APC kéde ₦50m owó fọ́ọ̀mù àti ọjọ́ ètò ìdìbò abẹ́lé sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo

Asia APC

Oríṣun àwòrán, APC/X

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC ti kéde ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí ètò ìdìbò abẹ́lé sí ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo yóò wáyé.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ètò APC, Sulaiman Argungun fi sórí ìkànnì ayélujára ẹgbẹ́ náà ni wọ́n ti kéde yìí.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ọjọ́ Kẹta sí ọjọ́ Kẹwàá oṣù Kẹrin ni ètò títa fọ́ọ̀mù yóò fi wáyé.

Àádọ́ta mílíọ̀nù náírà ni olùdíje tó bá fẹ́ díje fún àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC níbi ètò ìdìbò abẹ́lé náà yóò nílò láti fi ra fọ́ọ̀mù.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Fọ́ọ̀mù "expression of interest" ló jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà tí fọ́ọ̀mù "nomination" sì jẹ́ ogójì mílíọ̀nù náírà.

APC nínú àtẹ̀jáde náà ní àwọn obìnrin àti àwọn àkàndá ènìyàn tó bá fẹ́ kópa nínú ètò ìdìbò abẹ́lé náà yóò san mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà owó fọ́ọ̀mù "expression of interest" nìkan.

Ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní ìgbésẹ̀ àwọn yìí ló wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó rọ̀ mọ́ ètò ìdìbò tí ọdún 2022.

Bákan náà ni wọ́n fi àtẹ ètò bí ohun gbogbo yóò ṣe lọ lórí ètò ìdìbò náà léde.

Ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá ọdún 2024 ni àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC kéde pé ètò ìdìbò sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ondo yóò wáyé.

Kò dín ní àwọn olùdíje mẹ́rin lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tó fi mọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo lọ́wọ́ lọ́wọ́, tó ti fi èròńgbà wọn láti dupò gómìnà náà léde

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Orimisan Aiyedatiwa kéde ìpinnu rẹ̀ láti díje dupò náà fún sáà tuntun.