Kò ṣe e má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe e má gbọ̀ọ́
Kò ṣe e má gbọ̀ọ́

Lori koṣe ma gbọ ọ wa ti ọsẹ yii

N jẹ ẹ ti gbọ?

Pe kinni?

Niluu Ilorin, Ibanujẹ ma dori agba kodo lẹyin ti iran mẹta dero ọrun

Haa, ki lo sẹlẹ? Ba mi tan imọlẹ si i

Iṣẹlẹ yii wa lẹyin ti Halimat Yusuf, ọmọ rẹ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn,

Ati ọmọ-ọmọ , ẹni ọdun mẹwaa jẹ amala tan.

Lobatan, Kan si oju opo BBC.COM/YORUBA

Lati mọ ohun ti iwadi sọ pe o sokunfa iṣẹlẹ naa

O ya ẹ sumọ mọ bi, ki ẹ tẹti o

Ki ni a tun ri gbọ lọtẹ yii o

Njẹ o mọ pe Ijiya nla lo wa labẹ ofin orilẹede Naijiria

Fawọn eeyan to n gbe asia orilẹede mii soke lasiko iwode EndbadGovernance

Ọga ologun lorilẹede Naijiria, Ọgagun Christopher Mustapha lo se ikilọ yii fun araalu pe ki wọn so agbejẹ mọwọ o

Sugbọn dakun, iru ijiya wo gan lo wa labẹ ofin ti ẹnu rẹ ko gba

Kan si oju opo BBC.COM/ YORUBA lati mọ ijiya ọhun