick Dallaway/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Rick ṣe ètò ìlera pípa gbígba ìgbẹ́ ènìyàn sára

Kí ni ètò ìwòsàn lílo ìgbẹ́?

Iṣẹ́ abẹ láti fi fa ìgbẹ́ sára èèyàn, Faecal Microbiota Transplant (FMT) jẹ́ iṣẹ́ abẹ tí wọ́n máa ń lò ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè láti fi ṣètọ́jú àwọn àìsàn tó níṣe pẹ̀lú inú.

Wọ́n máa gba ìgbẹ́ àwọn tó fẹ́ fi ìgbẹ́ sílẹ̀, ṣe àyẹ̀wò rẹ̀, tí wọ́n sì ma fi iṣẹ́ abẹ fi kòkòrò àìfojúrí bacteria tó wà fún inú nínú ìgbẹ́ náà sínú ẹlòmíràn nípasẹ̀ lílo colonoscopy, enema tàbí túùbù nasogastric.

Rick ṣe iṣẹ́ abẹ yìí láti fi ṣe ìtọ́jú PSC àmọ́ ìwòsàn kan péré ni àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní ètò náà wà fún.

Àwọn aláìsàn tó bá ní àìsàn Clostridium difficile ni wọ́n ní ànfàní láti gba ìtọ́jú yìí lábẹ́ òfin àjọ ètò ìlera ilẹ̀ UK.

Clostridium difficile jẹ́ kòkòrò àìfojúrí tó léwu tó lè fa ìgbẹ́ gbuuru, tó sì tún lè ṣàkóbá fún àwọn tó bá ti ń lo oògùn antibiotics fún ìgbà pípẹ́.

Ọ̀rọ̀ ìgbẹ́

Ó ṣeé ṣe kí èèyàn tó bá àìsàn tó níṣe láti pàrọ̀ ẹ̀dọ̀, kíndìnrín tàbí ọkàn rí ẹni fún wọn lásìkò.

Àmọ́ ìgbẹ́ èèyàn kò wọ́n rárá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbẹ́ ẹlòmíràn jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ kìí fẹ́ rí rárá.

Àmọ́ Rick ní ìgbàgbọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sì ṣe àtìlẹyìn fún un lórí ìgbìyànjú rẹ̀.

"Kò sí ọ̀rọ̀ ìtìjú níbẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mi ní tó bá jẹ́ nǹkan tó máa mú àlàáfíà bá mi nìyẹn ki n lọ ṣé," Rick ṣàlàyé.

Ibi tí wọ́n ń kó ìgbẹ́ pamọ́ sí

Obìnrin tó ń gbé ike ìgbẹ́ jáde nibi tí wọ́n ko pamọ́ sí

Oríṣun àwòrán, MTC/University of Birmingham

Microbiome Treatment Centre (MTC) tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Birmingham ni irú rẹ̀ àkọ́kọ́ tó ń pèsè ìgbẹ́ fún àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n nílò rẹ̀ láti fi ṣe ìtọ́jú àti iṣẹ́ ìwádìí.

Ẹni tó bá fẹ́ fi ìgbẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò tó fi mọ́ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ àti irú ìgbé ayé ẹni náà.

Lẹ́yìn àwọn àyẹ̀wò yìí, wọ́n máa gba ìgbẹ́ onítọ̀hún sílẹ̀ èyí tí wọ́n le tọ́jú fún odidi ọdún kan.

Tí aláìsàn bá nílò ìgbẹ́ náà, wọ́n máa lọ gbe nínú yìnyín tó wà láti fi sí ẹni náà lára.

Àwọn tó máa ń fi ìgbẹ́ sílẹ̀ náà ni wọ́n máa ń fún ní ẹ̀bùn.

Ipa FMT nínú PSC

Àwọn onímọ̀ ṣèkìlọ̀ pé àwọn aláìsàn tó bá ní irú àìsàn tó ń ṣe Rick, ìyẹn PSC ni ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní àìsàn tó máa ń mú inú èèyàn wú tó sì máa ń fa kí inú máa dun ènìyàn àti ìgbẹ́ gbuuru.

Dókítà Palak Trivedi tó wà lára àwọn onímọ̀ tó ń ṣètọ́jú Rick ní àwọn kò ì tíì mọ ìdí tí àwọn èèyàn fi máa ń ní PSC àti bó ṣe papọ̀ mọ́ IBD.

Ó ṣàlàyé pé àwọn kan máa ń fa ìgbẹ́ tí wọ́n ti ṣètọ́jú sínú ilé ìgbẹ́ ẹni tó bá ní àìsàn PSC láti ri bó ṣe máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀dọ̀ rẹ̀ tó ń ṣe òjòjò.

Àwòrán àwọn ohun èlò àyẹ̀wò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìlànà lórí ṣíṣe ètò ìwòsàn yìí

Dókítà Horace Williams tí ilé ẹ̀kọ́ Imperial College, London ní lásìkò yìí, iṣẹ́ abẹ ìgbẹ́ fífa kọ́ ni àwọn máa ń kọ́kọ́ ṣe fún ẹni tó bá ní ìpèníjà.

Dókítà Williams tẹmpẹlẹmọ pé ẹni tó bá ní àìsàn Clostridium difficile tó ti lágbára gan ni NHS máa n pèsè FMT fún.

Dókítà Benjamin Mullish náà sọ fún BBC pé àwọn èèyàn kan ti ń gbèrò láti máa ṣe FMT fúnra wọn, èyí tó ní ó léwu gidi.

Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé pé tí ẹni tí kò ní ìmọ̀ kíkún nípa FMT bá ṣe le ṣokùnfà ikú nígbà mìíràn.

Ìgbẹ́ ẹbí ẹni tàbí ti ẹni tí o kò mọ̀ rárá

Yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀ èdè Yúróòpù àti Amẹ́ríkà, wọ́n ti gbìyànjú FMT ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi Brazil, South Africa àti India.

Àwọn aláìsàn míì kìí fẹ́ tẹ́wọ́ gbà á nítorí ìgbàgbọ́ wọn lórí ìgbẹ́ àti àṣà.

Dókítà Piyush Ranjan ní àwọn aláìsàn máa ń rò pé àwọn ń ṣeré ni tí àwọn bá sọ ọ́.

Àwọn dókítà ń tọ́jú aláìsàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nígbà tó ń sọ ìrírí rẹ̀, Dókítà Ranjan ní àwọn èèyàn míì máa ń gbà láti lo ìgbẹ́ ẹbí wọn lòdì sí ti ẹni tí wọn kò mọ̀ rí rárá.

Ìwádìí kan fi hàn pé ọ̀pọ̀ ni kò ní ìmọ̀ nípa ìtọ́jú yìí tí àwọn tó sì mọ̀ ní ó tẹ́ àwọn lọ́rùn láti lo ìgbẹ́ ẹni tí wọn kò mọ̀ rí níwọ̀n ìgbà tí àyẹ̀wò bá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbẹ́ náà dára láti lò.

Rick ní òun ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí pé ìgbìyànjú náà máa tán ìṣòro ìlera òun.

"Tí èèyàn kan bá sọ fún mi ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn pé wọ́n máa má fi ìgbẹ́ ṣe ìwòsàn, mà á jiyàn àmọ́ ó ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí," Rick sọ.