'Ó nira láti gbàgbọ́ nígbà tí Ọlọ́run ní kí n kúrò ní America lọ dá ìjọ sílẹ̀ ní Esie, Kwara'

Àkọlé fídíò, Ó ṣòro nígbà tí Ọlọ́run ní kí n fi America sílẹ̀ láti ní Esie nípìnlẹ̀ Kwara
'Ó nira láti gbàgbọ́ nígbà tí Ọlọ́run ní kí n kúrò ní America lọ dá ìjọ sílẹ̀ ní Esie, Kwara'
Yemi Adeyeye

Orilẹ-ede America ni Apostle Yemi Adeyey n gbe pẹlu idile rẹ, to si n ri ti aje ṣe.

Apostle Adeyeye ni ọkọ to fi ma n gbe awọn alaisan lọ si ileewosan fun itọju nilẹ America, oun lo si fi n tọju ẹbi.

Bakan naa lo ni awọn oṣiṣẹ to n ba a ṣiṣẹ.

Amọ lọjọ kan lo gbọ ohùn Oluwa pe, ko pada si orilẹ-ede Naijiria, lati lọ ma a ṣe iṣẹ iranṣẹ.

Adeyeye sọ fun BBC Yoruba nini ifọrọwanilẹnuwo pe, ilu Esie, nipinlẹ Kwara, ni ẹmi Ọlọrun dari oun si.

“Owurọ ọjọ kan ni Ọlọrun sọ fun mi pe ki n ko ẹru mi, ki n si ma a lọ si ilu kan ti wọn n pe ni Esie, nipinlẹ Kwara.”

Arakunrin naa sọ pe oun ko de ipinlẹ Kwara ri, ṣaaju asiko ti Ọlọrun ba oun sọrọ.

“Mo ni lati pe awọn eeyan mi fun apejuwe ilu ti ọlọrun dari mi si ni.”

Nigba to de si Naijiria lo da ile ijọsin Christ Tabernacle of Fire Global Outreach silẹ.

O ni aṣẹ naa nira fun oun lati gbagbọ, ti kii ba ṣe pe oun mọ ohun ẹni to ba oun sọrọ pe ko le parọ.

“Idi ni pe, ti ma a ba ti ẹ fi America silẹ lati lọ ṣiṣẹ ni ilu mii, bi Eko tabi Port Harcourt, ni mo fi ọkan si, kii ṣe ilu bii Esie.

Ọdun 2002 ni Yemi Adeyeye lọ si ilẹ America, amọo pada si Naijiria lọdun 2023, lẹyin ọdun mọkanlelogun.

Bakan naa lo ni awọn eeyan ti wọn jọ ma n korajọ lati gbadura ni ori-oke kan ni Cedar Hill, niluu Dallas Texas.

Iṣoro akọkọ ti Apostle Adeyey ni lẹyin to gbọ ohun ni pe, bawo ni yoo ṣe sọ fun iyawo rẹ pe Ọlọrun ni ki oun pada si Naijiria.

“Mo gbera lati sọ fun iyawo mi nipa nnkan ti mo gbọ. Amọ iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ẹẹrin lo bu si lẹyin ti mo sọ fun un.”

O ni iyawo oun sọ pe Ọlọrun funra rẹ ti ba oun sọrọ ni aarọ ọjọ naa, nipa irinajo ọhun.

Nnkan to ṣẹlẹ yii lo jẹ ko ni idaniloju akọkọ pe lootọ ni oun gbọ ipe.

O ni ṣaaju ni oun ti gbadura fun ami, nibi ti Ọlọrun ti sọ fun oun pe oun ti ran ẹnikan si i lori Facebook.

“Mo yẹ Facebook mi wo, mo si ri i pe pasitọ kan lati orilẹ-ede kan ni Africa ti fi ohun ranṣẹ si mi, pe Ọlọrun ni ko sọ fun mi pe ki n ṣe nnkan ti oun ni ki n ṣe , nitori asiko ti to lati ṣe e .

Apostle Adeyeye ṣalaye pe kii ṣe nitori owo ni oun ṣe gba iṣẹ iranṣẹ biko ṣe lati jere ọkan awọn eniyan ninu ilu naa.