Wo ipa tí ìpínyà Niger, Mali ati Burkina Faso pẹ̀lú Ecowas yóò ní lórí ọrọ̀ ajé Ìwọ̀-Oòrùn Afrika

Awọn ọmọ ogun Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, BURKINA FASO/PRESIDENCY

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, BBC News Yoruba
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ka rin ka pọ,yiyẹ ni i yẹ ni. Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ fun awọn orilẹ-ede mẹta nni, Niger, Mali ati Burkina Faso ti wọn lawon ko ba ajọ ECOWAS to n ri si ọrọ Iwọ-Oorun ilẹ Afrika ṣe mọ, ti wọn yapa.

Ajọ Economoic Community of West African States(ECOWAS), ko awọn orilẹede ẹkun Iwọ-Oorun Afrika sinu, eyi ti awọn ilu mẹta yii naa jẹ ara wọn tẹlẹ.

Satide to kọja ni Niger, Mali ati Burkina Faso kọwọ bọwe adehun kan ninu ilana tuntun ti wọn n tọ, eyi ti wọn pe ni Alliance for Sahelian States (AES).

AES ọhun lo tun n fi ẹsẹ ipinnu wọn lati kuro ni ECOWAS naa mulẹ ṣinṣin.

Nipa ilana iṣejọba wọn, iṣakoso awarawa ni awọn orilẹede mẹta yii n lo tẹlẹ bii awọn ilẹ Adulawọ to ku n’Iwọ-Oorun.

Ọdun 2020 ni ologun gbajọba ni Mali, wọn gba ti Burkina Faso ni 2022, wọn si gbakoso Niger ni 2023 to kọja.

ECOWAS gbiyanju lati ṣofin ifipa mu wọn pada si ilana iṣejọba tiwa-n-tiwa, ṣugbọn awọn ilu mẹta naa ni awọn ko gba.

Eyi lo mu wọn kuro ninu awọn orilẹede Iwọ -Oorun Adulawọ ti i ṣe ECOWAS.

Bi wọn ṣe waa kuro yii, awọn iṣoro kan yoo koju awọn ẹkun Iwọ-Oorun Afrika yooku ninu ECOWAS, awọn to kuro yii paapaa yoo koju awọn kan funra wọn.

Ohun tí yóò kojú ọrọ̀ ajé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn nnkan jijẹ kan yoo gbowo leri ju ti tẹlẹ lọ.

O ti le logoji ọdun bayii ti awọn ọmọ ẹgbe ECOWAS ti n jẹ anfaani nipa wiwọle nirọrun si awọn orilẹede to jẹ ọmọ ẹgbẹ bii tiwọn.

Anfaani ọhun de ibi kiko ọja wọle lati orilẹede kan sikeji lai sanwo.

Ajọ naa ṣe eyi lati mu ki karakata ati okoowo gbera sọ daadaa lai si wahala, ati ki ọrọ aje le rugọgọ si i fawọn orilẹede alajọṣe yii.

Ṣugbọn pẹlu iyapa awọn Niger,Mali ati Burkina Faso yii, ohun jijẹ bii ẹran,alubọsa ati awọn ounjẹ kan yoo gbowo leri si i.

Idi eyi ni pe awọn orilẹede apa Sahel ti i ṣe aṣálẹ̀ yii ni wọn maa n sin ẹran ju, bẹẹ naa ni wọn si maa n gbin ewebẹ daadaa, eyi ti wọn maa n ko wa si Iwọ-Oorun Afrika yooku.

Bi wọn ba ṣe bẹẹ kuro lara ECOWAS, wọn ko ni i jẹ anfaani aisanwo lori ohun ti wọn n ko wọlẹ mọ.

Wọn yoo ni lati maa sanwo lori ọja, awọn naa yoo si ṣe bẹẹ gbowo le e fun ara ECOWAS ti yoo ra a lọwọ wọn.

Eyi tumọ si pe Nigeria, Ghana, Senegal ati gbogbo ẹkun West Africa yoo ni lati maa sanwo ju ti tẹlẹ lọ lori awọn nnkan wọnyi.

*Yóò kóbá afẹfẹ TSGP to wa laarin Nigeria, Niger ati Algeria

Ipinnu ati maa ko afẹfẹ ti wọn pe ni Trans-Saharan Gas Pipeline laarin Naijiria, Niger ati Algeria yoo mẹhẹ bawọn ti wọn lawọn ko ṣe ECOWAS mọ yii ba fi lọ.

Ọdun 2030 ni ireti wa pe ileeṣẹ afẹfẹ gaasi naa yoo gberasọ.

Ẹgbẹrun mẹrin kilomita afẹfẹ yii ni eto wa pe Naijiria yoo maa ta ni iwọn ọgbọn (30 billion cubic), ti yoo maa gba Niger de Algeria, kọja agbami okun Mediterranean wọ ilẹ Europe.

