Ìgbà ọ̀tun dé tán ní Nàìjíríà, oṣù díẹ̀ ló kù - Igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima

Kashim Shettima

Oríṣun àwòrán, Kashim Shettima/FACEBOOK

Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Kashim Shettima ti sọ àrídájú rẹ̀ pé ohun gbogbo ń bọ̀ wá di ẹ̀rọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láì pé ọjọ́.

Shettima ní tó bá máa fi tó bí oṣù mélòó díẹ̀ si, gbogbo ohun tó le ní orílẹ̀ èdè yìí ló ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀, tí àwọn èèyàn yóò sì máa jẹ àǹfàní gbogbo ìnira tí wọ́n ti rí sẹ́yìn.

Níbi àpẹ̀jẹ ìṣínu awẹ èyí tí Ààrẹ Tinubu ṣe agbátẹrù fún àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ àtàwọn olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò ni Shettima ti sọ̀rọ̀ náà.

Shettima rọ àwọn tó di ipò òṣèlú mú lásìkò yìí láti gbárùkù ti Ààrẹ Tinubu lójú ọ̀nà àti mú ìgbà ọ̀tun bá Nàìjíríà, bó ṣe ní Ààrẹ ní ìfarajìn láti mú àyípadà bá ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.

Ó rán àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ náà létí pé ipò adarí jẹ́ èyí tí èèyàn gbọ́dọ̀ ní ìfarajìn sí tí èèyàn bá fẹ́ ṣe àṣeyọrí.

Igbákejì Ààrẹ náà tún ní àsìkò àwẹ̀ Ramadan jẹ́ àsìkò àánú àti ìforíjì, èyí tó ń wáyé lásìkò kan náà tí àwẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi náà ń lọ lọ́wọ́.

Ó fi kun pé èyí fi hàn pé ohun tó so àwọn ọmọ Nàìjíríà pọ̀ ju ohun tó lè túwa ká lọ.

Ó tẹ̀síwájú pé Nàìjíríà ti la àsìkò tó le kọjá, pé ọ̀nà láti jẹ ọrọ̀ ló kù báyìí.

Ó wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà báyìí la àwọn ìṣòro tó ju ti Nàìjíríà lọ kọjá tí wọ́n sì móríbọ́ níbẹ̀.

Shettima fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Tinubu kò fẹ́ràn láti máa di ẹ̀bi ru ẹnikẹ́ni àti pé ó ń sá gbogbo ipá rẹ̀ láti mú ìgbà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè yìí.

Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti máa fi àdúrà ran orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Ààrẹ lọ́wọ́ kó lè ṣe àṣeyè nídìí iṣẹ́ ìlú tó gbé dání.

Nígbà tó ń gba ẹnu ìgbìmọ̀ aláṣẹ náà sọ̀rọ̀, Mínísítà fétò ìdájọ́, Lateef Fagbemi fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí Ààrẹ fún bí ó ṣe gba àwọn lálejò, tó sì ní àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn lẹ́nu iṣẹ́ àwọn.