Nítorí kí n le ṣe tíátà ni mo ṣe lọ kọ́ iṣẹ́ ẹran títà - Monsuru Ijayegbemi

Àkọlé fídíò,
Nítorí kí n le ṣe tíátà ni mo ṣe lọ kọ́ iṣẹ́ ẹran títà - Monsuru Ijayegbemi
Monsuru Ijayegbemi

Agba oṣerekunrin, Monsuru Ijayegbemi, ti ṣalaye bi iṣẹ tiata ṣe di iṣẹ to sọ ọ di eeyan pataki lawujọ, ati bi irinajo rẹ ṣe jẹ.

Ninu ifọrọwwanilẹnuwo ti BBC ṣe fun un, oṣerekunrin naa to jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun, sọ pe lati igba ti oun wa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ni iṣẹ tiata ti wu oun.

O ni oun bẹrẹ nigba naa, ṣugbọn awọn obi oun ko fọwọ si.

Nigba to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ni wọn fi ranṣẹ si ilu Eko lati lọ kọ iṣẹ jorin-jorin, ti wọn n pe ni welder ni ede Gẹẹsi.

Ọgbẹni Ijayegbemi ṣalaye pe nibi ti oun ti n kọ iṣẹ naa, ni awọn eeyan kan ti ṣakiyesi pe oun le ṣe ere tiata, ti wọn si gba a ni imọran lati darapọ mọ ẹgbẹ kan.

O darapọ mọ ẹgbẹ naa lootọ, ṣugbọn asiko to n lọ fun igbaradi ere n ṣe idiwọ fun iṣẹ to n kọ.

Eyi lo mu ki ọga rẹ yari pe oun ko le ma a fun ni aaye lati ma a lọ fun ere tiata.

"Nigba ti ọga mi sọ pe ko si aaye, mo pinnu lati lọ ma a kọ iṣẹ ẹran tita, nitori pe iṣẹ naa ni ọga to n kọ mi ni ere tiata n ṣe."

Ọgbẹni Ijayegbemi sọ pe bi oun ṣe di alapata ẹran re e , to si tun n ṣe ere tiata pẹlu.

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Monsuru Ijayegbemi sọ pe oriṣiriṣi ipenija ni oun ti ni nidi iṣẹ ti oun yan.

Lara awọn ipenija to mẹnuba ni pe oun ti ti tori gbese owo ile oṣu kan, sa kuro ni ile ti oun n gbe ri.

Bakan naa lo sọ pe gbese lo le oun kuro ni odo ẹran, nitori iṣẹ sinima kan ti oun ṣe lọdun 2000.

O ni ṣugbọn oun dupẹ pe gbogbo rẹ ti di ọrọ itan bayii.