Wo ìdí tí MURIC fi n wọ́dìí Makinde lórí orúkọ tó sọ mọ́ṣáláṣí Adogba n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/FACEBOOK
Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn Mùsùlùmí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ìyẹn Muslim Rights Organization of Nigeria (MURIC), ti fariga lórí ìpinnu ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo láti yí orúkọ mọ́ṣáláṣí kan padà sí orúkọ gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Seyi Makinde.
MURIC ní mọ́ṣáláṣí ńlá náà tó wà ní Iwo road, ààrin gbùngbùn ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo, ni àwọn kò faramọ́ bí ìjọba ṣe yí orúkọ rẹ̀ padà.
Wọ́n ní kí ìjọba yí orúkọ náà padà kúrò ní orúkọ gómìnà Seyi Makinde, kí wọ́n da orúkọ rẹ̀ padà sí èyí tó wà tẹ́lẹ̀.
Àjọ náà fẹ̀sùn kàn gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde pé ó ń dá sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn Islam nítorí pé bí ó ṣe fi orúkọ ara rẹ̀ sọ mọ́ṣáláṣí Adogba nígbà tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi jẹ́ àbùkù ńlá sí àwọn Mùsùlùmí tó wà ní ìpínlẹ̀ náà.
Fún ìdí èyí, MURIC rọ gómìnà Makinde láti pàṣẹ pé kí wọ́n yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lára ògiri mọ́ṣáláṣí ọ̀hún.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ adarí àgbà ẹgbẹ́ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Akintola ni MURIC ti ní àwọn kò faramọ́ bí gómìnà Makinde ṣe sọ mọ́ṣáláṣí náà ní orúkọ ara rẹ̀ àti pé àwọn kò faramọ́ ìpinnu náà rárá.
“Kì í ṣe owó Seyi Makinde ni wọ́n fi tún mọ́ṣáláṣí náà kọ́, owó ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ni.
“Àti pé kìí ṣe Mùsùlùmí, ó kàn lò ó gẹ́gẹ́ bí i irinṣẹ́ òṣèlú ni. Mọ́ṣáláṣí náà tí wà nínú ìlú láti ọdún pípẹ́ láìsí wàhálà,” àtẹ̀jáde náà sọ.
Wọ́n fi kun pé àwọn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí kìí ṣe Mùsùlùmí ni yóò máa fi mọ́ṣáláṣí náà bú àwọn Mùsùlùmí bí orúkọ Seyi Makinde bá wà lára rẹ̀ pé ọmọlẹ́yìn Kristi ló kọ́ mọ́ṣáláṣí fún àwọn.
MURIC ní nǹkan tí àwọn ń fẹ́ ni pé kí gómìnà Makinde yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lára mọ́ṣáláṣí náà pátápátá.
Ẹ ó rántí pé lọ́dún 2019 ni ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo wó mọ́ṣáláṣí ńlá Adogba tó wà ní Iwo road, Ibadan láti fàyè gba ibùdókọ̀ ńlá tí ìjọba fẹ́ kọ́ sí agbègbè náà.
Ní báyìí, ìjọba ti kọ́ mọ́ṣáláṣí mìíràn láti fi dípò èyí tí wọ́n wó náà.
Níbi mọ́ṣáláṣí tuntun yìí, ààyè ilé kéwú wà níbẹ̀, ẹ̀ka láti ṣe ìwádìí wà níbẹ̀, yàrá ìkàwé wà níbẹ̀, yàrá ìpàdé wà níbẹ̀, àtàwọn nǹkan míì tí ẹgbẹ́ náà ń kan sáárá sí ìjọba fún.
Níbi ìpàdé kan lọ́dún 2019 ni gómìnà Makinde kéde pé àwọn yóò wó mọ́ṣáláṣí àti ṣọ́ọ̀ṣì Adogba tó wà ní Iwo road láti fàyè gba ibùdókọ̀ tí wọ́n fẹ́ kọ́.
Gbogbo ìgbìyànjú BBC láti bá ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo sọ̀rọ̀ lórí mọ́ṣáláṣí tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ padà náà ló já sí pàbó.
Ẹgbẹ́ àwọn Mùsùlùmí náà ní kìí ṣe pé inú àwọn kò dùn sí bí wọ́n ṣe tún mọ́ṣáláṣí náà kọ́ àmọ́ àwọn kò faramọ́ bí gómìnà ṣe sọ mọ́ṣáláṣí náà ní orúkọ ara rẹ̀.














