A fẹ́ kí Ààrẹ dá sí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti àìtó rẹ́ ní Nàìjíríà - Sẹnetọ Ndume

Ndume

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ọkan ninu awọn aṣofin orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ali Ndume, ti ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati da si bi ohun jijẹ ṣe wọn gogo lorilẹede yii bayii.

Bakan naa lo ni o ṣee ṣe keeyan lowo lọwọ ko ma si ri ounjẹ ti yoo fi ra bi nnkan ṣe n lọ yii.

Nigba to n ṣalaye ọrọ naa fun BBC,Ndume mẹnuba bi ajọ to n mojuto ounjẹ ati iṣẹ ọgbin lagbaaye (United Nations Food and Agriculture Organization), ṣe kilọ pe eeyan miliọnu mejilelọgọrin (82m) ni yoo koju isọro ai ri ounjẹ jẹ ni Naijiria fun ọdun marun-un si asiko yii.

Sẹnetọ Ndume sọ pe iṣoro to n koju iṣakoso Tinubu ju ni pe gbọin-gbọin ni wọn tilẹkun wọn, to bẹẹ ti awọn minisita mi-in gan-an ko le ri aarẹ, ka ma ti i sọ pe aṣofin yoo ri i.

O ni eyi ki i jẹ kawọn ri Aarẹ Tinubu ba sọrọ, awọn ko le sọ bi ebi to lagbara ṣe n pa araalu, ati bi ọwọngogo ounjẹ ṣe gbalẹ kan.

‘’A fẹẹ kijọba mọ pe ki i ṣe ọwọngogo ounjẹ nikan lo n ṣẹlẹ ni Naijiria, ounjẹ naa ko tiẹ si, ko kari rara.

0‘’Ni Katsina, a gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ nibẹ nigba ti ebi de. Awọn ọmọde bẹrẹ si i ṣaisan, nigba ti wọn ko ri ounjẹ to ṣe ara loore jẹ.

‘’A ri ohun to ṣẹlẹ lorilẹde Niger ati Guusu Sudan, ti awọn ọmọde n ku iku ebi.’’

Sẹnetọ Ali Ndume lo sọ bẹe.

Lori ọna abayọ si iṣoro yii, Ndume ni ohun to yẹ ni pe ki aarẹ jokoo pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa iṣoro yii, ki wọn si jọ wo ọna ti wọn yoo fi ṣẹgun rẹ.

O fi kun un pe atunṣe naa ki i ṣe ohun to yẹ ko pẹ rara, nitori iṣoro owo epo to wọn ṣi wa nibẹ ti awọn eeyan n koju.

O ni igbaye-gbadun kan ko si lasiko yii to le fa itura.