Wo àwọn Olubadan tó fi ilé wọn ṣe ààfin Ọba lásìkò ìṣèjọba wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Aafin Ọba jẹ ile kan pataki fun ọba ni ilẹ Yoruba, gbogbo Ọba alade pata ni ilẹ kaarọ ojiire lo gbọdọ ni aafin.
Sugbọn ni ilẹ Ibadan, nnkan fẹ da yatọ diẹ nitori awọn idi kan.
Ọpọ awọn Ọba to ti jẹ niluu Ibadani ni wọn ni lati sọ ile wọn di Aafin ọba.
Ile yii ni wọn ti ma n gba alejo, se ipade pẹlu ijoye, gba alejo eegun ati awọn nnkan mii.
Bo ti lẹ jẹ wi pe ayipada yoo waye lasiko ti Olubadan tuntun, Ọba Owolabi Olakulẹhun fẹẹ bọ sori itẹ Ọba.

Oríṣun àwòrán, Others
A le sọ pe Ibadan ko ni aafin nitori pe Baalẹ ni wọn jẹ ni ibadan tẹlẹ sugbọn lasiko ti Oba Yesufu Oloyede Asanike jẹ Olubadan ni ọdun 1983, Ibadan kọ aafin tuntun, eyi to wa ni Ọja Ọba niluu Ibadan.
Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin The Punch sọrọ, Ajoroba ti ilẹ Ibadan, Ọjọbọn Soji Adeyemo ṣalaye pe o le ni ọdun mẹdogun ti wọn fi kọ aafin Ọba tuntun.
O jẹ ko di mimọ pe ko ki n se asiko Ọba Lekan Balogun ni Ibadan bẹrẹ si ni kọ aafin tuntun.
“Labẹ idari Oloye Bode Amao ati gomina Rasidi Ladoja ni bi ọdun mẹdogun sẹyin ni wọn ra ilẹ naa, ti iṣẹ si bẹrẹ.
“Gomina ana nipinlẹ Oyo to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi ko ipa ninu rẹ, ti Gomina Seyi Makinde si pari rẹ lasiko Ọba Balogun,”
Ọ difa fun pe Ọba Asanike ni Ọba akọkọ to sun ni aafin ti ilu kọ gẹgẹ bii Ọba, to si jẹ pe oun naa ni Ọba kẹyin to sun aafin naa.
Ọba Asanike pada kuro ni aafin naa nitori idi kan tabi omiran.
Kọmisana fun Aṣa ati igbafẹ nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatubosun sọ fun BBC pe idi kan gboogi ti ọpọ ọba ko fi n duro si aafin naa ni pe o kere pupọ lati gba alejo.
“Aafin ti tẹlẹ, ko si aye nibẹ rara. Gbogbo ile ni wọn kọ yika rẹ, ko si wipe ọba fẹ gba atẹgun lagbaala.
“Nitori idi ni awọn Ibadan fi gbiyanju lati kọ aafin igbalode.”
Lẹyin Ọba Asanike, gbogbo ọba to jẹ lẹyin ni wọn ni lati lo ile wọn gẹgẹ bii Aafin ọba.

Oríṣun àwòrán, Others
Wo awọn ọba to sọ ile wọn di Aafin
Ọba Emmanuel Adegboyega Adeyemo
Ọba Emmanue; Adeyemo jẹ Oiubadan ni ọjọ kẹrinla oṣu kinni ọdun 1994.
O darapọ mọ ileeṣẹ ologun ilẹ Gẹẹsi to di pe o di Ọba.
O darapọ awọn baba nla rẹ ni ọjọ kẹsan Oṣu kẹjọ ọdun 1999.
Ọba Yinusa Ogundipe Arapasowu
Oba Ogundipe lo jẹ lẹyin Oba Adeyemo, bo ti lẹ jẹ pe idunkoko lori eto ti ilera rẹ wa nigba to bọm sipo.
Sugbọn Ọba yii pada lo ọdun lori itẹ ko to waja.
Ọba Samuel Odulana Odugbade
Lọjọ kọkanla oṣu kẹjọ ọdun 2007 ni Ọba Samuel Odulana Odugbade jẹ Ọba.
Lasiko naa ni Ọba yii jẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọrun.
Odugbade jẹ Ọba to ni ọpọlọpọ riri ati oye. Ologun, olukọ ati oloṣelu ni Ọba Odugbade ko to di Ọba alade ni ilẹ Ibadan.
Ọdun mẹsan an ni Ọba Odugbade lo lori itẹ ko waje lọjọ kọkandinlogun ọdun 2016.
Ọba Saliu Adetunji
Popoyemoja ni aafin Ọba Saliu Adetunji wa, to si wa lara awọn ori ade ti wọn sọ ile wọn di Aafin.
Ọjọ kẹrin oṣu kẹta ọdun 2016 ni gbe ade fun Ọba Adetunji
To si jade laye ni ọdun 2022 lẹyin ọdun mẹfa lori itẹ.
Ọba Lekan Balogun
Agbegbe Iwo Road ni Ọba Lekan yan Aafin rẹ si.
Ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2022 ni Ọba Lekan bọ sori itẹ Olubadan.
Lẹyin ọdun meji, Ọba Balogun dagbere faye ni ọjọ kẹdogun oṣu kẹta ọdun 2024.















