Ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀kan di àwátì,15 yè nígbà tí ọkọ̀ ojú omi dànù l’Ékòó

Ọkọ oju omi to danu

Oríṣun àwòrán, LASWA

Ko din ni eeyan kan to ti dagbere faye, ti ọkan si ri sinu omi nibi ijamba ọkọ oju omi to ṣẹlẹ l’Ọjọru, ọjọ kọkanlelogun, oṣu keji, ọdun 2024.

Atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ irin ajo ori omi nipinlẹ Eko, Lagos State Waterways Authority (LASWA) gbe jade, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe eeyan mẹtadinlogun lo wa ninu ọkọ oju omi naa.

LASWA ni awọn mẹẹdogun ni ori ko yọ lasiko ijamba ọkọ oju omi naa.

"Oku obinrin kan la ti i ri, a si n wa oku ọkunrin kan to ri sinu omi"

Atẹjade ọhun ti Wuraọla Alake, to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ naa fi sita jẹ ko di mimọ pe oku obinrin kan ninu awọn meji to ku ni wọn ri, to si ni wọn ṣi n wa oku ẹnikan yoku to jẹ ọkunrin.

Agbegbe Powerline to wa ni afara Ikoyi ni ijamba ọhun ti waye, gẹgẹ bi Wuraọla ṣe ṣalaye.

O ni ẹkun omi to ṣẹlẹ lo mu ki awakọ oju omi naa sare lọ kọlu opo ina onirin ti a mọ si ‘High-Tension Pole’, to si mu ki ọkọ oju omi naa ṣubu lojiji.

Wuraọla ni awọn ṣi n gbiyanju lati rii pe wọn ṣawari oku ọkunrin naa.