Lati ṣẹgun aito nnkan agbara bii eyi ni wọn ṣe n pete gaasi, ki okoowo afẹfẹ idana si le ṣe daadaa fun ọrọ aje orilẹede to ba kan.

Ṣugbọn pẹlu iyapakuro awọn Niger, ilu naa pẹlu Naijiria funra rẹ ti sọ ẹran jọbọjọbọ nu.

Ibùdó ẹrù tó wà ní Togo àti Ivory Coast yóò faragbá a

Ibudo ti wọn n ja ẹru si ni Togo ati Ivory Coast ki i gbẹ rara, ọjọ gbogbo ni wọn fi n ṣowo nibẹ ti owo si n wọle fun wọn gidi.

Ti Togo ni wọn tiẹ gbade fun ju bii eyi to daa to si yara kankan lati gba ẹru ni West Africa, ti Abidjan si ni wọn lo tobi ju lapa Iwọ-Oorun Afrika yii.

Ṣugbọn pẹlu iyapa kuro awọn ti wọn n fi ECOWAS silẹ yii, Togo ati Ivory Coast yoo faragba a nigba ti awọn to ti aṣálẹ̀ ko ba le gba ọdọ wọn fi ẹru ranṣẹ tabi gba ẹru mọ.

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ètò ìrìǹnà?

O ṣee ṣe ki iṣoro wa fun awọn orilẹede Iwọ-Oorun Afrika yooku lati wọ ọdọ awọn Sahel ti wọn lawọn o ṣẹ ECOWAS mọ yii.

Ni 2020 ti wọn gbe paali ECOWAS jade, wọn fi aaye silẹ fawọn orilẹede mẹẹẹdogun ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ lati wọle si awọn ilu naa lai lo fisa, wọn si le e lo o bii ti ilẹ okeere ni ilu Adulawọ ti wọn wa naa.

Aaye wa lati gbe lorilẹede kan foṣu mẹta lai ki i ṣe ọmọ ibẹ, bi o ba ṣaa ti jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS.

Ṣugbọn eyi le yipada bayii fun awọn orilẹede mẹta ti wọn lawọn n kuro ni ECOWAS.

Bakan naa ni igbeyawo ẹya kan si ikeji, laarin Naijiria ati Mali,Ghana ati Burkina Faso ati bẹẹ bẹẹ lọ le maa ya mọ.

Eyi yoo ri bẹẹ nigba to ba ti di dandan ki wọn maa gba fisa ki wọn too le wọle sọdọ awọn ẹni ti wọn fẹẹ fẹ lọmọ.

Ohun tí Burkina Faso, Mali àti Niger yóò pàdánù

Awọn ọmọ ẹgbẹ ECOWAS

Oríṣun àwòrán, ECOWAS

Awọn orilẹede mẹta yii ko ni odò, awọn orilẹede bii Togo, Benin, Nigeria ati Ghana lo n ba wọn ko ọja gba oju omi.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ECOWAS ṣe wi, ni 2022, ọja ti Mali fi ranṣẹ sawọn ilu mi-in jẹ $3.91 billion, eyi to wọle fun wọn si jẹ $6.45 billion.

Burkina Faso fi ọja $4.55 billion ranṣẹ, wọn ko $5.63 billion wọle. Nigba ti Niger ta $446.14 million silẹ okeere, to si ra $3.79 billion wọle.

Bi wọn ba fẹẹ kiru eyi tẹ siwaju, awọn ilu mẹta yii ni lati ba awọn orilẹede Iwọ-Oorun Afrika yooku ṣe, eyi ti yoo na wọn lowo gọbọi lati ṣe, afi bi wọn ko ba fi ECOWAS silẹ lo ku.

Lọwọlọwọ, orilẹede Benin ti gbegidina epo to n wa lati ẹkun Agadez, ni Guusu Niger.

Bẹẹ, owo ti Niger ba n ri lati ara epo yii ni wọn fẹẹ fi san gbese irinwo miliọnu dọla ($400 million) ti wọn jẹ China.

Awọn olori ECOWAS naa ti fi ẹ̀rù to n ba wọn nipa iyapa yii han, wọn ni ogiri to n lanu silẹ yoo faaye gba alangba lati wọle .

Iṣoro aabo pọ ni ẹkun aṣalẹ Iwọ-Oorun Afrika, iyẹn awọn Sahel.

Ọpọ igba ni awọn alakatakiti ẹsin ti kọlu wọn, eyi ti iwoye fi han pe wọn le gbabi iyapa yii tun wọle si awọn orilẹede mi-in.

Lọdun 2022, akọsilẹ agbaye(The Global Terrorism Index) fi han pe apa Sahel yii ni awọn agbesunmọmi to buru julo pọ si ju lagbaaye.

Aringbungbun ibi ewu ni wọn pe ibẹ ninu apejuwe wọn.

Wọn ni eeyan ibẹ pọ, ko si ounjẹ ati omi, oju ọjọ ko ṣe wọn loore pẹlu, bẹẹ ni ijọba wọn lẹ.