Wo àwọn ìdì tí ìfun inú rẹ ṣe ṣe pàtàkì àti bí o ṣe lè jẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa

Aworan inu eeyan ti wọn fọwọ ya ifun si

Oríṣun àwòrán, Getty image

    • Author, Onur Erem
    • Role, BBC World Service

Ohun ti a ba jẹ sikun ni i so ẹmi ro, beeyan ba si n jẹ ohun ti ko daa sikun rẹ, bii ẹni to n ge okun ẹmi kuru ni, nitori ailera yoo tibẹ maa ba ẹni bẹẹ ja.

Iwadii fi han pe ifun eeyan ni i ṣe pẹlu awọn ọra kan to wa ninu ẹjẹ (blood lipids) ati ọpọlọ pẹlu.

Bi imọ ijinlẹ ṣe n tẹsiwaju, bẹẹ ni iwadii n fi ipo ti ilera ikun eeyan wa han, bẹẹ naa si lo n fi ti ifun han pẹlu.

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ìfun rẹ ní àlááfìà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Aworan ifun eeyan

Oríṣun àwòrán, Getty image

Pẹlu bi Iṣẹda ṣe ṣeto ifun eniyan ti gbogbo rẹ wọnu ara wọn, o ṣoro lati mọ bi ifun eeyan kan ṣe ni alaafia to.

Ifun yatọ si awọn ẹya ara yooku to ṣee sare foju mọ, bẹẹ ni ko si irinṣẹ kan to le sọ ipo ilera ifun.

Ohun kan to foju han ni pe awọn eroja kẹmika pọ ninu ifun, to jẹ ti a ba ni ka gbe e si ori iwọn, yoo le ni kilo kan ati mẹjọ. (1.8kg).

Bakan naa ni awọn kinni kan naa wa ti a mọ si bakteria (bacteria) to to ọgọrun biliọnu ninu iwọn kọọkan ifun eniyan.

Dokita kan, Katerina Johnson, ẹni to maa n wadii ibaṣẹpọ ifun ati ọpọlọ eeyan ni Yunifasiti Oxford, ṣalaye pe,

" Imọ ijinlẹ nipa ifun ko ti i fi bẹẹ ri iṣẹ iwadii kikun, a ko ni akọsilẹ kikun lori bi ifun to ni alaafia ṣe maa n ri’’

Kí ló dé tí ìfun ṣe gbọ́dọ̀ ní àlááfíà?

Aworan ifun ati kokoro aifojuri

Oríṣun àwòrán, Getty image

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"O fẹrẹ jẹ pe gbogbo ẹya ara wa pata ni ifun ṣe pataki fun", Dokita Johnson lo ṣalaye bẹẹ.

O ni ọpọlọ eeyan pẹlu ifun ni ajọṣepọ kan, eyi ni awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi n pe bi "gut-brain connection".

Awọn nnkan meji yii ṣe pataki fun gbogbo eeyan.

Iwadii ti fi han pe iṣẹ ọpọlọ ko ni i pe bi awọn eroja kan ko ba si ninu ifun.

Nigba miran gan-an, wọn aa maa pe ifun ni ọpọlọ keji, nitori bakteria le ko ba iṣẹ ifun nipasẹ ọgọrun-un kan eroja neuron to wa ninu ifun.

Abala ibi ti a ti n ranti nnkan ni awọn neuron yii maa n wa, ibẹ gan-an si ni irori n gba kọja kari ara.

Ojulowo iṣẹ ifun ni pe ko ṣe afọmọ awọn eyi to daa ninu ounjẹ ti a ba jẹ.

Dokita Venkatraman Krishna, gbajugbaja onimọ nipa inu eeyan lorilẹede India, ṣalaye pe,

" A ki i padanu omi ati awọn eroja to daa ninu ifun’’

Bakan naa ni Dokita Megan Rossi, gbajugbaja onimọ nipa inu lorilẹde UK, sọ pe beeyan ko ba ni awọn kẹmika to yẹ ninu ifun rẹ, aisan nla bii aadọrin (70) lo ni o ṣee ṣe ko maa daamu ẹni bẹẹ.

Awọn aisan to n daamu ọkan eeyan, awọn to n pa ṣọja aronilagbara(immune system breaker) ati bẹẹ bẹẹ lọ lo pe awọn aisan ọhun.

" Inu ifun eeyan ni ida aadọrin (70%) ninu awọn eroja to n ro ara lagbara n gbe, wọn si maa n fi gbogbo igba ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ṣọja to n ro ara wa lagbara ni.

‘’Eyi lo fi jẹ pe awọn eeyan ti ifun wọn ba ni alaafia maa n le ṣẹgun aisan ti ko ba da wọn gunlẹ.’’

