Ìjọba apapọ̀ kéde orúkọ àwọn agbésùmọ̀mí tó kọlu Owo, Kuje àtàwọn onígbọ̀wọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, getty Images
Ijọba apapọ ti kede orukọ oniṣowo kan ni Kaduna, Tukaur Mamu, atawọn merinla mii gẹgẹ bii awọn to n ṣonigbọwọ awọn agbesumọmi ni Naijiria.
Ajọ Nigerian Financial Intelligence Unit, NFIU, lo kede orukọ awọn eeyan marundinlogun naa, ti mẹsan an ninu wọn jẹ oniṣowo dọla.
Ileeṣe iroyin Punch jabọ pe ibi ipade kan ti ajọ Nigeria Sanctions Committee ti pade ni wọn ti fẹnuko pe ki awọn afurasi naa jẹ iya to tọ labẹ ofin fun ipa ti wọn n ko ninu igbesumọmi ni Naijiria.
Atẹjde NFIU sọ pe “Adajọ agba Naijiria, pẹlu atilẹyin Aarẹ ti ti paṣẹ ki a fi orukọ awọn eeyan wọnyii si orukọ awọn ti yoo jiya labẹ ofin.
Lara orukọ awọn eeyan ti wọn kede ni Tukaur Mamu wa.
Mamu n jẹjọ pẹlu ijọba apapọ lọwọ bayii fun ipa to ko ninu ikọlu awọn agbsumọmi si ọkọ oju irin to n rinrinajo larin Abuja si Kaduna ninu oṣu Kẹta ọdun 2022.
Gẹgẹ bii ohun ti atẹjade naa sọ, Tukur Mamu kopa ninu igbesumọmi ọhun nipa gbigba owo itusilẹ ti iye rẹ to $200,000 lorukọ awọn abesumọmi ISWAP lati tu awọn ti wọn ji gbe ninu ọkọ oju irin Abuja-Kaduna silẹ.
Atẹjade ọhun tun sọ pe lara awọn ti wọn kede orukọ wọn naa lo wa nidi ikọlu to waye si ṣọọṣi St. Francis Catholic Church, ilu Owo nibi ti wọn ti pa eeyan to le ni ogoji lọdun 2022, to fi mọ ọgba ẹwọn Kuje ti wọn kọlu lọdun kan naa.
O tun juwe lara wọn bii “ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Ansarul Muslimina Fi Biladissudam, ẹgbẹ to ni ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ Al-Qaeda.”
NFIU tun juwe ẹlọmiran lara wọn bii “adari ninu ẹgbẹ Islamic State of West Africa Province Okene.”
O tẹsiwaju pe “Ẹgbẹ naa ni a fura si pe wọn kọlu ilu Abuja ati agbegbe rẹ, to fi mọ ikọlu ijọ St. Francis Catholic Church, niluu Owo, ipinlẹ Ondo lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
Ijọba ti ni ki wọn gbẹsẹle owo wọn to wa ni banki bayii.
orukọ awọ afurasi naa
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Loju opo Twitter ni agbẹnusọ Aarẹ Muhammadu Buhari tẹlẹ, Bashir Ahmad, ti kede orukọ awọn afurasi naa ati ileeṣẹ ti ijọba furasi.
Awọn orukọ naa ree:
- Tukur Mamu
- Yusuf Ghazali
- Muhammad Sani
- Abubakar Muhammad
- Sallamudeen Hassan
- Adamu Ishak
- Hassana-Oyiza Isah
- Abdulkareem Musa
- Umar Abdullahi
- West and East Africa General Trading Company Limited
- Settings Bureau De Change Ltd
- G. Side General Enterprises
- Desert Exchange Ventures Limited
- Eagle Square General Trading Company Limited
- Alfa Exchange BDC












