Nígbà tí mo pé ogójì ọdún ni mo bí ọmọ kan ṣoṣo tí mo ní láyé, ṣùgbọ́n ó nídìí- Binta Ayo Mogaji

Ayo Mogaji

Oríṣun àwòrán, Binta Ayo Mogaji/ Instagram

Ogbontarigi agba oṣerebinrin n ni, Binta Ayọ Mọgaji ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ko to o di ọlọmọ laye, to si loun ti le logoji ọdun ko to di pe oun bi ọmọ kankan ṣoṣo ti Ọlọrun yọnda foun.

Ayọ Mọgaji ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Igbanladogi lo sọ eyi nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu oṣerebinrin mii, Biọla Adebayọ loju opo ayelujara rẹ laipẹ.

Agba oṣerebinrin naa sọ pe iṣoro airi oyun ni da oun laamu gan an, ati pe nigba toun yoo pada ni oyun, idaamu nla lo jẹ foun nitori pe kii ṣe ibi to yẹ ki oyun duro si lo duro si, eyi to jẹ koun maa paarọ ile iwosan kaakiri.

“Ṣọla Ṣobọwale, Sam Loko, Jide Kosọkọ ati awọn eeyan mii naa kan n bu sẹkun ni lọsibitu.

Wọn ni lati yọ ọkan ninu awọn egboro to n gbe atọ lọ sinu ile ọmọ naa kuro ninu mi.

“Bayii ni mo ṣe bi ọmọ mi pẹlu ọpa atọ kan ṣoṣo lai ṣiṣẹ abẹ rara.

A le lọ soko ere fun oṣu mẹta si mẹfa, ka sun si gbangan National Theatre pẹlu ẹfọn to n jẹ wa.

“Nigba to su mama mi, wọn lawọn ba mi ri iṣẹ banki, mo sọ pe mi o ṣiṣẹ banki nitori pe mi o mọ nnkan tọju.

“Mo jawọ lati maa wa ọkọ, mo ṣaa kan fẹẹ bimọ ni. Bi mi o ba si bimọ titi digba ti mo fi pe ọmọ ogoji ọdun, niṣe ni maa lọ gba ọmọ ti maa si sọ ọ di temi labẹ ofin.

Arabinrin Mogoaji ṣalaye pe “asiko naa ni Jibọla wa, nigba to ku diẹ ki n pe ogoji ọdun, nitori pe ọsẹ mẹfa lẹyin ti mo pe ogoji ọdun ni mo bimọ mi, ṣugbọn oun naa ko ṣetan lati fẹyawo, o sọ fun mi nigba yẹn."

Ayo Mogaji

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ayọ Mọgaji fikun ọrọ rẹ pe diẹ lo ku ki oun dẹni igbagbe lasiko ogun abẹle, ṣugbọn to ni ori lo ko oun yọ lọdun naa lọhun.

O ni ẹnikan lo deede pariwo to fi di pe gbogbo eeyan bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi ara wọn, to si jẹ pe oun nikan ni wọn gbagbe siwaju ita .

"Wọn fi emi nikan siwaju ita. Ọkan lara awọn ṣọja to n kọja lo fi ipa ja ilẹkun, to si gbe mi sọle."

Gbajugbaja oṣerebinrin to ti rinrin ajo kaakiri ilẹ okeere naa tun fi kun ọrọ rẹ pe oun padanu nla nigba toun ṣe fiimu agbelewo Jombo lọdun 2003.

O ni miliọnu mẹrin le diẹ (N4.1m) naira loun na lati ya fiimu ọhun, ṣugbọn to jẹ pe owo toun ri nibẹ ko to nnkan.

Bakan naa nigba to n sọrọ nipa ipenija to koju nidi ọkọ fifẹ, o sọ siwaju pe ''nigba yẹn, ko si ọkunrin to fẹẹ gbe wa sile gẹgẹ bii iyawo nitori pe igba miran ti de ti awọn eeyan ti n pe awọn oṣerebinrin ni aṣẹwo.

Nigba ti wa, oun ti wọn maa n sọ fawọn ọkunrin ni pe ‘ko le gbọrọ si ẹ lẹnu.’

“Ẹni ti mo ba pada nigba yẹn, a pada nifẹ ara wọn, ṣugbọn bi ọrọ kekere kan ba ṣẹlẹ, igbaju ati igbamu ni, koda nigba ti a de orilẹede Gẹẹsi.

Lilu ati ọrọ buruku pẹlu epe, nigba ti eyi ba ti pọ ju, amọran ti mo maa gba eeyan ni pe ko fi igbeyawo ọhun silẹ.

Ayo Mogaji sọ pe “o to asiko kan to jẹ pe bi emi pẹlu rẹ nikan ba jọ wa nile, mo maa jade sita lati da jokoo ninu ọgba titi ti awọn eeyan yoo fi de ni, nitori ko ma ba a lu mi.

“Bayii la si ṣe fun ọdun mẹtala, a si ti kọ ara wa silẹ bi ọdun mẹrin bayiii."

Ogbontarigi oṣere yii sọ pe ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1980 loun bẹrẹ sii pa owo nidi iṣẹ tiata.

Bẹẹ lo ni oun ko gba awọọdu lori fiimu Igbanladogi nigba yẹn, ṣugbọn to ni eeyan kan fun oun ni mọto.