Nǹkan kò fararọ ní Cameroon, aráàlú ń pariwo ebi
Awọn eeyan orilẹede Cameroon ti n pari ebi bayii lẹyin ti ijọba ilẹ naa bẹrẹ si n fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro.
Lọwọ yii, Cameroon wa lara orilẹede mẹwaa ti nnkan ti le koko julọ ni Afrika.
Owo ounjẹ ti gbowo lori nitori ere oko ti ko dara, isọro eto abo atawọn ileeṣẹ abẹle to yẹ ko maa pese ounjẹ amọ ti wọn dẹnukọlẹ.

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọkan lara awọn eeyan orilẹede naa to ba BBC sọrọ, Stella Anchuo ṣalaye pe nnkan ko rọrun fun awọn mọ, awọn si n fẹ ọna abayọ lati ọwọ ijọba.
Ọdun marun un sẹyin ni Anchuo ko lọ si ilu Yaoundé to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa lẹyin to sa kuro lagbegbe ariwọ iwọ oorun nitori ikọlu lemọlemọ awọn agbebọn.
Wayi o, ijọba ti sọ pe oun ti gbe awọn igbesẹ kan ti yoo maye dẹrun.
Lara igbesẹ naa ni afikun owo oṣu oṣiṣẹ ni ida marun un ati afikun owo oṣu to kere julọ.
Amọ ṣa, awọn eeyan ilẹ naa ko tii ni imọlara igbesẹ ijọba.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.