Bayii ni Dokita Rossi ṣalaye.

Báwo lo ṣe lè mú ìlera ìfun rẹ ṣe dáadáa sí i ?

Aworan eso, ataalẹ, ayu ọsan lemon, cabbage,tumaati ati eso pear

Oríṣun àwòrán, Getty image

Lẹyin iṣẹ iwadii kan ti wọn ṣe lori ifun lorilẹede Amẹrika ni 2018, awọn akọṣẹmọṣẹ bẹrẹ si i gba awọn eeyan nimọran lati maa jẹ eso oriṣiiriṣii to to ọgbọn (30) lọsọọsẹ.

Wọn ni eyi yoo jẹ ki wọn ni awọn eroja ọlọkan-o-jọkan ti ifun nilo lara wọn.

Wọn fi kun un pe awọn ounjẹ to dabii tewe-tegbo n ṣe ara loore.

Dokita Rossi gba awọn eeyan nimọran lati maa se awọn ounjẹ to ni ata suẹsuẹ ninu, ki wọn si maa jẹ ẹfọ fun ilera ifun wọn.

"Njẹ a le yi ounjẹ aarọ wa pada si eyi ti a se pẹlu awọn nnkan ibilẹ lati fun ifun wa ni alaafia? Dokita Rossi lo beere bẹẹ.

"Ṣe o le yi ounjẹ rẹ pada si tibilẹ to jẹ tewe-tegbo?

‘’Awọn ounjẹ to ni fiber ninu to le jẹ ki ounjẹ tete da ninu ti yoo si ṣe ara loore, awọn bii potato, ẹwa pẹlu awọn ẹfọ ati ewe jijẹ bii salaadi lo yẹ lati maa jẹ.

‘’Awọn mi-in ni ọgẹdẹ, alubọsa elewe, aayu, alubọsa eleso, eso apple, lemon, ewe salaadi ta a mọ si cabbage ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn oúnjẹ wo ni kò dàa fún ìfun rẹ?

Aworan ounjẹ onikẹmika

Oríṣun àwòrán, Getty image

‘’Awọn ounjẹ ti wọn ti bu kẹmika ti ko ni i jẹ ko tete bajẹ si, ọti ati siga ko daa fun ifun rẹ’’Dr Krishna lati Pakistan lo sọ bẹẹ.

Awọn ounjẹ onikẹmika yii ni awọn eroja ti yoo ko ba ifun eeyan, abi ko mu inira lekun si i fẹni to ba ti ni wahala ninu ifun rẹ tẹlẹ to tun waa n jẹ wọn.

Dokita Krishna sọ pe o ṣe pataki kawọn eeyan yago fun ounjẹ arajẹ ti ki i ṣe awọn ni wọn se e funra wọn.

O ni ki wọn ri i pe wọn n fọ eso ati ewebẹ ti wọn ba fẹẹ jẹ daadaa, ki wọn ma baa jẹ bakteria aifojuri mọ ounjẹ, eyi ti yoo ṣakoba fun ifun.

Ko maa rẹ eeyan (fatigue) naa maa n ran awọn kẹmika to lewu ninu ifun lọwọ bi Dokita Krishana ṣe wi.

Dokita Johnson si ki in lẹyin pe awọn to ba tete maa n rẹ le ṣe alaini awọn ohun to n ran ifun lọwọ.

Ohun tó yẹ kí o ṣe láti dèna ìsòro ìfun

" O gbọdọ gbe igbesẹ to yẹ lasiko to yẹ lati ro ifun rẹ lagbara " Dokita Megan Rossi lo sọ eyi di mimọ.

O ni awọn orilẹede kan wa ti awọn ileeṣẹ maa n sanwo ayẹwo fawọn eeyan lati mọ ipo ti ifun inu wọn wa.

Dokita Rossi ṣalaye pe awọn ayẹwo yii ki i mu anfaani ti awọn ileeṣẹ naa n kede ẹ wa, ṣugbọn wọn le jẹ keeyan mọ awọn ohun to le ran ifun rẹ lọwọ ṣaa.

Airowo gbe kalẹ fun ayẹwo yii n fa idiwọ, gẹgẹ bi Dokita Xand to maa n ṣeto lori amohunmaworan to si tun jẹ oniṣegun oyinbo nilẹ Gẹeṣi ṣe sọ ni tiẹ.

"Wọn maa gba ọ nimọran, ṣugbọn imọran nikan ko to, o ni lati wa owo lati ṣayẹwo to o nilo nipa ifun rẹ.

" Ohun ti le sọ ni pe tu owo jọ, bi o ba ni iṣoro pẹlu ifun rẹ, gbiyanju lati lọ sileewosan ki o si ri dokita "

Bẹẹ ni Dokita Xand wi.