Àwọn alátakò mi lágbo òṣèlú ló ní kí afurasí agbénípa dárúkọ mi gẹ́gẹ́ bíi bàbá ìṣàlẹ̀ wọn – Aṣòfin Osun

Oríṣun àwòrán, olusanyaomirin/Instagram
Lori awuyewuye to n lọ nipa bi Bode Owoeye tawọn eeyan mọ si Bode Itaapa, ti sọ pe oloṣelu pataki kan nipinlẹ Ọṣun, Aṣofin Sanya Omirin, ni ẹni to n ran awọn tawọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye niṣẹ, Họnọrebu naa ti sọ pe awọn alatako oun lagbo oṣelu lo wa nidi ọrọ naa.
Họnọrebu Omiran sọ fun BBC Yoruba pe ''awọn alatako mi ti wọn ko ara wọn jọ lagbo oṣelu lo wa nidii ọrọ yii.
Mi o mọ ohun kohun lori ọrọ yii o, ṣe awọn eeyan to dibo fun mi ni ma a sọ pe ki wọn lọ maa pa?
Awọn oloṣelu APC kan ri mi gẹgẹ bi iṣoro wọn wi pe ti wọn o ba ri nnkan sọ si mi, wọn le ma ri ọna lọ.
Awọn oloṣelu APC lo darukọ mi, kii ṣe afurasi ọdaran yẹn, amọ, ọrọ ko tii to sọ.
Awọn oloṣelu APC yii lo n lo awọn ọlọpaa lori ọrọ yii.
Amọ, wọn o bẹru Ọlọrun. Igbagbọ mi ni pe bi irọ ba lọ fun ogun ọdun, ọjọ ṣoṣo ni otitọ yoo le ba.
Afurasí agbénipa dárúkọ gbajúmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun gẹ́gẹ́ bíi bàbá ìsàlẹ̀ wọn, aṣòfin náà ti fèsì

Oríṣun àwòrán, Police
Ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Keje 2024 ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, fi oju awọn afurasi ọdaran kan han ni olu ileeṣẹ naa l’Oṣogbo.
Lasiko ifihan naa ni ọkan lara awọn tọwọ ba, Bode Owoeye tawọn eeyan mọ si Bode Itaapa, ti sọ pe oloṣelu pataki kan nipinlẹ Ọṣun, Aṣofin Sanya Omirin, ni ẹni to n ran awọn tawọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye niṣẹ.
Sanya Omirin lo n ṣoju ẹkun Guusu Ileṣa, l’Abuja, gbajumọ si ni wọn pe e nipinlẹ Ọṣun.

