Kò sí àyè fún àwọn mínísítà láti fi owó ìjọba lọ òkè òkun fún oṣù mẹ́ta – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ti fofin de awọn minisita, olori ileeṣẹ ijọba atawọn mii ninu ijọba rẹ lati ma le rinrinajo ilẹ okeere pẹlu owo ijọba.
Ofin naa yoo bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, yoo si mulẹ fun oṣu mẹta gbako.
Aṣẹ ọhun lo jade ninu lẹta kan ti olori oṣiṣẹ Aarẹ, Femi Gbajabiamila kọ ranṣe si akọwe ijọba, George Akume.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹta ni wọn kọ lẹta ọhun.
Lẹta naa ka pe “Aarẹ n kọminu lori iye owo ti awọn minisita ati ẹka ijọba mii n na lori irinnajo ati afojusun lati sin araalu.
“Nitori ipo ti ọrọ aje wa ati ojuṣe ijọba lati ṣe ohun to yẹ, mo n kọ lẹta yii gẹgẹ bi aṣẹ Aarẹ lati fofin de irinjo ilẹ okeere awọn olori pẹlu owo ijọba fun oṣu mẹta gbako, bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.”
Gẹgẹ bii ohun ti lẹta naa sọ, eredi igbesẹ ọhun ko ṣẹyin ọna ati din iye owo ti ijọba n na ku.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju
Ninu oṣu Kinni ọdun 2024 ni Tinubu kọkọ din iye eeyan ti yoo maa tẹle lọ irinnajo labẹle ati lokeere ku, nibi to ti sọ pe awọn ti yoo maa tẹle oun ko gbọdọ ju eeyan marundinlogun lọ fun irinajo abẹle ati ogun eeyan fun irinajo ilẹ okeere.
Aarẹ tun sọ nigba naa pe awọn ẹṣọ alaabo ibi ti oun n lọ ni ko maa ṣọ oun dipo ki oun maa ko ẹṣọ kiri lati ilu Abuja.
Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti araalu sọrọ abuku si Aarẹ latari bo ṣe ko eeyan ti iye wọn le ni 500 lọ si ipade COP28 to waye nilẹ United Arab Emirates.














