Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 17 tó gún òṣìṣẹ́ ìjọba pa ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ẹbi, Ọ̀rẹ́, Ojúlùmọ̀ ṣe ìsín ìdágbére fún olóògbé tẹkún-tẹkún
Ọwọ ṣikun Ajọ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo ti tẹ afurasi ti wọn lero pe o ṣekupa arabinrin Adelayi Funmilayo Florence ẹni ọdun mẹrin-le-laadọta ti wọn ba oku rẹ ninu ile rẹ lẹyin ọjọ marun-un ti wọn ti da ẹmi arabinrin naa legbodo.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, SP Funmilayo Odunlami-Omisanya ṣalaye pe afurasi ọhun, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Aduloju Omowumi ti wa lakata oloogbe naa fun ọdun pipẹ ti o si mu gẹgẹ bi ọmọ.
O ni iwadii fi han pe ọdọmọbinrin afurasi yii ni arun ọpọlọ sugbọn awọn oniṣegun oyinbo ko ti fi idi rẹ mulẹ.
Odunlami-Omisanya sọ pe ohun ti o waye laarin oloogbe naa ati Ọmọwumi ti o fi gun un pa ni ko i ti di mimọ si ẹnikẹni.
O ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun ti o waye gan-an.
Lara awọn olugbe agbegbe ọhun ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe, oloogbe naa ko ni ọmọ, idi rẹ niyi to fi fi ọmọ naa sọdọ, to si jẹ pe awọn mejeeji nikan lo n gbe ile naa. Sugbọn ni kete ti ọmọ naa ṣe iṣẹ laabi yii tan, o ti oku obinrin naa mọle o si na papa bora.
Wọn safikun rẹ pe lootọ ni Ọmọwumi ni arun ọpọlọ, sugbọn ohun to ru wọn loju ni pe, wọn ko le sọ ohun ti o waye gan ti ọmọdebinrin yii fi le yọ ọbẹ mọ ẹni to mu gẹgẹ bi iya.
Ni bayii, wọn ti ṣe isin ikẹyin fun oloogbe naa ni ile rẹ ti o wa ni adugbo Premier Estate, ni opopona Okunbadejo n'ilu Akure.
Awọn ẹbi, alabaṣiṣẹpọ, aladugbo ati awọn abanikẹdun lo pe ju pesẹ sibi eto isinku naa pẹlu awọn ẹri maa jẹ mi niṣo nipa awọn iṣẹ rere oloogbe naa.
Kini ohun ti o ṣẹlẹ?
Wọ́n bá òkú Florence ẹni ọdún 54 nínú ìyàra lẹ́yìn ọjọ́ márùn ún tí ọlọ́pàá sọ pé ó ti kú
Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori iku ẹni ọdun merinlelaadota ti wọn ba oku rẹ ninu iyara lẹyìn ọjọ marun un.
Ṣe won ni afẹfẹ to kaṣọ ni yara, ẹni wọ ti ẹ sọrun ko ma ṣafira ni.
Kayeefi ati iyalẹnu lo jẹ fún awọn ara adugbo, ẹbi ati ọrẹ arabinrin Florence Funmilayo Adelayi to je oṣiṣẹ ni ọfiisi aṣiro-owo ìjọba ìpínlè Ondo nígbà ti won gbọ nipa iku re.
Iwadii BBC Yoruba fihan pe, awọn ara adugbo Premier Estate, ni opopona Okunbadejo, nilu Oda to ri eṣinṣin, ti wọn si gboorun to n jade láti inú ogba Ile oloogbe naa lo ke gbajari sì àbúrò arabinrin to jade laye ọhun.
Gbajari yi waye lẹyin ti ilẹkùn Ile oloogbe naa wa ni titipa tiwọn si ro pe ko si ẹnikẹni nile.
Kini ọlọpaa sọ?
Alukoro àjọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo Funmilayo Odunlami- Omisanya ṣalaye fún BBC Yoruba pe aburo oloogbe naa lo wa sì Ile isẹ ọlọpaa lagbegbe Oda lati fi to agbofinro leti pe oun o gburo oloogbe naa ko to di pe o ri oku rẹ ni ile.
O ni pe: " Ni ọjọ Isinmi, ọjọ ketadinlogun oṣu yi ni arabinrin kan wa si ago ọlọpaa to wa ni Oda pe oun gbọ pe wọn ko ri arabinrin Funmilayo Adelayi to je ẹgbọn rẹ fun bi ọjọ márùn un.
"Oun wa lo si ile rẹ ti oun si ri oku re nilẹ ninu yàrá.
O ni Kete ti oun ri kayeefi yi ni oun wa sì àgó ọlọpaa".
Odunlami-Omisanya ni " lẹyìn ti wọn fi iṣẹlẹ yi to awọn ọlọpaa létí ni wọn gbera lọ si ile naa lati palẹ oku ọhun mọ lọ si ile igbokusi.
Nibi ti wọn ti n palẹ ara naa mọ ni wọn ti ri oju ibi ti wọn ti gùn oloogbe naa pa.
Awọn ọlọpa naa sì ri ọbẹ ninu yara."
Alukoro àjọ naa ni ọwọ Ọlọpaa ti tẹ afunrasi kan bayi ti iwadii sì n lọ lọwọ.
O parọwa sì awọn eeyan lati fi ife han si awọn alabagbe ati aradugbo to fi mọ bibẹrẹ alaafia awọn ti wọn ko ri ni asiko kan.
Lara awon alabasisepo oloogbe naa, to ni kan foruko bo oun laṣiri, ṣalaye pe ọjọru, ọjọ Kẹtala, oṣu yii n iwọn ri arabinrin naa kẹyin ni ọfiisi.
Akoroyin BBC Yoruba ri awọn iwe alẹmode lati kede iku arabinrin Adelayi ni abawọle ọgba ọfiisi aṣiroowo ipinlẹ Ondo.