Oríṣun àwòrán, Police
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Osun, SP Yemisi Opalola fi ṣọwọ si BBC Yoruba, lo ti fidi ẹ mulẹ pe Bode Itapa darukọ Omirin gẹgẹ bii ẹni to n ran oun atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye yooku niṣẹ.
O fi kun un pe orukọ Bode Itaapa ti wa lara awọn ọdaran ti ileeṣẹ ọlọpaa n wa tipẹ.
Atẹjade naa ṣalaye bi afurasi yii ṣe jẹwọ pe Aṣofin Omirin maa n ran awọn niṣẹ ibi lati ipasẹ akẹgbẹ awọn torukọ ẹ n jẹ Adefioye Solomon ( Solo Iwara).
O ni Solo to ti sa lọ bayii, mọ nipa ipaniyan ọlọkan-o-jọkan to ti waye n’Ileṣa, ati pe Omirin lo maa n paṣẹ bi awọn yoo ṣe lọọ huwa ibi fun Solo, iyẹn naa yoo si waa jiṣẹ oloṣelu naa fawọn.
Bakan naa ni atẹjade yii ṣalaye bawọn ọmọ ẹgbẹ Aye ṣe n ji awọn eeyan gbe nipinlẹ Ọṣun, ti wọn n pa wọn sinu igbo pẹlu.
Afurasi to jẹwọ naa tun sọ pe ikọ awọn lo yinbọn fun Ayodeji Olaolu, ọmọ ẹgbẹ APC to n dije fun ile igbimọ aṣoju ni 2023.
Ori ati aya lo ni awọn ti yinbọn fun oloṣelu naa.
Bode Itaapa tun jẹwọ pe o le ni ibọn ọgbọn ti ẹgbẹ okunkun awọn ra ṣaaju idibo 2023.
Kí ni Aṣofin Omirin sọ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án?
Aṣofin Omirin ti fesi si ẹsun ti Itaapa fi kan an pe oun ni ẹni to n ran awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye niṣẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Họnọrebu Omirin ni ko ṣee ṣe ki Itaapa darukọ oun pe oun loun n ran wọn niṣẹ.
‘’Idi ni wi pe ọmọkunrin ti wọn n sọ yii, ko de ile mi ri, mi o ni nọmba foonu rẹ lọwọ, ati pe emi ati ọmọ naa ko jọ sọrọ ri.
Mi o ṣi ninu ẹgbẹ okunkun ri laye mi, mi o ṣi ni ṣe e laelae,’’ Omirin lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe oun ti figba ri jẹ akọwẹ ijọba ibilẹ, bẹẹ naa loun tun ti ṣe kọmiṣọna ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ awọn awọn ijọba ibilẹ.
Họnọrebu Omirin sọ pe lẹyin naa loun di alaga ijọba ibilẹ.
Aṣofin naa ni ko si ohun to le ni koun lọ maa ṣe baba isalẹ awọn ẹlẹgbẹ okunkun nibi ti ọjọ ori oun de bayii.
‘’Ọrọ awọn ẹlẹgbẹ okunkun lo n ṣẹlẹ ni ilẹ Ijẹṣa, mi o fẹ ki wọn tọwọ oṣelu bọ iwa ọdaran.
Ẹni ti wọn ba ti mu pe o tapa sofin, ni ṣe lo yẹ ki wọn ṣe iwadii ki wọn ṣi ba a wi labẹ ofin.
Ẹwẹ, aṣofin Omirin ti sọ pe oun yoo gbe igbesẹ lori ọrọ naa to ba to asiko.
Ta a ni Ọnarebu Sanya Omirin?
Ilu ileṣa, nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti bi Emmanuel Sanya Omirin.
O kẹkọọ nipa imọ iṣiro nile ẹkọ Yaba College of Technology, bakan naa lo lọ si yunifasiti Ado-Ekiti pẹlu.
Ilu Abuja ni Sanya Omirin n gbe, ibẹ naa lo ti n ṣoju ẹkun Guusu Ileṣa bayii.
O ti figba kan ṣe alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa, ọkan lara awọn olutẹle gomina Ọṣun tẹlẹ, Gboyega Oyetola, ni.
Lọdun 2022 ni iroyin kan jade lori ayelujara, pe Omirin lọwọ ninu iku oloṣelu kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Job Akinola.
Ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ ni Omirin ti sọ pe awọn ti wọn fẹẹ ba orukọ oun jẹ ni wọn wa nidii iroyin naa.
O ni nitori oun n tẹle Oyetola, ti eru si n ba won pe gomina tẹlẹ naa yoo wọle lẹẹkeji ni wọn ṣe n tabuku orukọ oun.
Báwo ni ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ àwọn afurasi naa?
SP Yemisi Opalola, ṣalaye pe awọn kan ni wọn mu ẹjọ lọ si agọ ọlọpaa Iperindo, ti wọn ni ọmọ awọn meji, Kelechi Agha ati Tega Robinson, kuro nile lọjọ kẹjọ, oṣu Keji ọdun 2024, wọn ko si pada wa sile mọ .
Opalola sọ pe awọn taari ẹjọ naa si ẹka to n ri si ijinigbe, iwadii to fẹsẹ mulẹ si fi han pe lọjọ naa gan-an ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye bẹrẹ si i yan fanda nigboro pẹlu nnkan ija lọwọ.
Eyi lo ni o mu awọn ọlọpaa maa wa ibuba awọn awon ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kiri, nibi ti wọn ti ri ibọn ilewọ ibilẹ kan ati iboju.
Lẹyin eyi lọwọ ba Bode Owoeye tawọn eeyan mọ si Itapa, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye, pẹlu awọn meji mi-in torukọ wọn n jẹ Lateef Mukaila ati Daviv Samuel.
Ibọn kan (pump action), alupupu TVS kan, ibọn ilewọ ibilẹ kan pẹlu ọta ibọn mẹta,ati ibọn ọlọta kan pẹlu jiipu Highlander kan, iboju dudu, baagi meji pẹlu awọn oogun abẹnugọngọ ni awọn ọlọpaa kede pe awọn ri gba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa.
SP Opalola si ni won yoo tóó foju bale-ẹjọ.















