Bíṣọ́ọ̀bù ẹni ọdún 74 ń kojú ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀

Aworan afihan ami idanimọ Biṣọọbu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Biṣọọbu tẹlẹ ri kan lorileede Australia, Christopher Saunders ni wọn ti fẹsun ifipabanilopọ ati awọn ẹṣẹ mii to jẹ mọ ibalopọ ninu kan an.

Ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin yi ni ọwọ awọn agbofinro ba lẹyin ti iwadii waye lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Australia ati ọfisi Poopu mimọ.

Ọgbẹni Saunders ti fi han pe oun ko ni bẹbẹ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn ba fi kan an.

O jẹ ọkan lara awọn agbaagba ijọ Katọliki ti wọn yoo fi iru ẹsun bayii kan.

Ẹsun ifipabanilopọ onigun meji ni wọn fi kan Saunders, ẹsun mẹrinla to nii ṣe pẹlu ikọlu si ẹlomiran lọna aitọ ati ẹsun mẹta to da lori biba ọmọ ṣe pọlọna ti ko tọ fun eeyan to wa ni ipo giga.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan an yi ni wọn lo waye laarin ọdun 2008-2014 lawọn ilu Australia to jina si igboro diẹ.

Awọn ilu naa ni: Broome, Kununurra ati laarin awọn eeyan ibilẹ to wa ni Kalumburu.

Wọn gba beeli rẹ lỌjọbọ ti wọn si paṣẹ pe ki o ma kuro nile rẹ titi di igba ti wọn yoo fi gbẹjọ rẹ ni oṣu Kẹfa gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Australia ti ṣe jabọ.

Saunders ni oṣiṣẹ ṣọọṣi to ni ipo to ga julọ ti wọn fẹsun ifipa ba ọmọde lo pọ kan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si Cardinal George Pell, to doloogbe ti wọn ran lẹwọn, ti wọn si tun pada tu silẹ, Saunders ni oṣiṣẹ ṣọọṣi to ni ipo to ga julọ lorileede naa ti wọn fẹsun ifipaba ọmọde lo pọ kan

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lỌjọbọ, ẹgbẹ awọn Bisọọbu Australia jẹjẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro ti wọn si ni ẹsun to lagbara ni wọn fi kan Ọgbẹni Saunders ni paapa fun awọn to mu ẹsun naa wa.

''O tọ bẹẹ lo si yẹ ki wọn ri pe wọn ṣe iwadii ẹsun wọnyii lẹkunrẹrẹ''

Bẹẹ ni Archbishop Timothy Costelloe to jẹ Archbishop ilu Perth.

Ọgbẹni Saunders ti wọn kọkọ ṣe iribọmi fun lọdun 1976 lo ọpọ ọdun lagbegbe Kimberly ni iwọ oorun ariwa orileede naa ti wọn si yan sipo Biṣọọbu Broome lọdun 1996.

Diocese too n dari yi sunmọ odinwọn dedee orileede Turkey to si kaari gbogbo awọn agbegbe to wọnu julọ ni Australia.

Eeyan ti awọn eeyan pọnle pupọ ni agbegbe naa ni Ọgbẹni Saunders jẹ to si jẹ ẹni ọwọ lawujọ rẹ.

Lọdun 2020 ni wọn kọkọ fi ẹsun kan ṣugbọn wọn ko pawe de lori iwadii ọlọpaa lalae fẹsun kankan kan.

O jọwọ ipo rẹ gẹgẹ bi Biṣọọbu Broome ṣugbọn wọn ṣi kaa kun gẹgẹ bi Biṣọọbu Emeritus.

Poopu mimọ pada wa gbe igbimọ dide ti o mu ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii tuntun mii.