Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sọ ìdí tí wọ́n fi gba N70,000 tí Tinubu buwọ́lù gẹ́gẹ́ owó oṣù tó kéré jùlọ

Aworan Bola Tinubu atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Dele Alake

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin o rẹyin, apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ti fẹnuko pẹlu ijọba apapọ lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ni ọsan Ọjọbọ ọjọ kejidinlogun oṣu Keje yii ni oludamọran aarẹ Bola Tinuba lori ọrọ iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Onanuga kede pe aarẹ ti buwọlu ẹgbẹrun un lọna aadọrin naira(N70,000) gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, aarẹ Tinubu ti n ṣe ipade pọ pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn o gba N62,000 ti igbimọ ti ijọba gbe dide lati ṣiṣẹ lori owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ gba ijọba ni imọran lati san iye naa.

Ikede owo yii waye lẹyin ipade ti Tinubu ṣe l’Ọjọbọ pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ nile ijọba niluu Abuja.

Ninu atẹjade ti Onanuga fi sita, o ṣalaye pe Aarẹ Tinubu ṣeleri lati maa ṣe ẹkunwo owo oṣu awọn oṣiṣẹ lọdun mẹta mẹta.

Ṣaaju ipade Ọjọbọ pẹlu Tinubu, N250,000 ni aarẹ NLC, Joe Ajaero ati akẹgbẹ rẹ ti TUC, Festus Usifo sọ pe awọn fẹ gba.

Aarẹ Tinubu tun ṣepade pẹlu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lọsẹ to kọja lori owo oṣu tuntun yii naa.

Nibi ipade ọhun ni Tinubu ti sọ pe awọn oṣiṣẹ orilẹede Naijiria nilo ẹkunwo owo oṣu ati ibi to rọrun lati maa ṣiṣẹ.

Bakan naa ni Tinubu sọ pe ijọba oun n ṣiṣẹ lori owo oṣu tawọn oṣiṣẹ yoo tẹwọ gba.

Idi ree ti a fi gba N70,000 ti Tinubu buwọlu gẹgẹ owo oṣu to kere julọ - Ajaero

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero ati akẹgbẹ rẹ ti TUC, Festus Usifo ṣalaye pe awọn gba N70,000 wọle gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ tori awọn nnkan moriya mii naa to wa pẹlu owo ọhun.

Ajaero ni ipinnu aarẹ Tinubu eyi to sọ pe ijọba yoo maa ṣe ẹkunwo owo oṣu lọdun mẹta mẹta jẹ ọkan gboogi lara idi tawọn fi gba N70,000 wọle.

Aarẹ NLC ni oun yoo lọ ṣalaye fawọn oṣiṣẹ pe N70,000 lawọn fẹnuko si pẹlu ijọba.

‘’A ṣe ipade pẹlu aarẹ lọsẹ to kọja nibi, a ṣi tun ti ṣe ipade miran lonii.

N70,000 ti ijọba apapọ kede lo ṣapejuwe ibi ti a wa lonii lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ.

Amọ, ohun to wa nibẹ ni pe a o ni duro di ọdun marun un mii ki a to tun sọrọ ẹkunwo owo oṣu.

N70,000 yii ni yoo rọpo N30,000 ti ijọba n san tẹlẹ ti ile aṣofin agba ba ti fontẹ lu u.

Ẹwẹ, minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ, Nkiruka Onyejeocha, ti sọ pe aarẹ ti kepe minisita eto inawo, Wale Edun, lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ agba ni fasiti, SSANU ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti ti ko ṣiṣẹ olukọni, NASU.

Tinubu atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ko fẹnuko lori owo oṣu tuntun ninu ipade ọsẹ to kọja

Ìpàdé láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tó wáyé ní ilé ìjọba ní ìlú Abuja lọ́sẹ̀ to kọjá kò fẹnukò síbì kan.

Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, Nigeria Labour Congress, Joe Ajaero àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ti Trade Union Congress, Festos Osifo ni wọ́n ṣaájú ikọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Tinubu lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Keje, ọdún 2024.

Níṣe ni ìrètí wà pé lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ìpàdé náà ni ààrẹ Tinubu yóò kéde pé àwọn ti fẹnuk]o pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àma tí èyí kò ṣẹlẹ̀.

Mínísítà fétò ìròyìn, Mohammed Idris tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà ṣàlàyé pé ìjíròrò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí owó oṣù náà àti pé ìpàdé tí ààrẹ ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ni láti fẹnukò lórí iye kan ní pàtó.

Idris ṣàlàyé pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní lẹ́yìn ìjíròrò wọn pẹ̀lú ààrẹ, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní kí ààrẹ fún àwọn ní ọ̀sẹ̀ láti lọ jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn kí wọ́n sì jábọ̀ padà nígbà náà.

Ó ní òun ní ìgbàgbọ́ pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan yìí, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba yóò fẹnukò lórí iye kan pàtó àti pé yóò so èso rere fáwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ẹ ó rántí pé láti bíi oṣù mélòó kan ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lórí owó oṣù tó kéré jùlọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà igba lé ní àádọ́ta náírà (N250,000) ni àwọn ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ àmọ́ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ aládani ní àwọn kò lè san ju ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) lọ.

Bákan náà ni àwọn gómìnà ní àwọn kò lè san ẹgbẹ́rùn méjìlélọ́gọ́ta (N62,000) tí ìjọba àpapọ̀ ní àwọn fẹ́ san.