Ilé aṣòfin ní kí ìjọba àpapọ̀ dáwọ́ dúró lórí ṣíṣe àmúṣe àdéhùn SAMOA tó ń fa awuyewuye

Abẹnugan ilé aṣojúṣòfin

Oríṣun àwòrán, @HOUSEOFREPSNGR

Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin Nàìjíríà ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti má ṣàmúṣẹ àdéhùn Samoa tí wọ́n tọwọ́bọ̀ àyàfi tí wọ́n bá yanjú gbogbo àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye lórí àdéhùn náà.

Àwọn aṣòfin méjìdínláàdọ́rùn-ún ló tẹ pẹpẹ ọ̀rọ̀ náà síwájú ilé aṣòfin níbi ìjíròrò wọn tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Keje, ọdún 2024.

Aṣòfin Aliyu Madaki tó gbé ọ̀rọ̀ náà síwájú ilé aṣòfin ní ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo tó ń fa awuyewuye lórí àdéhùn náà le fa ohun tó le da omi àláfíà ìlú rú tí ìjọba kò bá tètè mójúto.

Bákan náà ni ilé aṣòfin tún gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe ìwádìí àdéhùn náà.

Láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti tọwọ́bọ àdéhùn Samoa pẹ̀lú àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù, EU ni awuyewuye ti ń wáyé pé ìjọba àpapọ̀ tí fẹ máa fi àyè gba ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo ní Nàìjíríà.

Lẹ̀yìn awuyewuye yìí ni Mínísítà fún ètò ìsúná àti ọrọ́ ajé Nàìjíríà, Atiku Bagudu ní ìjọba kò ní tọwọ́bọ àdéhùn tó lòdì sí ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí.

Bagudu ní àṣà, ẹ̀sìn àti ìṣe Nàìjíríà lòdì sí ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo nítorí náà ìjọba kò ní ṣe nǹkan tó lòdì sí àwọn ènìyàn àwọn.

Ó ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn fi tọwọ́bọ àdéhùn náà ni láti mú kí oúnjẹ pọ̀ yanturu àti láti pọn kún ètò ọrọ̀ ajé, tó fi mọ̀ àwọn nǹkan igbáyégbádùn mìíràn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò ní Nàìjíríà ìyẹn Nigeria Bar Association, (NBA) ní àwọn ti ṣe àgbéyẹ̀wò àdéhùn náà dáradára pé kò sí ibi tí wọ́n ti pa á ní dandan fún Nàìjíríà láti fàyè gba ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo.

Àtẹ̀jáde tí ààrẹ ẹgbẹ́ NBA, Yakubu Maikayau fi léde nínú àtẹ̀jáde kan pé díp]o bẹ́ẹ̀, àdéhùn náà fàyè kí ìjọba ṣàmúlò òfin orílẹ̀ èdè rẹ̀.

Maikayu ní àwọn tó gbé àdéhùn náà mọ̀ wí pé òfin tó de ìbálòpọ̀ ní Nàìjíríà kò fàyè gba ìbálòpọ̀ akọsákọ tàbí abosábo, tí wọ́n sì gbàgbọ́ pé ìwé òfin Nàìjíríà ju gbogbo àdéhùn tí wọ́n ń gbé bọ̀ lọ.

Ó ṣàlàyé pé tó bá jẹ́ pé àdéhùn náà ní àwọn nǹkan tó le da ìṣọ̀kan Nàìjíríà rú, àwọn ti máa gba ìjọba nímọ̀ràn láti má tọwọ́bọ àdéhùn náà tipẹ́tipẹ́.

NBA wá rọ ìjọba àpapọ̀ láti lékún lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú láti mọ àwọn nǹkan tí àdéhùn náà dá lé lórí àti láti paná gbogbo awuyewuye tó ń wáyé lórí rẹ̀.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti máa ṣe ìwádìí àwọn nǹkan tí wọ́n bá ń kà lórí ayélujára dáadáa láti di èyí tó bá jẹ́ òótọ́ ibẹ̀ mú.