Àwọn jàndùkú agbébọn tún ti jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé lọ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Kaduna ti fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku agbebọn tun ti ji eeyan to le ni ọgọrin lọ niluu Kajuru ni ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi o ṣoju mi koro kan ṣe ṣalaye fun BBC, awọn janduku naa tun ya wọ awọn ṣọọbu nibi ti wọn ti ounjẹ atawọn nnkan mii lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Mansur Hassan, to ba BBC sọrọ ṣalaye pe lootọọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, amọ, ko sọ iye eeyan ti wọn ji gbe.
Ọgbẹni Hassan ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo sọ iye eeyan ti wọn tun jigbe lọ laipẹ.
Hassan ni ‘’ọtitọ ni pe awọn janduku agbebọn tun ti ṣọṣẹ ni Kaduna, amọ, a ko le sọ pato iye eeyan ti wọn jigbe bayii tori inu igbo nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Idi niyii ti a fi maa n sọ fawọn eeyan lati fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ti kẹfin ẹnikẹni to ba fara jọ ajinigbe.
Ọrọ to wa nilẹ yii dabi ogun nio pẹlu bawọn ajinigbe ṣe n gbe awọn eeyan lọ ni gbogbo igba.’’
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbofinro ti bẹrẹ si ni wa awọn ajinigbe to tun ṣọṣẹ yii lati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ọjọ meji tawọn janduku agbebọn ji obinrin mẹẹdogun ati ọkunrin kan lọ ni abule Dogon Nama ni ijọba ibilẹ Kajuru kan naa.















