Òní ni sátẹ́láìtì ‘ERS-2’ yóò jábọ́ láti òfúrufú sórí ilẹ̀ ayé

Grandfather satellite

Oríṣun àwòrán, Esa

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe satẹlaiti ilẹ Yuroopu kan yoo jabọ sori ilẹ aye lati oju ofurufu laarin wakati diẹ si asiko yii.

Satẹlaiti naa, ti wọn n pe ni 'Grandfather satellite' ni wọn fi ranṣẹ si ofurufu lọdun 1995, lati maa wo ilẹ aye lati oke.

Amọ lẹyin to ti pari iṣe rẹ tan lọdun 2011 lo ti bẹrẹ si n jabọ lati oke, a si gbọ pe oni yii gan ni yoo balẹ si aye.

Ajọ European Space Agency (Esa) sọ pe pupọ lara awọn ẹya ẹrọ naa yoo jona ko de ile aye, amọ lara rẹ ti ko ni gbina loju ọna lo maa balẹ si ibi ti ero pọ si, eyii to le ṣe ijamba fun awọn eeyan.

Esa ni ko si ẹni to mọ ibi ti yoo ja si to ba dele aye, amọ niwọn igba to jẹ pe omi lo gba pupọ ilẹ aye, o ṣeeṣe ki satẹlaiti naa ja sinu alagbalugbu omi.

AIRBUS

Oríṣun àwòrán, AIRBUS

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ Esa, Mirko Albani, sọ pe ti satẹlaiti naa ba de ile aye, ko le pa ẹda lara.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn onimọ sọ, o ṣoro lati sọ ni pato akoko ti satẹlaiti naa yo jabọ, ati ibi ti yoo balẹ si, eyii da lori ipo ti oju ofurufu loke lọhun wa.

Wọn ni lara awọn ẹka satẹlaiti naa ti yoo bale saye ni awọn irin ti wọn fi ṣe, atawọn ẹya rẹ mii.

Ẹwẹ, ileeṣẹ kan nilẹ Amẹrika to n ri si ọrọ satẹlaiti, SpaceX, sọ pe oun yoo da nnkan bii ọgọrun satẹlaiti pada ninu ẹgbẹrun marun un o le satẹlaiti rẹ to wa loju ofurufu.

SpaceX sọ pe eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin pe awọn satẹlaiti ọhun ti n kọṣẹ, ko si ni dara ko jabo silẹ aye lairo tẹlẹ.