Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ bí epo pupa tí o ń jẹ ṣe jáde? Àlàyé bí wọ́n ṣe ń ṣe epo rèé
Lode oni, epo pupa ni ohun isebẹ ti gbogbo agbaye n jẹ ju lọ.
Iroyin inu fidio yii ṣe ayẹwo bi wọn ti ṣe maa n ṣe epo, ibi ti o ti n wa ati bi o ṣe n gbera sọ di ohun adidudn inu ọbẹ.
Nibo ni epo pupa ti n jade wa – Ori igi ọpẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ara eso ẹyin ti wọn kọ lori igi ọpẹ ni wọn ti maa n ri epo pupa. Ẹkun iwọ oorun Afirika ni igi ọpẹ wulẹ ti gbilẹ, amọṣa lode oni o ti kaakairi awọn ilẹ olooru lagbaye lati lee koju bi awọn eeyan ṣe n fẹ ẹ si.
Ilana ṣiṣe epo pupa

Ẹyin ni wọn maa kọkọ n kọ ni oko. Idi ẹyin ti wọn ba kọ lori igi ọpẹ wọnyii ni wọn yoo ko lọ si ibi ti wọn yoo ti se e, tabi lọ si ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe epo pupa. Nibẹ ni wọn yoo ti yọ awọn ẹyin wọnyii kuro lara idi ẹyin ti wọn kọ bọ lati oko.

Ni kete ti wọn ba yọ ẹyin yii tan ni wọn yoo daa si inu ikoko ti wọn yoo fi se e ti wọn yoo si dana sii labẹ.

Lẹyin ti wọn ba se e tan ni wọn yoo ko o sinu ẹrọ ti yoo lọ ọ tabi ki wọn fi ẹsẹ tẹẹ gẹgẹ bi wọn ti n ṣe ni aye atijọ lati yọ epo ara rẹ.






