Àjọ DSS ti fẹ́ pa mí, ó tẹ́ mi lọ́rùn láti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje-Nnamdi Kanu

Aworan Nnamdi Kanu pẹlu awọn agbẹjọro

Oríṣun àwòrán, Other

Nnamdi Kanu bọ aṣọ silẹ, o fariga nile ẹja pe ó togẹ lọwọ ajọ DSS.

Nile ẹjọ to ga ni Abuja nibi ti Nnamdsi Kanu ti farahan lo ti sọ pé awọn DSS ko tọju oun rara ati pe iya ti oun n jẹ nibẹ pọ.

Oga awọn IPOB yii fi awọn apa to wa lara rẹ han awọn eeyan lẹyin ti ile ẹjọ fun un laaye lati sọrọ.

Kanu sọ pe oogun ti ko dara ni wọn n fun oun fun aisan ọkan aya to n ṣe oun ati pe DSS ko fun oun laaye lati ri dokita ti oun gangan.

Ile ẹjọ giga to jokoo lonii ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 niluu Abuja ti kọ lati gba beeli ajijagbara ẹya Igbo ati olori ẹgbẹ Ipob, Nnamdi Kanu.

Ẹsun meje ọtọtọ ni ijọba apapọ fi kan Kanu eyi to rọ mọ igbesunmọmi ati iditẹ mọ ijọba.

Adajọ Binta Nyako yi ẹbẹ agbẹjọro rẹ, Aloy Ejimakor, tọ rọ ileẹjọ lati gba beeli Kanu nitori ailera rẹ danu.

Iléẹjọ́ kọ̀ láti gba béèlì Nnamdi Kanu, dá a padà sí àhámọ́

Kanu to tun foju ba ile ẹjọ lonii ti wa ni atimọle ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati oṣu Kẹfa ọdun 2021.

Nigba ti o n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Nyako paṣẹ pe ki igbẹjọ naa yara kiakia ju ti atẹyinwa lọ.

Bakan naa ni adajọ kepe igbimọ olupẹjọ lati mu ẹlẹri akọkọ wọn wa.

Ẹwẹ, agbẹjọro Kanu ko ṣai fi aidunnnu rẹ han si idajọ ileẹjọ.

Amofin Ejimakor ni o nira lati maa ba Kanu sọrọ ni atimọle DSS tori gbogbo ohun ti awọn ba fẹ sọ ni ajọ DSS yoo maa gbọ eleyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Ejimakor ni aṣọ kan naa lo si wa lọrun Kanu lati ọjọ yii, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ ti paṣẹ wi pe ki wọn paarọ aṣọ rẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro ijọba apapọ, Adegboyega Awomolo (SAN), rọ ile ẹjọ lati yi ẹbẹ agbẹjọro Kanu sanu, eleyii ti ileẹjọ pada ṣe.

Amofin Awomolo(SAN) ṣalaye pe ajọ DSS ni ile iwosan ti Kanu ti le ṣe itọju ara rẹ.

Agbẹjọro ijọba tun sọ pe Kanu ti salọ tẹlẹ ri nigba ti ileẹjọ gba beeli rẹ lọdun 2017.

Òní ni ilé ẹjọ́ yóò dájọ́ bóyá kí Kanu máa lọ ilé tàbí kó ṣì wà ní àhámọ́

Nnamdi Kanu

Oni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti Nnamdi Kanu pe lati bere fun beeli lẹyin ti ijọba apapọ fi si ti atimọle.

Ṣaaju ni ijọba apapọ Naijiria ti kọkọ fi ẹsun meje ọtọtọ kan Kanu eyii to rọ mọ igbesumọ ati iditẹ.

Nigba to n pe fun beeli naa, agbẹjọro Kanu, Alooy Ejimakor sọ fun ile ẹjọ pe eto ilera onibara oun ti dagẹgẹ o si nilo ki ijọba tu silẹ.

O sọ fun ile ẹjọ ọhun pe arun ọkan n yọ Kanu lẹnu eyii ti ile iwosan ijọba apapọ ti fidi rẹ mulẹ.

Amọ agbẹjọro ijọba apapọ Adegboyega Awomolo tako beeli naa bo tilẹ jẹ pe o ki ijọba tete ṣe ẹjọ afurasi ọhun ni kiakia.

Awomolo sọ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS n ṣetọju Kanu daadaa ni ahamọ rẹ, ati pe afurasi ọhun funra rẹ ti ṣe awọ ohun to fi han gbangba pe yoo na papa bora ti ile ẹjọ ba gba beeli rẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ṣaaju ni ileẹjọ to julọ ni Naijiria ti kọkọ dajọ pe Nnamdi Kanu gbọjọ tẹsiwaju igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga lori awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan an.

Ile ẹjọ to ga julọ yi idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to fagile awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Kanu danu.

Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to ga julọ sọ pe Kanu to jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara fawọn ẹya Igbo, IPOB, gbọdọ tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga.

Ninu idajọ ile ẹjọ giga julọ eleyii ti adajọ Emmanuel Agim ṣe aadri rẹ, igbimọ igbẹjọ naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna lati paṣẹ pe Kanu ko ni lati lọ ile ẹjọ mọ tori lilodisofin bi ijọba apapọ ṣe ya wọ ile rẹ.

Ile ẹjọ ni lootọọ ni pe ọna ti ijọba Naijiria fi gbe Kanu pada wale lati orilẹede Kenya lodi sofin, amọ iyẹn ko ni pe ki Kanu ma lọ sile ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ile ni Kanu le gbe ijọba lọ si ile ẹjọ lori bi ijọba apapọ ṣe gbe pada wa si Naijiria, amọ ko le sọ pe ki ile ẹjọ ma tẹsiwaju igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.