Ooni sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn jìbìtì $180,000 t’óbìnrin kan fi kàn án, ó ní ó tún kọ̀ láti fẹ́ òun

Oríṣun àwòrán, ooniadimulaife/Instagram
Aafin Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi Ojaja Keji ti sọ pe Kabiyesi ko mọ ohunkohun nipa iroyin kan to ti lu ori ayelujara pa bayii pe Ooni lu arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Oladoyin Fagbule ni jibiti $180,000.
Otunba Moses Olafare to jẹ adari eto iroyin ni aafin Ooni lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita l’Ọjọru.
Gbajumọ ori itakun ayelujara X kan ti oju opo rẹ n jẹ 99% OPPRESSED lo sọ pe Ooni lu arabinrin naa ni jibiti lori idokowo, dukia ati ileri lati fẹ ẹ ni iyawo.
Bawo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ gan an?
@PIDONIFERIA 99% OPPRESSED lo sọ lori itakun ayelujara X ni Ọjọru pe, Ooni lu obinrin kan, Fagbule to jẹ dokita to ti n ṣiṣẹ lorilẹede Amẹrika fun bi ọdun mẹrindinlogun ni jibiti $180,000 lori idokowo, dukia ati ileri lati fi ṣe aya.
Obinrin ọhun ti wọn ni o wa lati Ile-Ife,ipinlẹ Osun ni a gbọ pe o n gbero lati da ile iwosan silẹ kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ lati ipinlẹ Osun to jẹ orirun rẹ.
Eyi ni 99% OPPRESSED ni o fẹ bẹrẹ nipa pipese iwosan ọfẹ fawọn obinrin atawọn ọmọde niluu Ile-Ife ki o to pada da ile iwosan silẹ nibẹ.
Lẹyin iwadii rẹ nipa bi o ṣe le ṣe agbekalẹ eto yii ni wọn sọ fun un wi pe ko kan si Ooni lọri ọrọ naa.
99% OPPRESSED ni bayii ni obinrin yii kan si Ooni lori Facebook ti o ṣi ṣalaye ohun to fẹẹ ṣe fun kabiesi.
Iroyin sọ pe Kabiesi naa ni gbolohun pẹlu rẹ wi pe oun ṣetan lati ṣe iranwọ fun un lori ohun to fẹ ṣe niluu Ile-Ife.
Koda, wọn ni Kabiesi gba a ni imọran pe ko da ile iwosan naa silẹ lopopona ilu Ibadan si Eko tori bi ijamba ọkọ ṣe maa n ṣẹlẹ nibẹ ni gbogbo igba.
"Bayii ni arabinrin yii bẹrẹ sii fi owo ranṣẹ si Ooni pẹlu igbagbọ wi pe Kabiesi ti n ba iṣẹ lọ lori ọrọ ti wọn jọ sọ.
Ooni ṣe oriṣiriṣi ayederu iwe dukia to fi mọ risiiti lati le maa ri owo gba lọwọ obinrin yii.
Obinrin yii ko tii yọju si Naijiria pẹlu bi o ṣe n fi owo ranṣẹ si kabiesi to" ẹni to loju opo 99% OPPRESSED lo ṣalaye bẹẹ lori itakun ayelujara X.
Iwe kan ti wọn ni Fagbule sọ pe Ooni kọ lati ṣeleri fun un pe oun ṣetan lati fẹ ẹ gẹgẹ bi iyawo naa wa lori ayelujara.
Koda, lẹta ọhun ni ibuwọlu eyi ti orukọ Ooni wa nibẹ ninu.

Oríṣun àwòrán, Pidomnigeria/X

Oríṣun àwòrán, X
Aafin Ooni fesi lori ẹsun jibiti $180,000 ti wọn fi kan an
Otunba Moses Olafare to jẹ adari eto iroyin ni aafin Ooni ti sọ pe irọ to jinna si ootọ ni iroyin to lu ori ayelujara pa nipa kabiesi Oonirisa.
Otunba Olafare fidi rẹ mulẹ pe arabinrin Fagbule ti ko sọwọ awọn onijibiti ti wọn n pe ara wọn ni Ooni ni.
O ni o ṣeni laanu pe ọpọ obinrin lo ṣi tun n ko sọwọ awọn onijibiti lori ayelujara, bi aafin ṣe ti n kilọ fawọn obinrin ti wọn ṣa fẹ di olori laafin Ooni pẹlu tipatipa.
‘’Bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe aṣa wa lati maa fesi si iroyin ofege nipa Oonirisa, amọ, o ṣe pataki lati tan imọle si ọrọ yii tori ọpọ ololufe Ooni ti wọn ti n kọminu lati igba ti iroyin ọhun ti jade.
"A n fi asiko yii sọ pe iroyin ti @99% OPPRESSED gbe jade loju opo X rẹ ko ribẹ rara, iroyin ofege ni.
O lo iroyin naa lati jẹ ki ọpọ eeyan le maa tẹle e ni, ati ibanilorukọjẹ ni iroyin ọhun.
Ooni ko mọ ẹni to n jẹ Fagbule, debi wi pe kabiesi yoo ba a sọrọ ati fi ṣe aya,’’ Otunba Olafare ṣalaye.
Otunba Olafare tun fikun ọrọ rẹ pe Ooni kii lo Facebook fun ra rẹ, tori awọn eeyan kan wa to jẹ wi pe iṣẹ ti wọn ni lati maa mojuto oju opo kabiesi lori itakun ayelujara rẹ bii Instagram, Facebook ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Otunba Olafare sọ ninu atẹjade to fi sita pe dipo ki Fagbule lo ileeṣẹ ọlọpaa, tabi ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lati ri idajọ òdodo lori awọn to lu u ni jibiti, ẹni ti ẹnikan o mọ ti o kan pe orukọ ara rẹ ni 99% OPPRESSED lori oju opo ayelujara X lo lọ ba.
Adari eto iroyin láàfin Ooni tun sọ pe Fagbule tun kọ lati fi ọrọ rẹ lọ awon gbajugbaja agbẹjọro ati ajafẹtọọ ọmọniyan bii Femi Falana ti wọn ko ni fi igba kan bọ ọkan nínu.
"Irọ nla to jina si ootọ ni lẹta to wa loju opo 99% OPPRESSED lori itakun ayelujara X eleyii to sọ pe iwe naa ni Ooni kọ si Arabinrin Fagbule lati ṣeleri pe oun yoo fi ṣe aya.
Kii ṣe iru iwe ti Ooni maa fi n kọ lẹta ni iwe ti wọn ṣafihan rẹ loju opo X 99% OPPRESSED yẹn.
Pẹlu bi Ooni ṣe lowo to ti Eledua ṣi kẹ ẹ pẹlu ọrọ, ki i ṣe iru ọba alaye bii Ooni ni yoo maa beere owo lọwọ enikan lati le rinrin ajo tori o fẹ fi obinrin kan ṣe aya.
Ti o ba jẹ pe lotitọ ni awọn kan lu Fagbule ni jibiti pẹlu ileri lati fẹ ẹ, Kabiesi ti sọ fun un pe ko wa si aafin ni Ile-Ife ki awọn le ran an lọwọ pẹlu atilẹyin awon agbofinro lati mu awọn ọdaran naa.
A tun n lo asiko yii lati sọ fun gbogbo eeyan kaakiri agbaye pe Ooni ki i ba ẹnikẹni sọrọ lori itakun ayelujara, bẹẹ ni kabiesi ki i si ran ẹnikẹni lati ṣe bẹẹ, ni orukọ rẹ" Otunba Olafare ṣalaye.















