''Ẹ̀yin tí ẹ gba owó tí kìí ṣe tiyín lẹ́nu ATM nígbà tí kọ̀mpútà bánkì wa daṣẹ́ sílẹ̀, ẹ ò lè gbówó wa lọ''

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Ọgagba banki CBE ni orilẹede Ethiopia ti kilọ pe gbogbo awọn to gba ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lẹnu ẹrọ ATM banki nigba ti kọmputa awọn daṣẹ silẹ ko le gbe owo banki ti wọn gba naa lọ.

Lopin ọsẹ to lọ lawọn onibara ile ifowopamọ ọhun ya lọ si idi ẹrọ ATM ti wọn si bẹrẹ si ni gba owo to ju iye ti wọn ni ninu akaunti wọn lọ.

Koda, awọn mii tun gba owo lati akaunti wọn pẹlu banki CBE ti wọn si ranṣẹ si apo ikowosi banki wọn mii.

Lẹyin wakati diẹ ti eyi ti n ṣẹlẹ ni banki ọhun ṣẹṣẹ lanfani lati dawọn eeyan naa duro.

Ẹwẹ, ogagba banki naa, Abe Sano ti kilọ pe gbogbo ẹni to gba owo ti kii ṣe ti wọn ti ko si da a pada ni yoo foju wina ofin.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu BBC, Ọgbẹni Sano sọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati da owo ti wọn gba ti kii ṣe ti wọn pada titi ipari ọsẹ yii yoo foju wina ofin.

‘’Ko si bi wọn ṣe le gbe owo naa lọ, tori a mọ bi wọn ṣe gba owo yii, onibara banki ni wọn.

A mọ gbogbo wọn daadaa, a mọ bi a ṣe le wa wọn.

Ofin wa ti a le lo lati wa wọn ri,’’ ọgagba banki CBE lo sọ bẹẹ.

Oṣiṣẹ banki CBE kan sọ fun BBC pe o ṣoro lati ri owo tawọn eeyan fi ranṣẹ si akaunti wọn ni banki mii gba ju eyi ti wọn fi ranṣẹ si akaunti mii ti wọn ni pẹlu banki CBE lọ.

Ọgagba banki CBE ni banki naa ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ẹjọ awọn ti ko tii da owo ti wọn gba pada lọ sọdọ awọn ọlọpaa.

Ọgbẹni Abe tun ṣalaye pe owo tawọn eeyan gba lọ ko to $40m gẹgẹ bi iroyin kan ṣe sọ.

Amọ, o sọ pe awọn yoo mọ iye to jẹ ti banki naa ba ṣe iṣoro tan ni ipari ọsẹ yii.

Àwọn èèyàn gba ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lẹ́nu ATM lẹ́yìn tí ẹ̀rọ̀ kọ́mpútà báńkì daṣẹ́ sílẹ̀

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ile ifowopamọ to tobi julọ lorilẹede Ethiopia ṣi n gbiyanju lati gba ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu tawọn onibara wọn gba lẹnu ẹrọ ATM nigba ti ẹrọ kọmputa wọn daṣẹ silẹ.

Lopin ọsẹ to kọja lawọn onibara banki Commercial Bank of Ethiopia (CBE) ṣadeedee ri pe awọn le gba ju owo ti wọn ni ninu akaunti wọn lọ.

Awọn ileeṣẹ iroyin ni Ethiopia sọ pe owo to le ni N59bn($40m) lawọn eeyan gba lọ lẹnu ẹrọ ATM.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin wakati diẹ tawọn eeyan ti n gbowo ni banki naa ṣẹṣẹ lanfani lati da gbigba owo naa duro lẹnu ATM.

Aarẹ banki naa sọ fawọn akọroyin pe awọn akẹkọọ lo gba eyi to pọju ninu owo naa.

Ṣaaju ni ile ifowopamọ ọhun ti fi atẹjiṣẹ ransẹ sawọn onibara wọn pe ẹrọ kọmputa awọn n ṣe ṣege ṣege.

Akẹkọọ kan sọ fun BBC pe niṣe lawọn akẹkọọ pọ biba lori ila nibi ti wọn ti n gbowo lẹnu ẹrọ ATM kawọn ọlọpaa to wa dawọn duro.

Akẹkọọ mii, Jimma sọ pe oun o tiẹ gbagbọ nigba ti akẹgbẹ oun sọ foun pe eeyan le gba owo to ju iye to wa ninu akaunti eeyan lọ.

Banki CBE ni onibara to to miliọnu mejidinlogoji lati bi ọdun mejilelọgọrin ti wọn ti da banki ọhun silẹ.

Ẹwẹ, o kere tan, ile ẹkọ giga fasiti mẹta lo ti rọ awọn akẹkọọ wọn lati da owo ti wọn gba lati ẹnu ẹrọ ATM banki CBE ti kii ṣe ti wọn pada.

Koda, banki naa t i sọ pe awọn ko ni fẹsun ọdaran kan ẹnikẹni to ba da owo naa pada.

Amọ, akẹkọọ kan lati ile ẹkọ giga fasiti Jimma sọ pe oun ko tii gbọ pe akẹkọọ kankan ti da owo ti wọn gba pada.

Oṣiṣẹ fasiti Dilla kan sọ pe awọn oṣisẹ banki CBE wa ni ile ẹkọ naa nibi ti wọn ti n gba owo tawọn akẹkọọ n da pada.