Bàbá mi Taye Currency ò ṣubú, ẹ yé gbé irọ́ kiri - Yusuf ọmọ Currency

Aworan Taye Currency

Oríṣun àwòrán, tayecurrency/Instagram

Laarọ Ọjọru tii ṣe ogunjọ, oṣu Kẹta ọdun 2024 yii ni iroyin kan gba ori ayelujara pa pe gbajugbaja olorin Fuji, Taiwo Akande Adebisi ti ọpọ mọ si Taye Currency ṣubu ti o si dero ile iwosan niluu London loke okun.

Iroyin ọhun sọ pe ilumọọka akọrin Fuji naa n forin dawọn eeyan lara kaakiri loke okun ni iṣẹlẹ yii fi waye.

Awọn eeyan kan ti wọn sọ pe iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni Currency n ṣere lọwọ ni nigba to ṣadeedee ṣubu eleyii to mu ẹru ba awọn ololufẹ rẹ.

Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Taye Currency ṣubú tó sì dèrò ilé ìwòsàn ní London?

Aworan Taye Currency

Oríṣun àwòrán, tayecurrency/Instagram

Wọn ni awọn oṣiṣẹ eto ilera pajawiri lo sare gbe Currency digba digba lọ ile iwosan to wa layika ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

A ko le sọ bo ya gbajugbaja olorin Fuji naa ni arun kan ti o ba a finra, amọ, ọpọ ninu awọn ololufẹ rẹ papaa julọ lori ayelujara ni wọn ti n kọminu lori ilera rẹ.

Aworan Taye Currency

Oríṣun àwòrán, 9jaconnect

Mi o ṣubu o! Ṣáká lara da - Taye Currency

Ẹwẹ, Currency gan an fun ra rẹ ti sọ pe ko si otitọ ninu iroyin to ti tan kalẹ lori ayelujara pe oun ṣubu wi pe oun si ti dero ile iwosan.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin kan sọrọ lori foonu, Currency sọ pe ko si nnkan kan to mu oun.

O ni ‘’alaafia ni mo wa, ẹ maa dawọn to n gbe iroyin ofege kiri lohun.’’

Bakan naa, amugbalẹgbẹ rẹ, Tope Eluyefa naa sọ pe irọ nla lawọn eeyan kan n gbe kiri lorio ilera Currency.

Eluyefa sọ pe oun ṣi ba Currency sọrọ laarọ oni Ọjọru ki iroyin naa to jade.

‘’Ẹ beere lọwọ wọn pe nibo ni o ti ṣubu, o ti wa nle bayii,’’ Eluyefa lo sọ bẹẹ.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni Currency nigba ti o bẹrẹ iṣẹ orin Fuji pẹlu Kehinde ekeji rẹ to ti ku ati Rahmon Akilapa, to jẹ manija rẹ nigba naa ti oun naa ti di oloogbe bayii.

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo yan an sipo aṣoju aṣa ni saa kinni rẹ lẹyin to kọrin fun un lasiko ipolongo ibo.

Yusuf Adebisi, to jẹ ọmọ Currency naa wọle ibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo nibi to ti n ṣoju ẹkun guusu iwọ-oorun ipinlẹ Oyo.

''Baba mi Taye Currency o ṣubu, e ye gbe irọ kiri''

Aworan Taye Currency ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Hon Yusuf Adebisi/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọkunrin Taye Currency, Yusuf Adebisi to tun jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo naa ti sọ pe kokoko bayii ni ara baba oun le.

Nigba to n bawọn akoroyin sọrọ, Adebisi sọ pe ni gbogbo igba loun n ba baba oun sọrọ.

ko si si igba kan ti oun ṣe akiyesi ailera ninu ohun rẹ.

Adebisi ṣalaye pe awọn eeyan kan lo pinu lati gbe iru iroyin ofege yii sita, eyi to yẹ ki gbogbo eeyan yi danu.

Aṣofin Yusuf ni iyalẹnu lo jẹ fun oun bi ọpọ eeyan ṣe n pe oun lori ago lati beere nipa ilera baba oun.

O ni gbogbo ere ti baba oun n ṣe loke okun lo wa lori itakun ayelujara.

Nitori naa, ko si ibi kankan ti o ti ṣubu tabi ṣaarẹ.

''Mo fẹ fi da gbogbo eeyan loju papaa julọ awọn ololufẹ baba mi, Taye Currency pe ko si nnkan to ṣe Currency.

Currency n ṣere rẹ lọ lati ibikan si ibomiran lọwọ yii loke okun.

Mo fẹ kawọn eeyan fara balẹ nitori ko si ewu loko fun baba mi, afi giri aparo lasan.

Kii ṣe asiko yii lo yẹ kawọn eeyan kan maa gbe iroyin ofege kiri.

Orilẹede Naijiria nilo adura lasiko yii ki nnkan le yipada si rere,'' Adebisi lo sọ bẹẹ.