Gomina Makinde ṣí ààfin Olubadan tuntun

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣí ààfin Olubadan tuntun.
Ní ìrẹ̀lẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Keje, ọdún 2024 ni ayẹyẹ ìṣílé ààfin Olubadan tuntun ti ilẹ̀ Ibadan, Oke-Aremo ọ̀hún wáyé.
Ayẹyẹ ìṣílé náà ló ń wáyé ní o kú ọjọ́ méjì tí ètò ìwúyè fún Ọba Owolabi Olakuleyin yóò wáyé.
Ọ̀pọ̀ ọmọ ìlú Ibadan káàkiri nílé lóko àti lẹ́yìn odi lọ péjú pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà



Díẹ̀ lára àwọn àwòrán bí ayẹyẹ ṣíṣí ààfin tuntun ní ìlú Ibadan ṣe ń lọ nìyí.













Lónìí ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Keje, ọdún 2024 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde yóò ṣí ààfin Olubadan tuntun, Oke-Aremo.
Èyí ló ń wáyé ní ìgbáradì fún ìwúyè Olubadan tuntun, Ọba Owolabi Olakuleyin, tí yóò wáyé lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje, 2024.
Bí èèyàn bá gẹṣin nínú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìlú Ibadan lónìí pàápàá àwọn tó wá láti ìdílé oyè, ó ṣeéṣe kí èèyàn má kọsẹ̀ bínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ń dùn tó lórí ààfin náà.
Ohun tó fà á tí èyí fi ri bẹ́ẹ̀ ni pé láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni àwọn Olubadan kò ti rí ààfin tó jẹ́ ti ìlú lò mọ́, tó sì jẹ́ pé ilé ara wọn ni kálukú wọn ń lò gẹ́gẹ́ bí ààfin.


Oríṣun àwòrán, others
Láti ọdún 1993, láyé Olubadan Yesufu Oloyede Asanike ni Olubadan ti rí ààfin tó jẹ́ ti ìlú lò gbẹ̀yìn.
Ìdí nìyí tí ìgbìmọ̀ àwọn ọmọ bíbí ìlú Ibadan fi dìde láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fí ṣàdá, tí wọ́n sì sáré káàkiri láti kọ́ ààfin tó jojú ní gbèsè fún oyè Olubadan.

Oríṣun àwòrán, other
Níṣe ni àwọn ọmọ bíbí ìlú Ibadan nílé, lóko àti lẹ́yìn odi, tó fi mọ́ àwọn mọ́gàjí àti àgbà oyè ní ìlú Ibadan tí wọ́n fi ń kan sáárá sí gómìnà Seyi Makinde fún ipa tó kó láti ri pé ààfin náà jẹ́ píparí báyìí lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀.
Wọ́n ní píparí ààfin náà pàápàá nírú àsìkò yìí jẹ́ àfihàn ìfarajìn gómìnà sí gbígbé àṣà àti ìṣe lárugẹ àti láti ri pé Ọba Olakuleyin lógbá ire lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Olubadan.















