Àṣírí bí Emefiele ṣe fi òbítíbitì owó ránṣẹ́ láti CBN sí àpò àṣùwọ̀n ìyàwó rẹ̀ nílé-ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Igbakeji alakoso ile ifowopamọ Zenith, Arabinrin Ifeoma Ogbonnaya ti jẹri tako gomina ana nile ifowopamọ agba lorileede Naijiria, Godwin Emefiele lori iwa jibiti to hu.
Ogbonnaya sọ pe Emefiele wọ awọn owo nla kan lati apo iṣuna CBN sinu apo aṣuwọn iyawo rẹ, Arabinrin Margaret Emefiele toun ti na papa bora.
Arabinrin Ogbonnaya lo tu awọn aṣiri yii niwaju ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ara-ọtọ, eyi to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti n gbọ ẹjọ Godwin Emefiele lori ẹsun jibiti ati ṣiṣe owo kumọkumọ, to fi mọ aṣilo ipo.
Lara awọn ẹsun ti wọn tun fi n kan Emefiele ni ẹsun jibiti biliọnu mẹrin aabọ dọla ati biliọnu mẹta din ni ẹgbẹrun lọna igba (N2.8b) naira lasiko to wa ni iṣakoso.
Ogbonnaya ni ẹlẹri karun-un to n tako Emefiele, eyi ti agbẹjọro ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, EFCC, Ọgbẹni Rotimi Oyedepo fi han fun ile-ẹjọ.
Nigba to n sọrọ, obinrin naa ni ọpọ igba ni Emefiele ti fi aṣuwọn iyawo gbe owo jade kuro ni CBN nipasẹ awọn ileeṣẹ loriṣiriṣi.
Ogbonnaya ni lara awọn ileeṣẹ naa ti owo n jade lati CBN sinu rẹ ni Amswing Resources and Solution, Limelight Dimensional Service Ltd., Omec Support Service Ltd. ati Mango Farm.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Limelight lo n mojuto awọn dukia CBN to wa lagbegbe Alakija, bẹẹ ni wọn tun n mojuto gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu ina ati awọn nnkan miran ni CBN.”
Ogbonnaya, ẹni to tun jẹ alakoso to n ri sọrọ ibaṣepọ ti okoowo lo darapọ mọ banki naa lọdun 2006.
O sọ pe lotitọ loun ko tii ni ibaṣepọ kankan ri pẹlu Emefiele, ṣugbọn toun maa n gba itọni lati ọdọ iyawo rẹ lati fi owo ranṣẹ lati CBN sinu apọ aṣuwọn awọn ileeṣẹ aladani wọn lati Zenith.
Siwaju sii ni Ogbonnaya sọ pe, yatọ si iyawo Emefiele, oun tun maa n gba itọni lati ọdọ awọn meji kan, Ọgbẹni John Ogah ati Ọgbẹni Ọpẹyẹmi Oludimu ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu Emefiele, ṣugbọn to ti ku bayii.
Ẹlẹri yii sọ pe oun loun n mojuto awọn apo aṣuwọn awọn ileeṣẹ naa ti obitibii ẹgbẹẹgbẹrun miliọnu n wọnu rẹ loore-koore.
“Arabinrin Margaret Emefiele, iyawo gomina CBN tẹlẹ ni ẹni to lanfaani si awọn apo aṣuwọn naa. Awọn ileeṣẹ naa maa n fi atẹjiṣẹ ori imeeli ranṣẹ si mi lati fi owo ranṣẹ, to si jẹ pe Margaret lo n ṣakoso awọn apo aṣuwọn ọhun.
“Gbogbo bi owo ṣe n wọle-jade lo n jẹ pe Arabinrin Emefiele lo n fi ontẹ lu ko to di pe owo naa jade. Oun lo maa n paṣẹ lati inu atẹjiṣẹ ori imeeli pẹlu banki Zenith lati fi owo ranṣẹ, tabi ko ran awọn meji miran lati duro fun un, sibẹ, oun lo n paṣẹ fun mi.”
Bakan naa lo tun sọ fun ile-ẹjọ pe laarin ọjọ kẹsan si ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2015, awọn apo aṣuwọn naa gba miliọnu mọkandinlogun (N18.9m) ati miliọnu mejidin-lẹgbẹrun-lọna-igba (N1.8m) naira.
“Lọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2021, awọn owo atigbadegba to jẹ miliọnu mẹtalelogoji jade lati CBN; lọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun 2021, miliọnu mẹtadinlogoji le diẹ (N37.3m) tun jade; miliọnu mẹrinlelogoji le diẹ (N44.6m) lowo to tun jade lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2022; bẹẹ ni miliọnu mẹtalelaadọrun (N93.1m) naira miran tun jade lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2023.”
Arabinrin Ogbonnaya sọ pe iyawo Emefiele maan ba oun sọrọ yala lori imeeli, ẹrọ ibanisọrọ tabi atẹjiṣẹ wasaapu lori owo to fẹẹ jade ko to di pe wọn ṣiṣẹ lori rẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo bi awọn owo naa ṣe jade loun ti tẹ jade lati fi ṣafihan fun ile-ẹjọ.
“Wọn fi awọn iwe naa ranṣẹ sori imeeli mi, nigba ti iwadii si bẹrẹ, wọn sọ pe ki n tẹ gbogbo rẹ jade fun awọn agbofinro, eyi ti mo si ṣe bẹẹ.
“Mo tẹ gbogbo rẹ jade lati ori ẹrọ kọmputa mi, ti mo si fa a le awọn oniṣẹ iwadii lọwọ. Mo tun ni iwe ẹri wi pe banki Zenith ni mo ti tẹ awọn iwe naa jade.” Ogbonnaya ssọrọ.
Lẹyin eyi ni agbẹjọro EFCC ko gbogbo ẹri naa to nii ṣe pe pẹlu ẹlẹri pẹlu iyawo Emefiele siwaju ile-ẹjọ.
Agbẹjọrọ Emefiele, Ọgbẹni Ọlalekan Ojo ati Ọgbẹni Kazeem Gbadamọsi ko tako awọn iwe to nii ṣe pẹlu ẹri naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin, ọdun yii ajọ EFCC foju Emefiele ba ile-ẹjọ lori ẹsun mejilelogun to nii ṣe pẹlu aṣilo ipo ati iwa ajẹbanu.
Ẹnikeji rẹ ti wọn jọ fẹsun kan lo n jẹjọ lori ẹsun mẹta to nii ṣe pẹlu gbigba ẹbun ninu iwa jibiti naa.
Awọn olujẹjọ yii ni wọn sọ fun ile-ẹjọ wi pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ju gbogbo rẹ lọ, Onidajọ Oshodi ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹwaa, ọsu keje, ọdun yii.















