Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ojú òpó Facebook, Instagram àti X rẹ tí ọlọ́jọ́ bá dé?

Socila media

Oríṣun àwòrán, getty images

Ọpọ awọn ọrẹ Mathew ni ko gbọ pe o ti ku, wọn ṣi n ki ku oriire ọjọ ibi rẹ loju opo Facebook rẹ, eyii to ba iyawo rẹ ninu jẹ lọpọlọpọ.

Mathew, to jẹ ọkọ Hayley Smith ku lẹni ọdun mẹtallelọgbọn ni nnkan bii ọdun meji sẹyin lẹyin to ni arun jẹjẹrẹ.

Iyawo rẹ ni oun ti gbiyanju lati sọ oju opo rẹ naa di ti ẹni ti jade laye, iyẹn ‘memorial page,’ ṣugbọn Facebook ni ki oun fi iwe ẹri iku rẹ ṣọwọ amọ gbogbo ohun ti oun n ṣe ni ko so eso rere.

O ni “Mo ti gbiyanju rẹ fun igba ogun ti ko lọ lo jẹ ki n fi silẹ nitori mi o ni okun lati kan si Facebook funra rẹ.”

Ki ni wọn n pe ni ‘memorialised account?’

Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti n woye pe ki ni yoo ṣelẹ si oju opo ibanidọrẹ eeyan lori ayelujara ti irufẹ ẹni ba papoda.

Eyii ko ṣẹyin bi awọn eeyan ṣe maa n ki eeyan loju ọpọ rẹ lori ayelujara lasiko ọjọ ibi, paapaa ti wọn ko ba mọ pe irufẹ ẹni ti dagbere faye.

Awọn oju opo kan gba awọn mọlẹbi ẹni to jade laye laaye lati pa oju opo eeyan wọn to ku de, nigba ti awọn oju opo mii n lo ọna miran.

Fun apẹrẹ, ileeṣẹ kan ṣoṣo lo ni Instagram ati Facebook, wọn si fi aye silẹ ki eeyan sọ oju opo mọlẹbi rẹ di ti ẹni to ti ku pẹlu iwe ẹri iku ‘death certificate.’

Eyii ni wọn n pe ni pe wọn ‘memorialise’ oju opo naa.

To n tumọ si pe wọn yoo ti oju naa pa amọ awọn eeyan le lọ maa fi aworan sibẹ lati ṣe iranti ẹni to jade laye.

Irufẹ oju opo bẹẹ ni wọn maa n kọ akọle ‘in memory of’ si.

Facebook kii gbe irufẹ oju opo bẹẹ wa fun ẹlomiran lati badọrẹ.

Ni ti oju opo X, ko tii si aye lati sọ oju opo ẹni to ti jade laye di ‘memorial.’

Ewu to wa fun oju opo oku to wa ni ṣiṣi silẹ

Onimọ nipa abo ori ayelujara, Sasa Zivanovic sọ pe awọn onijibiti le bẹrẹ si n lo oju opo ẹni to ti ku lati ṣiṣẹ aburu.

Zivanovic sọ pe awọn kọlọrọsi ẹda le mu awọn nnkan nipa ẹni naa bi aworan, orukọ, ọjọ ibi ati bẹẹ bẹẹ lọ, lati ṣiṣẹ ibi.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn le lo irufẹ awọn nnkan nipa ẹni bẹẹ lati ṣi oju opo mii lati gba owo lọwọ awọn ti ko mọ pe oloogbe naa ti jade laye.