Sunday Igboho padà dé sí Nàíjíríà lẹ́yìn ọdún mẹ́ta

Sunday Igboho laarin ero

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye mọ si Sunday Igboho lo ti wọ orileede Naijiria pada.

Ninu ikede kan ti agbẹnusọ fun Igboho, Ọlayọmi Kọiki gbe soju opo ayelujara ‘X’ rẹ lọsan ọni, Ọjọbọ, o ni Igboho de lati sinku mama rẹ.

Ọdun kẹta ree ti Igboho ti kuro lorileede Naijiria, lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ ṣe ikọlu sile ẹ to wa lagbegbe Ṣoka niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Aworan Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Instagram

Koiki ninu ọrọ to kọ sabẹ fọnran to gbe soju opo rẹ naa sọ pe oun le fidi rẹ mulẹ pe Igboho ti wọ Naijiria.

“Mo le fidi rẹ mulẹ fun un yin pe Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ si Sunday Igboho ti wa loju ọna ilu rẹ silu Igboho fun ayẹyẹ ikẹyin isinku mama rẹ, Arabinrin S. A. Adeyẹmọ.

“Oku Arabinrin Adeyẹmọ ni wọn ti lọ gbe kuro ni mọṣuari to wa niluu Ṣaki ni nnkan bii wakati meloo sẹyin.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Wo awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin si Sunday Igboho

Oru mọjumọ ọjọ kini, oṣu keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lorileede Naijiria lọ kọlu ile Sunday Igboho, nibi ti wọn ti pa awọn meji, ti wọn si ko awọn mẹtala lọ siluu Abuja.

Gboho ile naa ni wọn fi ibọn bajẹ, to fi mọ awọn mọto to wa ninu ile naa, ti ẹjẹ si bo gbogbo ilẹ inu ile si ayika inu ọgba ile Igboho.

DSS ni awọn pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo miran lorileede yii ni wọn jọ ṣiṣẹ papọ lati kọlu Igboho, ṣugbọn to poora mọ wọn lọwọ.

Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko ibọn ati awọn ohun ija oloro pamọ lati da ogun silẹ laarin ilu.

Lara awọn ohun ti wọn ko ni iwe irinna, ibọn, awọn aṣọ oogun loriṣiriṣi, to fi mọ ologbo.

Ọwọ tẹ Igboho ní Cotonou

Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni ileeṣẹ eleto aabo Interpol tẹ Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun to wa ni Cotonou ti ilẹ olominira Benin.

Alẹ ọjọ naa la gbọ pe Igboho n gbiyanju lati ri irin ajo lọ si orileede Germany pẹlu iyawo rẹ Rọpo Adeyẹmọ.

Ohun ti a gbọ ni pe oṣiṣẹ papakọ ofurufu ti ṣakiyesi Igboho ti iroyin rẹ tan kaakiri wi pe awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ n wa ni Naijiria lo fẹẹ gba Cotonou lọ si Germany.

Ibi ti wọn sọ pe oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa ti n beere oriṣiriṣi ibeere lọwọ ẹ, ni wọn sọ pe Igboho ti sa kuro niwaju ẹ, toun pẹlu iyawo rẹ si lọ farapamọ sibi kan.

Lẹyin o rẹyin ni wọn sọ pe ọkunrin kan to n ṣeto irinna fun Igboho ni wọn pada lo lati rii mu. Wọn ni ẹni naa lo ranṣẹ pe Igboho wi pe oun ti yanju pẹlu awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu naa.

Bi Igboho ṣe debẹ pada lati wọ baluu ni wọn sọ pe awọn oṣiṣẹ aabo Interpol naa mu, ti wọn si de e ni ṣẹkẹṣẹkẹ lọwọ ati ẹsẹ.

Igboho foju ba ile-ẹjọ

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni Igboho foju ba ile-ẹjọ Cour D’Appel De Cotonou lori ẹsun wi pe o wọ orileede naa lọna aitọ ati nini ayederu iwe irinna orileede naa.

