Àwọn ará abúlé bẹ àwọn òrìṣà lọ́wẹ̀ sáwọn olè tó ń jí irinṣẹ́ olówó ńlá lọ níléèwòsàn ìjọba

Aworan oriṣa ati ẹni to n bọ ọ

Oríṣun àwòrán, COAL CITY CONNECT/INSTAGRAM

Awọn eeyan abule kan, Ogurute Oombe, nipinlẹ Enugu, ti gbe igbesẹ to ya ọpọ eeyan lẹnu bayii.

Niṣe ni wọn bẹ awọn oriṣa ilu wọn lọwẹ si awọn ole to n ji irinṣẹ ati nnkan eelo nileewosan ijọba apapọ tijọba kọ fun wọn.

Kabiyesi ilu Ogurute Oombe, Igwe Wilfred Ogbonna Ekere, ṣalaye fun BBC pe otitọ ni awọn eeyan oun ti fi awọn to jale nileewosan naa ré.

O ni gboro yoo gbe ole yoowu to ba lọwọ si jiji ohunkohun lọsibitu naa.

Ṣaaju ni Igwe Ogbonna ti fibinu ṣalaye, pe awọn eeyan oun ṣe ipese kanka kan siwaju osibitu naa laipẹ yii, wọn bẹ awọn oriṣa lọwẹ lati ṣọ ọsibitu naa.

Ki wọn tun fi oju ẹnikẹni to ba waa jale nibẹ han fun gbogbo ilu ri.

Kí làwọn ohun tí wọ́n ti jí lọ́sibítù náà rí?

Aworan ileewosan ijoba Ogurute Oombe

Oríṣun àwòrán, COAL CITY CONNECT/INSTAGRAM

Igwe Ogbonna ṣalaye pe awọn irinṣẹ ti wọn fi n ṣe ayẹwo DNA, eyi ti wọn fi n ṣe ayẹwo ikọ ife (Tuberculosis), irinṣẹ ti wọn fi n ṣayẹwo arun ko-gboogun (HIV), ti jẹjẹrẹ (Cancer) ni awọn ole ti ji lọ tan lọsibitu abule naa.

O fi kun un pe ajọ kan ti ki i ṣe tijọba lo ra awọn eelo naa wa, wọn si fi wọn sileewosan naa.

Ọsan kan, oru kan ni awọn ole wọle tu gbogbo ẹ lọ bo ṣe sọ.

Bakan naa lo ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Enugu, Ifeanyi Uguanyi, naa ra awọn nnkan eelo sọsibitu yii, ṣugbọn niṣe lawọn ole ko o lọ tan pata.

Awọn nnkan mi-in ti wọn tun ji bi Igwe Ogbonna ṣe wi ni, ẹrọ ti wọn fi n ṣe ayẹwo ọkan eeyan.

Ẹrọ amuletutu, bẹẹdi tawọn alaarẹ fi n sun, ẹrọ kọmputa oriṣiiriṣii, ẹrọ to n ṣayẹwo egungun eeyan, aga ijokoo, tẹlifiṣan, oogun olowo nla ọlọkan-o-jọkan, jẹnẹretọ to n lo oorun lati tan, ọkọ agbokuu-gbe-alaarẹ (ambulance) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Batiri mẹta lasan ninu awọn ẹrọ naa le ni miliọnu meje naira bi Igwe ṣe ṣalaye. Bẹẹ lowo awọn yooku naa pọ gidi.

Olè ló múnú bí ará abúlé ti wọ́n fi bẹ alálẹ̀ lọ́wẹ̀

Aworan awọn to n bọ oriṣa

Oríṣun àwòrán, COAL CITY CONNECT/INSTAGRAM

Igwe Ogbonna sọ pe awọn ara abule ko ri itọju gba mọ latari idaamu ti awọn ole ko ba wọn nileewosan naa.

O ni idi niyẹn ti wọn fi pinnu lati bẹ alalẹ lọwẹ si ẹni yoowu to le jẹ.

‘’Inu bi awọn ara abule, wọn pe awọn oṣiṣẹ ileewosan yii jọ pe to ba jẹ awọn ni wọn n ji awọn nnkan naa, ki wọn da a pada kawọn too bẹ alalẹ lọwẹ si wọn.

‘’Wọn duro fasiko diẹ, ṣugbọn ko sẹni to da nnkan kan pada ninu awọn oṣiṣẹ naa, wọn ni awọn ko mọ nipa ẹ.

Idi niyẹn ti awọn araalu fi gbe igbesẹ naa.

‘’Wọn fi ẹnikẹni to ba ti ji awọn nnkan naa re, wọn si ran awọn alalẹ ti yoo mu si i. ‘’

Igwe Ogbonna lo sọ bẹẹ.

Ni bayii ṣaa, inu awọn ara abule Ogurute Oombe ko dun rara, wọn ni awọn ni ìyà awọn nnkan eelo to sọnu naa n jẹ.

Atọka ileewosan Ogute

Oríṣun àwòrán, OGURUTE/ FACEBOOK