Nítorí ìdájọ mánigbàgé lórí òmìnira ìjọba ìbílẹ̀ yìí, àwọn èèyan wa yóò bẹ̀rẹ̀ síí fa àwọn adarí wọn lọ́rùn báyìí – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook
Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti gbe oṣuba kare fun ile ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria lori idajọ to ṣẹṣẹ gbe kalẹ lori ominira awọn ijọba ibilẹ pẹlu iṣakoso owo to tọ si awọn ijọba ibilẹ kaakiri Naijiria, eyi ti awọn gomina n ko si ipamọ.
Tinubu ni awọn araalu, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun yoo bẹrẹ sii fa awọn adari wa lawọn agbegbe laṣọ lori bi wọn ṣe n na owo ilu to n wọle fun wọn lati asiko yii lọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, l’Ọjọbọ, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ agba naa gbe idajọ kalẹ wi pe ki awọn gomina dẹkun lati maa gba owo to tọ si awọn ijọba ibilẹ, nitori pe wọn ko lẹtọ sii, ati pe o ti di iwa aibofin mu bayii.
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun paṣẹ pe awọn gomina ko lẹtọọ lati maa tu iṣakoso awọn ti wọn dibo yan s’awọn ijọba ibilẹ ka, ati pe nipa ṣiṣẹ eyi, wọn ti n tapa si iwe ofin orileede Naijiria ti ọdun 1999.
Ko pẹ si asiko ti idajọ yii waye ni Arẹ Tinubu sọ pe bi ijọba ibilẹ ko ṣe ri iṣẹ ṣe mọ jẹ ọkan gboogi lara awọn ipenija to n doju kọ idagbasoke orileede lati ọdun pipẹ sẹyin.
Nipaṣẹ idajọ yii, awọn eeyan wa – paapaa awọn mẹkunnu – yoo ni anfaani lati bẹrẹ sii fa awọn adari wọn nijọba ibilẹ laṣọ lati ṣalaye bi wọn ṣe n na owo ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ,” wọnyi lohun ti Ajuri Ngelale to jẹ agbẹnusọ Tinubu sọ sita.
Ngelale tẹsiwaju pe “Ohun ti wọn fi n ranṣẹ si apo aṣuwọn ijọba ibilẹ ni yoo bẹrẹ sii di mimọ bayii, ati pe wọn gbọdọ maa fi ṣe awọn iṣẹ to yẹ lati ni awijare kankan.
“Iṣakoso mi lo gbe eyi dide nitori igbagbọ wa ni pe ohun gbogbo gbọdọ tu awọn eeyan wa lara, ati pe idajọ tonii yoo fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ti wọn ba yan sipo oṣelu nijọba ibilẹ ni yoo bẹrẹ sii ṣakoso awọn ohun amuṣọrọ araalu.
“Ofin yii fidi mulẹ gẹgẹ bi idaniloju pe a le ọna ofin lati fi ṣatunto orileede yii ati eto ọrọ aje wa lati le ki Naijiria wa ni ipo to dara lati gbe fun awọn eeyan wa ni irọrun.”
Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun adajọ agba ati minisita fọrọ eto idajọ lorileede yii ati, Lateef Fagbemi lori ọkan akikanju rẹ, to si ni iṣẹ to ṣe pataki ni idajọ to waye naa.
Iléẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíráà dájọ́ pé Owó ìjọba ìbílẹ̀ kò gbọdọ̀ dé ọwọ́ àwọn gómìnà mọ́, wo àwọn nǹkan míràn tó wà nínú ìdájọ́ náà

Oríṣun àwòrán, others
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti gbe idajọ kalẹ pe ohun to lodi si ofin patapata ni ki awọn gomina maa ko owo to yẹ fun ijọba ibilẹ si pamọ.
Ninu idajọ to ka gẹgẹbi aṣiwaju igbimọ onidajọ to gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Emmanuel Agim ni o ti pẹ tawọn gomina ti n wa ọwọ mọ owo awọn ijọba ibilẹ eyi to si ti mu ki awọn ijọba ibilẹ o maa ri owo to tọ siwọn gba taara lati ọdọ ijọba apapọ, bikoṣe lati ọdọ awọn ijọba ipinlẹ to n gba owo naa lorukọ wọn.
Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ni gbogbo ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o din mẹfa (774) ijọba ibilẹ to wa jakejado orilẹede Naijiria lo lẹtọ lati maa funrsn ṣe akoso awọn owo ti o ba tọ si wọn lati inu aṣuwọn apapọ orilẹede Naijiria.
Onidajọ Agim ni agbẹjọro agba fun ijba apapọ Naijiria lẹt lati pe ẹjọ to pe.
Ile ẹjọ naa wa paa laṣẹ pe inu aṣuwọn awọn ijọba ibilẹ taarata ni ki wọn maa san owo to ba yẹ fun wọn si, kii ṣe ti ijọba ipinlẹ.
O ni bi awọn gomina ṣe n ko owo ijọba ibilẹ sọwọ n ṣe idiwọ fun ṣiṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ẹka ijọba to sun mọ araalu julọ.
Bakannaa ni Onidajọ Agim paṣẹ pe ki wọn tẹle idajọ naa lẹyẹ o ṣọka, to si wọn ko gbọdọ san owo yoowu to ba jẹ ti ijọba ibilẹ fun ijọba ipinlẹ kankan mọ.

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria yoo gbe idajọ kalẹ loni lati sọ boya awọn ijọba ibilẹ n ni ominira to to gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe laa kalẹ tabi ki awọn gomina o tu ọwọ kuro lọrun wọn.
Agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria lo pe awọn gomina ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji to wa ni Naijiria lẹjọ lorukọ ijọba apapọ pe ki wọn fun awọn ijọba ibilẹ ni ominira to yẹ labẹ ofin.
Ile ẹjọ naa ti ranṣẹ si awọn agbẹjọro atawọn igun gbogbo ti ẹjọ naa kan.
Ki ni ẹbẹ ijọba apapọ niwaju ile ẹjọ naa?
Ohun ti ijọba apapọ n sọ bayii ni pe awọn gomina ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji to wa lorilẹede Naijiria n tẹ ẹtọ awọn ijọba ibilẹ loju mọlẹ paapaajulọ nipa ṣiṣeto idibo wọn ati gbigbawọn laaye lati funrawọn na owo ti to n tọ si wọn fun iṣakoso .
Ijọba apapọ n fẹ ki ile ẹjọ to ga julọ naa pa a laṣẹ lati maa san awọn owo to tọ si ijọba ibilẹ si inu aṣuwọn awọn ijọba ibilẹ ganagan lati inu aṣuwọn ijọba apapọ gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe laa kalẹ.
Ki ni esi awọn gomina?

Oríṣun àwòrán, X/officialABAT
Ohun ti awọn gomina fọ gẹgẹ bi esi niwaju ile ẹjọ naa ni pe awọn ko faramọ ẹbẹ ti ijọba apapọ gbe kalẹ niwaju ile ẹjọ naa.
Bawo lọrọ ṣe jẹ?
Ni orilẹede Naijiria, ọpọ igba lawọn ijọba ibilẹ ti n ke irora pe awọn gomina ṣe n ko owo to tọ si wọn pamọ, eleyi ti wọn ni o n pagidina ilakaka ati ṣe awọn akaṣe iṣẹ fun idagbasoke lẹsẹkuku.
Bakan naa si ni awọn onimọ ti n pe fun ominira ijọba ibilẹ nitori pe ijọba ibilẹ lo sun mọ araalu julọ.
