Oṣu mẹsan gbako ni Igboho lo lọgba ẹwọn ilẹ olominira Benin, ko to di pe o gba ominira.

Awọn ọmọ Yoruba ṣe iwọde ifẹhonuhan

Aworan iwọde

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Kaakiri ilẹ Yoruba ni awọn alatilẹyin Sunday Igboho ti ṣe iwọde ifẹhonuhan lati rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Wọn ni ki ijọba apapọ fi Igboho silẹ, ki wọn si jawọ ninu ẹjọ ti wọn n ba a fa, nitori pe kii ṣe ọdaran tabi agbebọn.

Awọn alatilẹyin Igboho naa sọ pe awọn ọmọ Yoruba ni Igboho n ja fun kuro lọwọ awọn Fulani darandaran ti wọn n fojoojumọ kọlu wọn kaakiri.

Wọle Ṣoyinka ṣabẹwo si Igboho

Ogbontarigi onkọwe, onkọtan nni, Wọle Ṣoyinka ṣe abẹwo si Igboho lẹyin bi ọsẹ marun-un ti ijọba Benin yọnda rẹ kuro lọgba ẹwọn lati lọ igba itọju to pe ye.

Ṣoyinka ṣe abẹwo yii lẹyin ọsẹ marun-un ti olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Oloye Banji Akintoye kede pe Igboho ti gba ominira.

Igboho pe ijọba apapọ l’ẹjọ lori ikọlu DSS

Agbẹjọro Igboho, Yọmi Alliyu lo gbe ijọba Naijiria ati ajọ DSS lọ sile ẹjọ giga tiluu Ibadan nipinlẹ Ọyọ, nibi to ti n beere fun ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira gẹgẹ bi owo itanran ile ati dukia rẹ ti wọn bajẹ.

Alliyu ni ọna aitọ ni DSS gba lati fi kọlu Igboho nile ẹ, to si ni wọn ba gbogbo dukia rẹ jẹ kọja sisọ, eyi to to ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira.

Ile-ẹjọ ni ki ijọba apapọ san owo fun Igboho

Onidajọ Ladiran Akintọla gba ẹbẹ Igboho nipasẹ agbẹjọro rẹ, to si ni ki ijọba apapọ lọ san owo ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira gẹgẹ bi owo itanran ati owo dukia Igboho ti wọn ba jẹ.

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun wọgile idajọ naa

Onidajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun niluu Ibadan, Muslim Hassan paṣẹ pe idajọ ile-ẹjọ giga ti Onidajọ Akintọla gbe kalẹ ko lẹsẹ nilẹ rara, fun idi eyi, o paṣẹ pe ijọba apapọ ko ni owo kankan lati san fun Sunday Igboho.

Igboho gbominira lẹyin ọdun meji

Igboho ninu fọnran to gbe soju opo Instagram rẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun ti gba ominira lati lọ sibi to ba wu oun, lẹyin ti ile-ẹjọ ti da oun lare wi pe oun ko jẹbi ẹsun kankan.

O ni oun le pada si Naijiria nigbakugba to ba wu oun.

Inu oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni Igboho gbe fọnran jade sita, nibi to ti n dupẹ lọwọ ijọba Benin fun atilẹyin wọn, to si jẹ ko di mimọ fun gbogbo agbaye, paapaa awọn ọmọ Naijiria wi pe oun ti gba ominira.

Ninu fọnran naa lo tun ti dupẹ lọwọ awọn ololufẹ ati awọn alatilẹyin rẹ fun aduroti wọn, pẹlu ileri wi pe oun yoo maa fi bi nnkan ba ṣe n lọ to wọn leti.

Ile-ẹjọ ECOWAS ni ki ijọba Benin san ogun miliọnu CFA fun Igboho

Igbimọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ naa kalẹ paṣẹ pe ọna aitọ ni wọn fi mu Igboho, ti wọn si tun tii mọle lai ṣẹ.

Ile ẹjọ naa paṣẹ wi pe wọn gbọdọ san owo ọhun fun Igboho laarin oṣu mẹta gbako.

Ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023 ni Igboho pe ijọba Benin lẹjọ.