‘Ẹ gbà mí! Ipò tí ìlera ọkọ mi, Lawori, wà kò dára lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Koko Zaria fọ ìgò mọ́ lórí’

Lawori ati Koko Zaria

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lọsẹ to kọja ni fidio kan ṣafihan oṣere Yoruba, Lawori torukọ rẹ gan-an n jẹ Ibrahim Bello, nileewosan, nibi ti iyawo rẹ ti n sunkun pe ọkọ oun ko le sọrọ ko si laju mọ.

Iyawo Lawori, Arabinrin Afusat Opeyemi, ṣalaye ninu fidio naa pe lati igba ti wọn ti la igo mọ ọkọ oun lori ni ooyi ti n kọ ọ, to fi di ero ileewosan pada, ti ko si laju.

O rawọ ẹbẹ si ọmọ Naijiria lati ma ṣe jẹ ki ajunilọ fi ọwọ ọla gba oun loju.

Obinrin naa sọ pe ki wọn ma jẹ ki Lawori ṣe bẹẹ di ero ọrun nitori igo ti awọn ọmọ ẹyin Koko Zaria, iyẹn Ganiu Ayinde Oyedepo, gun un lẹyin agbo.

Lati mọ ipo ti ilera oṣere naa wa bayii lẹyin fido naa, BBC Yoruba kan si Lawori, ohun ti a mu bọ ree.

Lawori ati iyawo rẹ nileewosan

Oríṣun àwòrán, Others

Lawori ti lajú sáyé, ṣùgbọ́n...

Lawori ati Koko Zaria

Oríṣun àwòrán, The News Chronicle

L’Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keje ọdun 2024, BBC Yoruba pe aago Lawori lati mọ ipo ti ilera rẹ wa, ṣugbọn iyawo rẹ lo gbe e.

Abilekọ Afusat Ọpẹyẹmi tawọn eeyan mọ si Alujo-Adinni ti i ṣe iyawo Lawori, sọ pe loootọ, ọkọ oun ti laju saye pada lẹyin fidio to ṣafihan rẹ nileewosan lai laju.

O ni ṣugbọn agbara ko ti i si fun un lati maa gbe ipe awọn eeyan, nitori awọn dokita sọ pe eyi lewu pupọ fun ilera rẹ.

‘’ Wọn ti laju ṣugbọn awọn dokita kilọ fun mi pe mi o gbọdọ jẹ ki wọn maa ba gbe kọọlu awọn eeyan. Wọn ni ibi ti wọn ti fọ wọn nigo lori yẹn ko ti i san.

‘’Bakan naa ni wọn sọ pe ẹjẹ ti wọn padanu ti pọ ju, oun lo fa a ti wọn fi n daku.

Emi atawọn ọmọ la n gbe kọọlu wọn bayii, a n tẹle aṣẹ ti awọn dokita pa fun wa.

‘’Ikanra ti ọkọ mi fi n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn eeyan lo jẹ ki kinni yẹn tun le si i, nitori ẹ ni wọn ṣe ni ki wọn ma sọrọ bayii.’’

Bayii ni iyawo Lawori ṣalaye.

Irọ́ ni Koko Zaria ń pa, àwọn ọmọ ẹgbẹ rẹ̀ ló fọ́ ìgò mọ́ ọkọ mi lórí

Lawori

Oríṣun àwòrán, Lawori@Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n dahun ibeere nipa ohun to ṣẹlẹ gan-an nipa igo ti wọn ni wọn fọ mọ Lawori lori, iyawo rẹ ṣalaye pe, ‘’ Emi naa wa loju agbo yẹn, ohun to ṣẹlẹ ni pe Lawori ko darukọ Koko Zaria loju agbo naa.

‘’Gbogbo bawọn eeyan ṣe n pariwo Koko Zaria, ọkọ mi to n ṣe adari eto ko darukọ rẹ loju agbo naa. Ohun to fa a ni pe M.C Oluomo lọkọ mi n ba ṣe, nitori ọmọ Awori jọ ni wọn, bii aburo ni Lawori jẹ si MC, nitori ẹ ni ko ṣe darukọ Koko nibi to ti n ṣe MC.

‘’Koko Zaria ranṣẹ pe ki wọn lọọ pe Lawori wa, o ni ki lo de ti ko ṣe ki oun loju agbo. Lawori dẹ ni ko ma binu, oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn, ṣugbọn toun ba pada de oju agbo, oun aa lọọ darukọ Koko Zaria.

‘’Bo ṣe fẹẹ maa lọ ni ẹnikan fa a sẹyin ninu awọn ọmọ ẹyin Koko Zaria, o dẹ la igo nnkan mimu ẹlẹridido to wa nibẹ mọ ọn lori.’’

Gẹgẹ bi obinrin yii ṣe wi, o ni ẹyin agbo ni ibi ti Koko atawọn ọmọ ẹyin rẹ wa, wọn si ti di ibẹ pa to jẹ pe eeyan lasan ko le debẹ.

O ni eyi ni ko jẹ kawọn eeyan tete mọ ohun to n ṣẹlẹ, koda, Malaika to n kọrin gan-an ko mọ ohun to ṣẹlẹ bi Iyawo Lawori ṣe sọ.

‘’Koko Zaria naa lo ṣeto bi wọn ṣe gbe Lawori lọ sọsibitu, emi naa ko mọ ohun to ṣẹlẹ, mo kan ṣaa ri i pe Koko n pe foonu Lawori, ọwọ mi dẹ ni foonu naa wa. Igba ti mo de ẹyin agbo yẹn ni ọkọ mi sọ ohun to ṣẹlẹ fun mi.

‘’Koko ni ki n maa dupẹ pe nnkan ko ṣe e, awọn ti tọju ẹ.

‘’Nigba ti mo ri ori ọkọ mi ni mo ri i pe ẹjẹ ti bo o, mo ni mi o ni i gba. Koko waa n nawo fun mi, bẹẹ lo n dimu mu, ṣugbọn mo ṣaa yari, awọn eeyan lo n ṣa owo to n na fun mi.

‘’Irọ ni Koko n pa, awọn ọmọ ẹyin ẹ lo fọgo mọ ọkọ mi lori. Ẹyin naa ẹ wo o, ṣe o ṣee ṣe ki ẹnikan wa lati ita ko kan waa lago mọ eeyan lori ?’’

Bẹẹ ni Iyawo Lawori beere.

Koko Zaria náà ṣe fídíò, ó ní kí Lawori bẹ̀rù Ọlọ́run

Ninu fidio kan ti Koko Zaria fi sita lati tako ohun ti Lawori ati iyawo rẹ n wi lo ti ni ki wọn bẹru Ọlọrun.

Koko tawọn eeyan tun mọ si Zaga-zaa, beere pe ki ni Lawori ṣe foun toun yoo fi ni ki wọn fọ ọ nigo lori.

Koko sọ pe awọn eeyan kan ni wọn n ran Lawori ati iyawo rẹ niṣẹ buruku lati ba orukọ oun jẹ.

O ni iṣẹ toun ti ṣe fawọn kan ri, toun ko ṣe mọ bayii ni Lawori ṣẹṣẹ bẹrẹ si i ṣe ni tiẹ.

Boun ba waa mọ nipa igo ti wọn fọ mọ oṣere yii lori, Koko Zaria gbe ara rẹ ṣe pe, o ni ki gbogbo egun inu Kurani jẹ toun.

Bẹẹ ni Lawori naa ko si yee sọ pe Koko Zaria lo wa nidii igo ti wọn fọ mọ oun lori.

Ṣaa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ni awọn yoo tọpinpin ọrọ yii, ododo yoo si foju han.