Ṣé Nàìjíríà yóò ní àǹfàní láti kópa nínú ìdíje Olympics 2024?

Oríṣun àwòrán, Senator John Enoh/X
Ileẹjọ CAS to n ri si ẹjọ to ni ṣe pẹlu ere idaraya lagbaaye yoo sọ lonii ọjọ Ẹti, ọjọ kejila oṣu Keje bo ya orilẹede Naijiria yoo lanfaani lati kopa ninu idije Olympics 2024 niluu Paris lorilẹede France.
Ajọ WADA to n gbogun ti lilo oogun oloro lati kopa ninu ere idaraya lo gbe Naijiria lọ sile ẹjọ CAS.
WADA sọ fun ile ẹjọ naa pe ko fofin de Naijiria lati ma le kopa ninu idije Olympics ọdun yii, tori ajọ to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria ko tẹle ilana ajọ WADA.
Naijiria ati orilẹede Angola ni WADA fẹsun kan, bo tilẹ jẹ pe Angola ti gba idalare bayii lori ọrọ naa.
Ọsan oni ọjọ Ẹti ni idajọ naa yẹ ko waye.
Ti Naijiria ba le jẹbi ẹsun ti ajọ WADA fi kan an, ko ni si asia Naijiria ninu awọn asia awọn orilẹ-ede ti wọn yoo ṣafihan rẹ ninu idije Olympics 2024.
Ati wi pe, awọn elere idaraya to yẹ ki wọn ṣoju Naijiria ninu idije Olympics yii ko ni le ṣe bẹẹ mọ.
Ohun to ma ṣẹlẹ ni pe awọn elere idaraya yii yoo kopa ninu idije naa gẹgẹ bi ọlọdanni.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje yii ni idije Olympics 2024 yoo bẹrẹ niluu Paris.















