Bí o bá fi Cucumber rọ́pò tòmátò nínú ọbẹ̀, wo ohun tí yóò ṣe fún àgọ̀ ara rẹ

Aworan ọwọ to n fa cucumber lilọ sinu ata lori ina

Bi ohun ti a n jẹ ba tan, ki eyi ti a ki i jẹ tẹlẹ ma ṣafira ni Yoruba n wi.

Ọwọngogo ounjẹ to fi mọ ata ati tomato ti kọ ọpọ eeyan lọgbọn mii ti wọn le fi sebẹ lai lo tomato, lara rẹ ni eso Cucumber wa.

Awọn eeyan lorilẹede Naijirian ti bẹrẹ si ni lo cucumber lati se ọbẹ bayii.

Bi wọn ṣe n le tomato ti ko ju ẹyọ mẹta lọ ni ẹẹdẹgbẹta naira (500n) lo mu awọn araalu ronu kan cucumber, ìgbá, karọọti ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn jẹ eso jijẹ lasan.

Bi o ba wa n fi cucumber to jẹ eso to si kun fun omi se ọbẹ,ki ni yoo ṣẹlẹ? Ipa wo ni yoo ni lori ilera rẹ ni ayọka yii fẹẹ ṣalaye.

Ṣugbọn ṣaaju eyi, bawo gan-an ni wọn ṣe n fi cucumber din ata ọbẹ?

Bí a ṣe ń fi cucumber dín ata ọbẹ̀ rèé

Aworan cucumber, ata ati awọn eroja ọbẹ mi-in

*Fọ cucumber rẹ daadaa ki o si ge e si wẹwẹ.

*Lọ ọ ko kunna daadaa.

*Fi asẹ sẹ omi to jade nibẹ, ma lo gbogbo ẹ tan ki omi pupọ inu cucumber ma baa mu ọbẹ rẹ ṣan.

*Gbe epo tabi ororo kana, jẹ ko gbona diẹ.

Rẹ alubọsa si i ko din diẹ.

Da ata si i pẹlu awọn eroja amọbẹdun ti o fẹẹ lo, ro o papọ lori ina nibẹ.

Fi iyọ si i .

*Asiko to wayi lati da cucumber ti o lọ (ti omi ko pọ ju nibẹ) sinu ata ọbẹ rẹ.

*Bẹrẹ si i ro o pọ lori ina ki gbogbo eroja to wa nibẹ le papọ.

*Fi ẹja, ẹran atawọn nnkan mi-in to o ba tun fẹẹ lo si i.

Ro o pọ diẹ ko o si de e pa titi ti yoo fi jinná.

*Lẹyin iṣẹju diẹ, sọ ọ kalẹ, ọbẹ rẹ ti delẹ.

Iyatọ kan ko si ninu ilana ọbẹ ata sise ati eyi, bi ko ṣe cucumber ti a fi rọpo tomato nikan .

Àǹfààní cucumber lára

Eso cucumber

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ọna to daa ju lati gbadun cucumber ni keeyan jẹ ni tutu bi eso, keeyan le ri anfaani to kun ara rẹ jẹ ninu ara.

Eeyan ko nilo lati bo eepo ara rẹ keeyan too jẹ ẹ ni tutu, awọn mi-in a si maa lo o fun salaadi ṣiṣe.

Ida mẹrindinlọgọrun-un (96%) cucumber jẹ omi, ẹya eso ati ewebe ni awọn onimọ nipa ounjẹ si ka a si.

Cucumber n pese eroja fitamin C fun ara. O n pese fitamin A pẹlu.

O ni eroja potassium, manganese, folate, dietry fiber ati magnesium.

Cucumber tun ni eroja kan to n din ọra ku ninu ara. Ko yẹ ki o maa bo eepo rẹ ki o too jẹ ẹ lati ri anfaani yii.

Eso yii tun daa fun dindin ara sisan ku.

Àǹfààní tomato lára

Aworan tomato

Oríṣun àwòrán, Getty image

*Tomato n ṣiṣẹ fun ọkan eeyan. Beeyan ba n jẹ ẹ, o maa n din ewu aisan ọkan ati ti rọpa-rọsẹ ku.

* O maa n jẹ ki oju mọlẹ kedere, dena aisan oju.

*Tomato n mu ara jọ̀lọ̀.

* O maa n jẹ ki oju ọgbẹ tete san nitori eroja fitamin k to wa ninu rẹ.

*Tomato jijẹ le sun asiko ti obinrin ko ni i ri nnkan oṣu rẹ mọ siwaju .

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí o bá ń se èso lórí iná?

Aworan obinrin to n bu ọbẹ sinu awo

Temiloluwa Omotoso,obinrin onimọ nipa ounjẹ ati iṣẹ to n ṣe lara, ṣalaye fun BBC pe gbogbo anfaani ti cucumber ni yoo sọnu beeyan ba n se e lori ina lati fi rọpo tomato.

O ni eyi yoo ri bẹẹ nitori ina to la kọja, ti yoo pa gbogbo eroja ti a ṣalaye pe o ni lara.

" Ọna to daa ju lati jẹ awọn eso bii cucumber ni keeyan jẹ ẹ ni tutu bo ṣe wa, ko le baa ṣe ara loore.

‘’Nitori o ni awọn fitamin kan to jẹ bi ina ba fi le kan wọn, wọn maa ṣan danu ni.Ko si ni i ṣe ara loore kankan mọ.

"Bi o ba n gbe cucumber kana lati se e lọbẹ tabi lọna yoowu ko jẹ, gbogbo fitamin ti ara rẹ nilo ninu eso naa yoo ti ba sise lọ.’’

Awọn eso kan wa ti wọn ko tiẹ gbọdọ sunmọ ina rara,keeyan jẹ wọn ni tutu lo ti daa."

Bẹẹ ni Temilolouwa ṣalaye fun BBC.

Àwọn èso wo ló ṣee sè lórí iná?

Kerry Torrens, akọṣẹmọṣẹ onimọ nipa ounjẹ, ṣalaye fun BBC pe awọn eso bii karọọti, tomato ewebẹ oyinbo ti a mọ si brocolli, le gba ina diẹ sara nipa bíbọ̀ wọn.

O ni ṣugbọn cucumber ko si ninu eso teeyan n se lori ina rara.

Torrens sọ pe loootọ ni sise ounjẹ lori ina maa n pa awọn kokoro kan ninu ounjẹ, o ni ṣugbọn eeyan gbọdọ mọ iru ohun to ṣee se lori ina, ateyi to yẹ keeyan jẹ ni tutu bẹẹ.

Bi ọrọ aje ṣe n le koko si i ti nnkan ko dẹrun, sibẹ, o ṣe pataki lati mọ ohun to yẹ ki o jẹ ti yoo fun ọ ni alaafia ara.